Valentine day case: Olaleye Paul rí ẹ̀wọ̀n he ní àyájọ́ olólùfẹ́ ní Ilọrin

Oríṣun àwòrán, Others
Ayajọ Ololufẹ di ayajọ ọjọ lati lọ si ọgba ẹwọn
Bí àwọn kan ṣe ń gba ẹbùn ní àyájọ́ olólùfẹ́ lọ́jọ́ Ajé, ẹ̀wọ̀n oṣù méjìdínlógún ni Olaleye Paul, ẹni ọdún márùndínlọ́gbọ̀n rí he ní Ilorin.
Onídàjọ́ Muhammad Sani ti ilé ẹjọ́ gíga ìlú Ilorin rán Olaleye Paul, fẹ́sùn ṣíṣe eèrú lórí ẹ̀rọ ayélujára.
- Afurasí tọkọtaya ta ẹ̀yà ara fún ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin náírà- Ọlọ́pàá
- Barrister ló sọ mí di èèyàn ńlá - Ayinla Kollington
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dárúkọ àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tó ń bá Abba Kyari ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé oògùn olóró
- Makinde buwọ́lu Sẹ́nẹ́tọ̀ Lekan Balogun gẹ́gẹ́ bí Olubadan tuntun
- Wo ohun méjé tó yẹ kí o mọ̀ nípa Abba Kyari, ọ̀gá ọlọ́pàá tí wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn
- Oríṣìíríṣìí aṣọ aláràǹbarà láwọn òṣèré tíátà fi ṣe àyájọ́ ọjọ́ olólùfẹ́
- Ẹgbẹ́ Olùkọ́ Fásitì ASUU bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì olóṣù kan lónìí
Olaleye wà lára àwọn afurasí tí ẹ̀ṣọ́ àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu (EFCC), tẹ̀ka ìlú Ilorin kó ní ìlú Ogbomoso, ìpínlẹ̀ Oyo lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá, ọdún 2021.
Ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí Paul lọ́rùn ni pé ó purọ́ láti fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí Roven Riley lórí ẹ̀rọ Gmail [email protected] pẹ̀lú èròńgbà láti gbá ènìyàn kan lówó $154.82 èyí tó lòdì sí òfin tó dé ṣíṣe èrú lórí ayélujára tọdún 2015.
Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀, Onídàjọ́ Sani ní Paul jẹ̀bi ẹ̀sùn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n fi kàn án tó sì jù ú sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan àbọ̀.
Kini Adajọ sọ pe ki Paul tun ṣe?
Bákan náà ni Adájọ́ ní Paul ní àǹfàní láti san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn dípò kó lọ sí ẹ̀wọ̀n.
Ilé ẹjọ́ ní fóònù alágbéká iPhone 6 tí wọ́n gbà lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tí wọ́n mú u ti di ti ìjọba àpapọ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Adájọ́ ní kí ó san owó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́rin Dọ́là fún ẹni tó lù ní jìbìtì.
















