Aregbesola vs Oyetola: Ìjọba ní ọgbọ́n à ti dá ìbẹ̀rù sọ́kàn àwọn ara ìlú ni Aregbesola ń dá

Oríṣun àwòrán, @Oyetola
Kini ki a ti pe ohun to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ Osun bayii? ni ibeere ti ọpọ n beere.
Saaju ni itahunsiraeni ti waye laarin Ogbeni Rauf Aregbesola to jẹ gomina ana ipinle Osun ati alhaji Gboyega Oyetola to n tuko ipinlẹ naa bayii.Kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ láti yé da àláfíà ìlú láàmú - Ìjọba ìpílnẹ̀ Osun sí Aregbesola
Ìjọba ìpílnẹ̀ Osun ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà, Rauf Aregbesola, ṣe dàbọn bolẹ̀ ní agbègbè Old Garage, ìlú Osogbo lọ́jọ́ Ajé.Àwọn tọ́ọ̀gì Aregbesola ló da wàhálà sílẹ̀ l'Osun - Ọlọ́pàá
- Wo àwọn ibùdó mánigbàgbé tó wà ní Ajaṣe ni orilé-èdè Benin Republic níbi tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá ti lọ ṣàbẹ̀wò
- Olaleye Paul rí ẹ̀wọ̀n he ní àyájọ́ olólùfẹ́ ní Ilọrin
- Wo ọkùnrin kan tó fi N1.2m gbẹ́ ibojì rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó sì wà láàyè
- Wo ohun méjé tó yẹ kí o mọ̀ nípa Abba Kyari, ọ̀gá ọlọ́pàá tí wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn
- Ọmọ ọdún 18 dèrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn pẹ ó gún akẹgbẹ́ lọ́bẹ pa
- Barrister ló sọ mí di èèyàn ńlá - Ayinla Kollington
- Ki lo ṣokunfa ikọlu to n waye si ẹni to ba wọ aṣọ Sunday Igboho tabi Yoruba Nation n'Ibadan?
Ijọba to n tuko ipinlẹ Osun bayii ti fesi si ohun to n ṣẹlẹ nibẹ bayii:
Ìjọba ní ọgbọ́n à ti dá ìbẹ̀rù sọ́kàn àwọn ara ìlú ni Aregbesola ń dá.
Olùdámọ̀ràn pàtàkì sí gómìnà Oyetola lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú, Sunday Akere ní kò sí òótọ́ kan nínú ọ̀rọ̀ tí Aregbesola sọ pé àwọn jàǹdùkú kan fẹ́ gba ẹ̀mí òun.
Akere ni ohun tó ń gbìyànjú à ti ṣe ní láti dá làásìgbò kalẹ̀ kí ìjọba àpapọ̀ le kéde ìpínlẹ̀ Osun bí ìpínlẹ̀ tí nǹkan kò ti fararọ.
Ó fi kun pé Aregbesola fẹ́ da ìbẹ̀rù bojo sọ́kàn àwọn olùdibò ṣaájú ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó ń bọ̀ lọ́nà lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ náà kò jọ àwọn lójú.
Bákan náà ló rọ ìjọba àpapọ̀ láti ba Aregbesola níwọ̀ọ́ bí gbogbo ìgbésẹ̀ àti ìhùwà rẹ̀ kò mú ìfẹ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun dání.

Oríṣun àwòrán, @Oyetola
Aregbẹsọla kìí ṣe Olọ́run, iṣẹ́ Oyetola ló máa fọhùn lọ́jọ́ ìdìbò- Ismail Omipidan
Agbẹnusọ gómìnà Ìpínlẹ̀ Osun, Omipidan tí fèsì sí ọ̀rọ̀ tí gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà, Rauf Aregbesola sọ pé kí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà má dìbò fún Oyetola níbi ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó ń bọ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.Bí ẹgbẹ́ APC ṣe yọ Ambode l'Eko la máa yọ Oyetola l'Osun- Aregbesola
Omipidan ní Aregbesola kìí ṣe Ọlọ́run àti pé òun kọ́ ni yóò sọ ohun tí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà yóò fún wọn.
