Abba Kyari arrested: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fa Kyari àtàwọn agbófinró mẹ́rin míì lé àjọ NDLEA lọ́wọ́

Abba Kyari

Oríṣun àwòrán, @Naija_PR

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti fi ṣikun ofin mu ọga ọlọpaa, Abba Kyari atawọn mẹrin miran ti wọn jẹ agbofinro.

Awọn ọlọpaa naa ti wọn mu pẹlu Kyari ni ACP Sunday Ubuah, ASP Bawa James, Simon Agrigba, ati John Nuhu, nigba ti ẹnikarun un wọn, ASP John Umoru ti na papa bora.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dárúkọ àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tó ń bá Abba Kyari ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé oògùn olóró

Ninu atẹjade kan ti igbakeji alukoro ileṣẹ ọlọpaa, Muyiwa Adejobi fi lede niluu Abuja lo ti sọrọ to pọ.

O ni awọn mu awọn ọlọpaa naa nitori wọn lọwọ ninu iwa ọdaran to rọ mọ iditẹ, aṣilo ipo gẹgẹ bii ọlọpaa, iwa jẹgudujẹra ati pe wọn gbimọ pọ pẹlu awọn to n gbe oogun oloro.

Adejobi sọ pe awọn ti fa awọn eeyan naa le NDLEA lọwọ fun iwadii to peye.

O ni "A mu awọn ọlọpaa ọhun lẹyin iroyin to tẹ wa lọwọ lati ọdọ awọn NDLEA lọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdu 2022 yii."

"Gẹgẹ bii aṣa ileeṣẹ wa, ọga agba ọlọpaa paṣẹ iwadii abẹnu to peye lori ẹsun naa, a si ṣe bẹẹ."

Àkọlé fídíò, Kong Thong: Àwọn òbí máa ń súfèé kọrin tàbí hu láti pe ọmọ tó bá dàgbà

O fi kun pe "Iwadii ti a kọkọ ṣe fi han pe ọwọ tẹ awọn eeyan meji kan ti wọn maa n gbe oogun oloro lati ilẹ okeere, iyẹn Chibunna Patrick Umeibe ati Emeka Alphonsus ni papakọ ofurufu ilu Enugu lasiko ti wọn n bọ lati ilu Addis Ababa lọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2022 yii."

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

Adejobi sọ siwaju si pe iwadii fi han pe awọn afurasi naa ni ibaṣepọ pẹlu awọn oṣiṣẹ NDLEA kan ni papakọ ofurufu naa, ti wọn n san owo oṣu fun.

Àkọlé fídíò, Wo aburú àti ìpalára tí òògùn olóró Kush tuntun yí n ṣé ní Sierra Leone

Gẹgẹ bii ohun to sọ, akara ibaṣepọ Abba Kyari atawọn afurasi naa tu sepo lasiko ti wọn ni ko lọ rọọkun nile nitori ẹsun ti wọn fi kan lori ibaṣepọ rẹ pẹlu afurasi onijibiti ori ayelujara, Hushpuppi.

O pari atẹjade naa pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni faye gba iwa ibajẹ oṣiṣẹ rẹ kankan ati pe awọn yoo tẹle agbekalẹ ofin lori iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Kwara Hijab Crisi: Èdè àwọn Krìsítẹ́nì àti Mùsùlùmí kò yé ara wọn lórí lílo Hijab

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Àjọ NDLEA ń wá ọ̀gá ọlọ́pàá Abba Kyari lórí ẹ̀sùn gbígbé òògùn olóró ''cocaine''

Abba Kyari

Oríṣun àwòrán, Other

Ajọ to n gbogun ti oogun oloro ni Naijiria, NDLEA ti sọ pe awọn n wa ọga ọlọpaa, DCP Abba Kyari lori ẹsun pe o n bawọn to n gbe oogun oloro ṣe papọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti kọkọ da Kyari duro lori ẹsun igbimọpọ pẹlu Ramon Abbas tawọn eeyan mọ si Hushpuppi lati jọ lu jibiti ori ayelujara.

Ajọ NDLEA sọ nibi apero awọn akọroyin lọjọ Aje pe ọmọ ẹgbẹ oloogun oloro kan to fi Brazil, Ethiopia ati Niajiria ṣe ibujoko ni Kyari jẹ

Ọrọ ti ajọ NDLEA sọ nipa Abba Kyari

Ajọ NDLEA ṣalaye pe awọn gbe ọrọ naa sita nitori ko fẹ fọwọ so ọwọ pọ pẹlu ajọ naa lori iṣẹ iwadii wọn.

NDLEA ni o ṣenu laanu pe ọkan lara awọn ọlọpaa to yẹ ki wọn maa gbe ofin ro ni wọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn to n ṣe fayawọ oogun oloro.

Àkọlé fídíò, Adunni Ade: Lóòtọ́ọ́ ní àwọn adarí eré máa ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré-bìnrin

Ajọ naa ni Kyari gbọdọ sọ tẹnu rẹ lori ẹjọ oogun oloro kan to n lọ lọwọ eleyii ti wọn ti darukọ rẹ.

NDLEA ni ọrọ naa bẹrẹ lọjọ kọkanlelogun oṣu kinni ọdun 2022 nigba ti DCP pe ọfiisi NDLA ni bi ago meji kọja iṣẹju mejila.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Àkọlé fídíò, Damilọla pàdánù ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nítorí ilà kíkọ

Lẹyin naa ni Kyari sọ pe oun n bọ ni ọfiisi NDLEA lẹyin irun Jimọh lati yanju ọrọ kan.

NDLEA ni awọn ni ẹri fọta ati fidio lori ẹsun ti awọn fi kan DCP Kyari.

Àkọlé fídíò, Bunmi Akinnanu: Ọlọ́run kìí fún èèyàn méjì ní orin ẹ̀mí kan ṣoṣo, ẹ jẹ́ ká ṣe sùúrù