Rituals in Ogun: Ará àdúgbò dáná sun afurasí méji tí wọ́n bá orí èèyàn lọ́wọ́ wọn ní àgọ́ ọlọ́pàá ní ọjà ọdàn

Oríṣun àwòrán, crimes channel
Awọn ara adugbo dana sun afurasi meji ti iroyin sọ pe wọn ba ori eyan lọwọ wọn ni adugbo Oja-Odan, nijọba ibilẹ Aria Yewa, nipinlẹ Ogun.
Awọn ọkunrin meji ọhun, Idowu Afolabi ati Johnson Adebiyi, ni ọwọ ọlọpaa ti kọkọ tẹ, ti wọn si fi wọn si ahamọ.
Ṣugbọn, awọn ọdọ adugbo ti inu n bi yabo agọ ọlọpaa naa, ti wọn si fi ipa wọ inu ahamọ tubu ti awọn afurasi naa wa lati wọ wọn jade.
Iroyin sọ pe lẹyin ti wọn wọ wọn jade si gbangba, ni wọn dana sun wọn niwaju agọ ọlọpaa.
Awọn ọdọ lo mu awọn ọkunrin naa pẹlu ori eeyan to jọ eyi ti wọn ṣẹṣẹ ge, ko to o di pe awọn ọlọpaa ko wọn lọ si agọ wọn.
- Wọ́n ti rí òkú eèyàn mẹ́ta yọ kúrò lábẹ́ ilé tó dàwó ní Yaba
- Àwọn jàndùkú agbébọn tún kọlu ilé Sunday Igboho, èèyàn kan dèrò ọ̀run
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ tọkọtaya tó gbé ẹ̀yà ara ènìyàn pamọ́ sínú yàrá l'Ogun
- "A ti ṣetán láti gbógun ti ikú àìtọ́jọ́ tó ń pa àwa akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU"
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tó gé ojú-ara ọmọdébìnrin ọdún mẹ́fà fún ètùtù ọlà
Ko ju bi i wakati kan lẹyin igba naa, ni awọn ọdọ to mu wọn, lọ si agọ ọlọpaa ti wọn si n pariwo pe idajọ gbọdọ waye lori wọn loju ẹsẹ.
Bi awọn ọlọpaa ko ṣe yọnda awọn afurasi ọhun fun wọn, lo mu ki wọn o fi ipa ko wọn jade, ti wọn si dana sun wọn.
Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ?
Gẹgẹ bi ohun ti awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ, owurọ kutu jọ Satide, ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun 2022, ni ọwọ awọn ara adugbo Oja Odan tẹ ọkunrin meji.
Bi ọwọ ṣe tẹ wọn, wọn ko wọn lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni agbegbe naa, pẹlu ẹsun pe wọn ba ori tutu to jẹ ti eeyan ninu apo to wa lọwọ awọn afurasi.
- Wo àwòràn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Abeokuta lásìkò ikú Rofiat tí Soliu àti Mustaqim pa
- Ilé ẹjọ́ ju ọmọkùnrin mẹ́rin tó fi olólùfẹ́ ọ̀kan lára wọn ṣe òògùn owó sí ẹ̀wọ̀n
- 'Mílíìkì ni a fẹ́ máa fi ẹbu tí a bá ri lára orí Sofia ti a jó pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé á máa di olówó'
- "Ariwo tí Sofiat pa ló fu ará àdúgbò lára, tí ọwọ́ fi tẹ̀ wá"
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ tọkọtaya tó gbé ẹ̀yà ara ènìyàn pamọ́ sínú yàrá l'Ogun
- Ọwọ́ tẹ oníṣègùn níbi tó ti ń sin ọmọ tuntun láàyè pẹ̀lú ọfọ̀ àti àyájọ́
Kini ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ yii?
Lẹyin ti awọn ọdọ dana sun awọn afurasi mejeeji, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun fi ikilọ sita fun araalu pe oun ko ni faaye gba iru iwa bẹẹ mọ.
Agbẹnusọ ọlọpaa, Abimbola Oyeyemi, ti sọró nipa rẹ ninu atẹjade kan lọjọ Aiku, ọjọ kẹtala, oṣu Keji.
O ni pe lasiko ti awọn ọlọpaa n fi ọrọ wa awọn afurasi naa lẹnu wo ni agọ wọn, ni awọn janduku kan ko ara adugbo to pọ wa si agọ ọlọpaa.
