Kíní ọ̀nà àbáyọ sí awuyewuye ìgbà gbogbo láàrin Gómìnà àti igbákejì wọn ní Nàìjíríà?

Aworan Gomina Obaseki ati igbakeji rẹ Philips Shuaibu

Oríṣun àwòrán, BBC

Bi eeyan ba ti n fi ọkàn ba oṣelu Naijiria bọ tipẹ yoo ti ṣe akiyesi nípa ìjà to máa n saaba waye laarin awọn Gomina àti igbakeji wọn.

Ija yi a maa le debi pe wọn a sí maa yọ igbakeji Gomina kuro nipo.

T'ohun ti pé o ti to ọjọ meloo kan ti Naijiria ti padà sí ìjọba awarawa ija yi kọ dẹkùn koda o sebi ẹni pé o n peleke sii ni.

Laipẹ yi nínú iroyin la rí tí àwọn ẹṣọ ile ìjọba nipinlẹ Edo tí igbakeji Gomina Philips Shuaibu sita nitori ede aiyede to n waye laarin rẹ ati Gomina Obaseki.

Lati igba tí Naijiria padà sí ìjọba awarawa lọdun 1999,ija laarin Gómìnà àti igbakeji titi di asiko yi kọ dẹkùn.

Ka to tẹsiwaju o tọ kí a mú ẹnu ba a wipe iru ija yi máa n waye laarin aarẹ ati igbakeji rẹ naa sugbọn ko wọpọ bi ti àwọn Gomina àti igbakeji.

Yato sí aarẹ Olusegun Obasanjo ati igbakeji rẹ Atiku Abubakar ti irú nkán bẹẹ ṣẹlẹ laarin wọn a kò kẹfin pé ija waye laarin aarẹ ati igbakeji mii.

Bi Gómìnà àti igbakeji ba fi ẹrin ati ayọ bẹrẹ, lọpọ igba tipa tikuku ni wọn a fi pari saa wọn lori ìjọba.

O buru débi wípé wọn a fi ofin mu igbakeji nígba mii tabi ki awọn mejeeji sí ko ọrọ lọ sí ile ẹjọ fún iyanju.

Apẹẹrẹ ibi ti ìjà ti waye laarin Gomina ati awon igbakeji won:

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Apẹrẹ ibi ti irú ìṣẹlẹ yí ti waye ni ipinlẹ Zamfara, Ondo, Kogi,Abia, Adamawa,Bayelsa,Plateau, Akwa-Ibom Bauchi Taraba Osun Enugu, Èkó ati Kano.

Eyi to gbòde bayi ni ija laarin Gómìnà Edo Godwin Obaseki ati igba keji rẹ Philip Shuaibu.

Ọrọ yí tàwọn akọroyin ti n sọ nípa rẹ tó ọjọ mẹta ti buru débi wípé Gomina Obaseki tí pàṣẹ ki wọn ma ṣe faaye gba igbakeji rẹ Philips Shuaibu lati wọlé sí ile ìjọba.

Àwọn olugbe ipinlẹ Edo kọọkan to ba BBC sọrọ ni inu awọn ko dun sí ìṣẹlẹ yí.

" Ija laarin Gómìnà àti igbakeji yi jẹ iyalẹnu tori igbọraeni yẹ yẹ kó wà laarin ọgá ati igbakeji rẹ amọ o ti wa de ọdọ awọn alatilẹyin Gomina ati igbakeji rẹ tó n ba ará wọn já"

"Àwọn onwoye agbo oṣelu kan láwọn ṣe akiyesi pe awọn Gomina Ti sọ igbakeji wọn di gbẹwu dani ti eyi kò sí dáa to nitori iwe ofin fún onikaluku lagbara lọtọótọ"

Ọjọgbọn Kamilu Sani Dagbe olùkọ ní fasiti Kano sọ pé "igbakeji Gomina kò ni isẹ kánkan ayafi eleyi ti Gomina ba gbe le lọwọ.Awon igbakeji ti o ba fẹ dà isẹ ará wọn jẹ eyi a máà mú kí Gomina bínú siwọn.Eyi lo fa ti Gomina mii kìí fẹ gbe agbara fún igbakeji rẹ lẹyìn tí wọn ba pari saa wọn papọ"

Níbi tí ija yi ba ti pọ laarin Gómìnà àti igbakeji tàwọn mejeeji kò sí fẹ gba, ohun tí yóò ṣẹlẹ ni pé Gomina yóò gbà tiketi ẹgbẹ tí yóò sí gbe fún elòmíràn"

Bi eyi ba waye Ọjọgbọn Fagge ni igbakeji yóò lọ sí ẹgbẹ oṣelu mii lati ri tikẹẹti Oludije gba ipo Gomina.

Ọnà Abayọ da?

Onimọ yi sọ pé ija yi ko ni ye maa waye ayafi ti wọn ba mu iyipada ba eto oṣelu Naijiria.

Ní pataki o sọ pé iwe ofin Naijiria yóò ni lati ri àtúnṣe eleyi ti ko ni jẹ ki gbogbo agbára wa lọwọ awọn Gomina.

O ní wọn kò bá ṣè eleyi opin kò lè de ba ija gbogbo ìgba laarin Gómìnà àti igbakeji rẹ.

Ija yi gẹgẹ bo ṣe sọ ninu akotan kò mọ ẹgbẹ oṣelu kan yatọ.

Yálà Apc ni tabi PDP o ní kò sí ẹgbẹ tí faakinfa kii waye laarin Gómìnà àti igbakeji wọn.