Aregbẹsọla kìí ṣe Olọ́run, iṣẹ́ Oyetola ló máa fọhùn lọ́jọ́ ìdìbò- Ismail Omipidan
- Wo àwọn ibùdó mánigbàgbé tó wà ní Ajaṣe ni orilé-èdè Benin Republic níbi tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá ti lọ ṣàbẹ̀wò
- Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀
- U.S. yóò máa fún àwọn ọmo Nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ tọkọtaya tó gbé ẹ̀yà ara ènìyàn pamọ́ sínú yàrá l'Ogun
- Ìjọba Guinea-Bissau di ẹbi ìdìtẹ̀gbàjọba tó foríṣánpọ́n rú àwọn tó ń ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró
- Ẹ dẹ́kun bíba ìjọba lórúkọ jẹ́ - Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fèsì sí lẹ́tà Oluwo
Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ènìyàn lo máa dìbò kìí ṣe Aregbesola, Ati pe gomina ana naa ko lẹ́nu láti sọ fún àwọn ènìyàn ohun tí wọ́n máa ṣe nítorí kì í ṣe ọmọlúwàbí tó bẹ́ẹ̀.
Ati pe ti a ba fi Aregbesola wé Oyetola bi Omoluwabi, wọn yatọ si ara wọn.
- Wo ohun méjé tó yẹ kí o mọ̀ nípa Abba Kyari, ọ̀gá ọlọ́pàá tí wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- Ọmọ ọdún 18 dèrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn pẹ ó gún akẹgbẹ́ lọ́bẹ pa
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dárúkọ àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tó ń bá Abba Kyari ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé oògùn olóró
- Barrister ló sọ mí di èèyàn ńlá - Ayinla Kollington
- Ki lo ṣokunfa ikọlu to n waye si ẹni to ba wọ aṣọ Sunday Igboho tabi Yoruba Nation n'Ibadan?
- Àgbáríjọpọ̀ èèyàn sẹkúpa ọkùnrin kan lórí ẹ̀sùn pé ó dáná sun Kurani
Bákan náà ló fi kun pé ṣàṣà ni ìlérí tí gómìnà tó wà lórí àléfà ṣe fún àwọn ènìyàn tí kò ì tíì múṣẹ.
Omipidan ni pe látorí owó òṣìṣẹ́, owó àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì tí gbogbo rẹ̀ ń lọ déédéé, títún àwọn ilé ẹ̀kọ́ ṣe àti títí ṣíṣe gbogbo rẹ̀ ni Oyetola ti ṣe.

Oríṣun àwòrán, Others
Bí ẹgbẹ́ APC ṣe yọ Ambode l'Eko la máa yọ Oyetola l'Osun- Aregbesola
Bí ẹgbẹ́ APC ṣe yọ Ambode l'Eko la máa yọ Oyetola l'Osun- Aregbesola
Kìí ṣe ohun tó pamọ́ pé àárín gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola àti gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà, Rauf Aregbesola kò dán láti bí ọjọ́ mélòó sẹ́yìn.
Láìpẹ́ yìí ni Aregbesola níbi ayẹyẹ kan nílùú Ilesa fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Osun kò ṣọ̀kan.
Nlíbi ayẹyẹ náà ló tún ti jẹ́ kó hàn pé kò sí àníàní pé ti ikọ̀ alátakò gómìnà Oyetola ni òun ń ṣe.
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- A ṣì lè yanjú ọ̀rọ̀ Ukraine ní ìtùbí-ìnùbí - Russia
- Ọmọ ọdún 18 dèrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn pẹ ó gún akẹgbẹ́ lọ́bẹ pa
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dárúkọ àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tó ń bá Abba Kyari ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé oògùn olóró
- Barrister ló sọ mí di èèyàn ńlá - Ayinla Kollington
- Ki lo ṣokunfa ikọlu to n waye si ẹni to ba wọ aṣọ Sunday Igboho tabi Yoruba Nation n'Ibadan?
- Makinde buwọ́lu Sẹ́nẹ́tọ̀ Lekan Balogun gẹ́gẹ́ bí Olubadan tuntun
Bawo ni ọrọ ṣe bẹrẹ?
Ṣaájú àkókò tí Aregbesola fi ibi tí tó fì sí hàn yìí, onírúurú awuyewuye àti àhesọ ọ̀rọ̀ ló ti ń jẹ jáde nípa bí àjọṣe gómìnà Oyetola àti ọ̀gá rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe di kíkan.
