Lekan Balogun: Makinde buwọ́lu Sẹ́nẹ́tọ̀ Lekan Balogun gẹ́gẹ́ bí Olubadan tuntun

Oríṣun àwòrán, Lekan Balogun
Lẹyin ọ rẹyin, Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti buwọlu iyansipo Sẹnẹtọ Lekan Balogun gẹfgẹ bi Olubadan ilẹ Ibadan tuntun.
Sẹnẹtọ Balogun to jẹ Ọtun OLubadan tẹlẹ ni Olubadan kejilelogoji ti yoo gori apere ọba ilẹ Ibadan.
Makinde buwọlu iyansipo Sẹnẹtọ Balogun lẹyin ti igbimọ afọbajẹ ilẹ Ibadan orukọ rẹ ranṣẹ si gomina.
- Ìjà ni tọkọtaya ní àwọn fẹ́ bá àbúrò mi àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ parí kí wọ́n tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò - ẹ̀gbọ́n olóògbé
- Àjọ NDLEA ń wá ọ̀gá ọlọ́pàá Abba Kyari lórí ẹ̀sùn gbígbé òògùn olóró ''cocaine''
- Àgbáríjọpọ̀ èèyàn sẹkúpa ọkùnrin kan lórí ẹ̀sùn pé ó dáná sun Kurani
- Oríṣìíríṣìí aṣọ aláràǹbarà láwọn òṣèré tíátà fi ṣe àyájọ́ ọjọ́ olólùfẹ́
- "Ẹ̀yin obìnrin, ẹ fi òdòdó ṣe ẹ̀bùn ọjọ́ olólùfẹ́ fún ọkùnrin dípò kẹ gbà kó já òdòdó ara yín"
- Ẹ̀yin òṣèrè tíátà, ẹ ní ṣùúrù de àsìkò Ọlọ́run, ẹ máṣe kánjú kọjá kádàrá - Madam Ṣajẹ
- Ìdí tí mo fi ní ọ́jọ́ ikú ni ọ̀la ọjọ́ 'Valentine' fún àwọn kan- Mike Bamiloye
Ninu atẹjade kan tti akọwe iroyin gomina, Taiwo Adisa fi sita lọjọ Aje, Makinde ki Olubadan tuntun ku oriire.
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Oyo gbadura pe alaafia ni yoo fi lo akoko rẹ gẹgẹ bi ọba ilẹ Ibadan.
Makinde ni lorukọ gbogbo eeyan ipinlẹ Oyo ni oun gbadura aṣeyọri ati ilọsiwaju fun Olubadan tuntun lori oye.
Bakan naa ni Makinde ti buwọlu irọloye awọn ọba ilẹ Ibadan ti wọn n de ade tẹlẹ.
Gomina ṣe eyi ni ibamu pẹlu iwe ofin Naijiria ati idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo lori ọrọ naa.












