Ede Cult Attack: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Osun ní àwọn ń wá 'ọkọ ìlú'

Oríṣun àwòrán, other
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun ni awọn ti n wa afurasi ọdaran kan, ti orukọ rẹ n jẹ Rasheed, ti ọpọ mọ si "Ọkọ ilu' fun iṣẹlẹ iyinbọn paniyan kan to waye nilu Ẹdẹ lọjọru.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun ṣalaye fun BBC News Yoruba pe, o ti pẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa ti n dọdẹ afurasi naa ṣugbọn ti ẹja rẹ ko si ti i ko sinu awọn ọlọpaa fun oniruuru iwa ọdaran to ti hu nilu Ẹdẹ ati ipinlẹ Ọṣun.
- Wo ìdí tí ilé ẹjọ́ àgbáyé ṣé ní kí Uganda sàn $325m fún DR Congo
- Ṣé lóótọ́ ni Oluwo bèèrè ₦20m lọ́wọ́ ìjọba Osun láti ṣe ìgbéyàwó ní Kano?
- Ẹ wo bí ‘dókítà’ ṣe yọ àpò ẹyin ilé ọmọdébìnrin kan lásìkò iṣẹ́ abẹ́
- Ìjọba Oyo àti IBEDC parí ìjà, fẹnu kò láti ṣiṣẹ́ pọ̀ fún ànfààní aráàlú
- Ìjà abẹ́nú bẹ̀rẹ̀ lẹ́gbẹ́ NURTW l‘Eko, nǹkan kò fara rọ
Ki lo ṣẹlẹ gangan?
Ni alẹ Ọjọru ọjọ kẹsan oṣu ọdun 2022 ni iro ibọn dun lakọlakọ lagbegbe Bode, nitosi Agbalemọbode nilu Ẹdẹ.
Iro ibọn yii da ọpọlọpọ ikayasoke silẹ lagbegbe naa ati gbogbo ilu Ẹdẹ lapapọ.
Nigba ti ohun gbogbo yoo fi kofiri, oku arakunrin meji kan ti wa nilẹ pẹlu ọpọlọpọ oju ibọn lara wọn.
Hassan Adedeji, akẹkọjade ileewe gbogboniṣe Poly apapọ, Federal Polytechnic, Ẹdẹ ti wa ninu agbara ẹjẹ.
Ọlọkada kan nilu Ẹdẹ ni ẹni keji ti wọn yinbọn fun.
Oloogbe n mura lati lọ sinru ilu, ni wọn pa a:
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe nnkan bii agogo mẹwaa alẹ Ọjọru ni iṣẹlẹ naa waye.
Ninu ọrọ to sọ fun BBC News Yoruba, alukoro ile ẹkọ giga gbogboniṣe naa, Alagba Ṣọla Lawal ṣalaye pe Hassan Adedeji lorukọ akẹkọọ naa.
Ẹka imọ nipa akoso Banki ati iṣuna ni ẹkọ to kẹkọ gboye ninu rẹ.
Alagba Lawal tun jẹ ko di mimọ pe, Hassan n mura ati ṣe awọn ayẹwo gbogbo to yẹ lati le e gba iwe ipe fun isinru ilu iyẹn 'NYSC Call up letter' rẹ.
O fi kun un pe wọn ti sin oku akẹkọọ naa ni ilu Iwo, to jẹ ilu abinibi rẹ lọjọbọ.
Ki lo ṣẹlẹ lẹyin iku rẹ?
Awọn akẹkọọ ileẹkọ naa ya bo igboro ilu Ẹdẹ lati ṣewọde fi ẹhonu wọn han lori iṣẹlẹ naa.
Gbogbo awọn ikorita ati ojuna ni wọn dana taya ọkọ si. Kiakia lawọn to ni ṣọọbu ati ileeṣẹ si agbegbe ile ẹkọ giga naa ti tilẹkun ọrọ aje wọn ti wọn si sa asala fun ẹmi wọn.
Alukoro ile ẹkọ giga Federal Polytechnic Ẹdẹ, Alagba Ṣọla wa rọ awọn akẹkọọ ibẹ lati bu omi suuru mu nitori awọn alaṣẹ ileewe naa ko fi ọrọ igbayegbadun wọn ṣere rara yoo si ṣe atilẹyin gbogbo to ba yẹ fun awọn ọlọpaa.
Bẹẹ gẹgẹ ni alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Arabinrin Yẹmisi Ọpalọla ṣalaye pe, kọmiṣọna ọlọpaa, Ọlawale Ọlọkọde ti paṣẹ ki awọn ikọ kogberegbe gbogbo to wa nikalẹ ṣiṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Bakan naa lo pasẹ pe ki wọn fi panpẹ ofin mu awọn eeyan kọkan ti aje iwa ibajẹ naa ba ṣi mọ lori.



