Ó jọ wí pé aáwọ̀ àárín wọ́n yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò bí fọ́nrán kan ṣe gba orí ẹ̀rọ ayélujára níbi tí Aregbesola ti sọ pé bí ẹgbẹ́ ṣe lé gómìnà kan ní ìpínlẹ̀ Eko náà ni ọ̀rọ̀ yóò ṣe rí fún Oyetola ní ìpínlẹ̀ Osun.
Nibo ni Ogbeni Aregbesola ti sọrọ yii?
Aregbesola sọ̀rọ̀ yìí níbi ètò ìpòlongo fún Moshood Adeoti ní Ijebu-Jesa lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù Kejì.
Ó ní ''Bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí l'Eko lánàá, gómìnà kan wà ń bẹ̀, ó lòun fẹ́ lọ sígbà kan, ẹgbẹ́ lóhun ò fẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ni ọ́ ṣe?, wọ́n fìbò wọ́n fi lé e."
"Bó ṣe rí l'Eko lánàá, ló ṣe rí l'Osun lónìí o, kò sí bí ajá ṣe ṣorí tí inaki ò ṣe o, kò lè wá kan ti àbúrò yín nísìnyí kẹ ní kò ríbẹ̀."
Bákan náà ni onírúurú orin ọ̀tẹ̀ ni Aregbesola àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń kọ láti sọ pé gómìnà Oyetola kò mú ìlérí tó ṣe fun àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun ṣẹ.
Bẹ́ẹ̀ náà ló tún fi orin rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC láti má dìbò fún Oyetola níbi ètò ìdìbò abẹ́nú tó ń bọ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kọkàndínlógún, ọsù kejì.
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?
Ìyapa wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Osun.
Ó ṣeéṣe kí aáwọ̀ tó wà láàárín Mínísítà fọ́rọ̀ abélé, Rauf Aregbesola àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola túbọ̀ le sii bí Aregbesola ti ṣe làá mọ́lẹ̀ pé ìyapa wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú wọn ní ìpínlẹ̀ náà.
Níbi ìfilọ́lẹ̀ Digital Nigeria Centre (DNC) ní ilé ẹ̀kọ́ Ijesa Muslim Grammar School, Ilesa, Aregbesola ní ikọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC méjì ló wà ní ìpínlẹ̀ Osun.
Ó ní Rasaq Salinsile jẹ́ alága ikọ̀ kan tí Gboyega Famodun sì jẹ́ alága èyí tí ó ń gbè lẹ́yìn Gómìnà Oyetola.
Iṣẹlẹ naa ni ṣisẹntẹle rèé....
Ṣaájú kí Aregbesola tó gúnlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ náà ní akọ̀wé ìròyìn sí gómìnà, Ismail Omipidan ti sọ lórí ètò kan wí pé Aregbesola kò sí lẹ́yìn àwọn ikọ̀ tí kò tẹ̀lé gómìnà ìyẹn ikọ̀ "The Osun Progressives" (TOP).
Omipidan fi kun un pé àìsí Aregbesola níbi ìpàdé TOP àti ikọ̀ ìpẹ̀tù sááwọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lábẹ́ ìdarí Sénétọ̀ Abdullahi Adamu ti fojú hàn pé kò sí lẹ́yìn wọn.
Ó ní Aregbesola kò sọ́ níbi kankan wí pé òun kò ní ṣe àtìlẹyìn fún ọ̀gá òun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Esi wo lo wa jade tẹle ọrọ Aregbesola naa?
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí Aregbesola sọ níbi ètò yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé tí ikọ̀ TOP ni òun ń ṣe àti pé òhun ló ṣe àtiwáyé ikọ̀ tí Salinsile ń darí rẹ̀.
Aṣojú gómìnà níbi ètò náà, Kọmíṣọ́nà fún ìmọ̀ ẹ̀rọ àti sáyẹ̀ǹsì, Dókítà Olawale Babatunde ní Aregbesola jẹ́rìí si pé ti ikọ̀ TOP ni òun ń ṣe.
Ó wá pàrọwà sí Kọmíṣọ́nà àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun láti ṣòótọ́ nídìí làásìgbò ẹgbẹ́ òṣèlú ìpínlẹ̀ náà.
Aregbesola ní fún ọdún mẹ́jọ tí òun fi ṣe gómìnà ní ìpínlẹ̀ Osun pẹ̀lẹ́ kùtù ni gbogbo nǹkan lọ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ láti ìgbà tí òun ti kúrò.





