Oyeyemi ni pe awọn eeyan naa pọ debi pe agbara awọn ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ lasiko naa ko ka wọn.
"Awọn janduku naa fi ipa gba awọn afurai, wọn lu wọn ni alupa, ki wọn o to dana sun oku wọn."
Ọgbẹni Oyeyemi sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun n fi asiko yii kilọ fun awọn to fẹran lati ma a sẹ idajọ lọwọ ara wọn, pe ki wọn o jawọ ninu iru iwa bẹẹ.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo fi iya to tọ́ jẹ ẹnikẹni to ba tun dan iru rẹ wo.
- Afurasí ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn yìnbọn pa akẹ́kọ̀ọ́ tó ń múra NYSC àti ọlọ́kadà l'Ẹdẹ
- Ọlọ́pàá kánkan kò ku sùgbọ́n a pa ọkan ninu àwọn tó fẹ́ já ọkọ̀ agbówórìn gbà-Ọlọ́pàá
- Ta ló gbé òkú èèyàn tó ti jẹrà sínú ilé àkọ́patì nílùú Oyo?
- Davido, bá mi kọ ẹsẹ orin kan nínú àwo orin mi, jẹ́ ká da ayé láàmú - Portable Zazzu
- Èèyàn mẹ́jọ kú, ọ̀pọ̀ farapa lásìkò ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàrin Cameroon àti Comoros
- Ṣé lóòtọ́ ni abẹ́ Venus Williams ẹni ọdún 41 ṣì dí pa, tí kò tíì bá ọkùnrin kankan lájọṣepọ̀ rí?
- "Ariwo tí Sofiat pa ló fu ará àdúgbò lára, tí ọwọ́ fi tẹ̀ wá"
- Femi Falana kò gba kọ́bọ̀ fún ìgbẹ́jọ́ Timothy Adegoke àmọ́ aráàlú ń dáwó jọ - Ẹ̀gbọ́n olóògbé
Oyeyemi ṣalaye pe afurasi ni afurasi yoo ma a jẹ, titi ile ẹjọ yoo fi sọ pe o jẹbi ẹsun yoowu ki wọn o fi kan an.
Ni bayii, kọmisonna ọlọpaa nipinlẹ naa ti paṣẹ pe ki iwadii o bẹrẹ lati mu awọn janduku to dana sun awọn afurai afini ṣe oogun owo naa.
Iṣẹlẹ ifini ṣoogun owo to ti waye nipinlẹ Ogun sẹyin
Iroyin pe ọwọ tẹ afurasi to fẹ ẹ fi eeyan ṣoogun owo ko ṣẹṣẹ ma a jade lati ipinlẹ Ogun.
Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2022, ni ọwọ tẹ ọdọmọkunrin mẹrin tọjọ ori wọn wa labẹ ogun ọdun pe, wọn pa ọrẹbinrin ẹnikan lara wọn fun oogun owo.
Awọn ọdomọkunrin naa ni ọwọ ọdẹ adugbo tẹ ni, nibi ti wọn ti n dana sun ori Sofiat Okeowo.
Wọn jẹ wọ pe ori ayelujara Facebook ni awọn ti kọ nipa oogun owo naa.
Yatọ si eyi, ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla, oṣu Keji, ni ọwọ tẹ tọkọtaya kan, Kehinde Oladimeji ati Jumoke Raji, ni agbegbe Leme, nilu Abeokuta bakan naa, fun pe wọn ba ẹya ara eeyan ninu yaara wọn.
Alabagbe tọkọtaya naa kan, lo lọ fi ẹjọ sun ni ile Baalẹ agbegbe naa pe oorun ti ko dara n jade lati yara awọn afurasi ọhun.
Nigba ti awọn ọlọpaa wọ yara naa ni wọn ba ẹya ara eeyan ninu ike kan.
Ọjọ siẹ sẹyin si ni iroyin kan jade pe araalu ri oku eeyan kan, ti ẹya ara rẹ ko pe ni agbegbe Leme tọwọ ti tẹ tọkọtaya yii.
Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ pe awọn yoo sẹ iwadii lati mọ boya ara oku naa ni tọkọtaya ọhun ti yọ awọn ẹya ara ti wọn ba ninu yara wọn.
























