Oyo IBEDC Crisis: Òkùnkùn biribiri n'Ibadan torí aáwọ̀ ìjọba àti iléeṣẹ́ amúnáwá

Oríṣun àwòrán, Oyo Satet Government
Ìjọba ipinlẹ Oyo ati ileeṣẹ ina mọnamọna IBEDC ti pẹtu si aawọ lori owo ina ti ijọba jẹ ati owo ori ti ileeṣẹ IBEDC naa jẹ wọn eyi to wahala silẹ ni Ibadan.
Ni Ọjọru ni ijọba ipinlẹ Oyo gbe ileeṣẹ IBEDC ti pa lẹyin ti wọn gbaṣẹ nile ẹjọ gíga lati ṣe bẹẹ nitori owo ori bii irinwo mílíọ̀nù ti ijọba ni IBEDC n jẹ.
Ijọba gbe igbesẹ yii lẹyin ti ileeṣẹ IBEDC ja ina olu ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Oyo ni Agodi niluu Ibadan lori ẹsun pe ijọba n jẹ owo ina to to miliọnu lọna ọtalenirinwo o din mẹwa naira (N450m).
- Ìjọba Oyo àti iléeṣẹ́ amúnáwá wọ̀yá ìjà torí gbèsè tí wọn jẹ ara wọn
- Ìjà abẹ́nú bẹ̀rẹ̀ lẹ́gbẹ́ NURTW l‘Eko, nǹkan kò fara rọ
- Ọlọ́pàá méjì kú sílé ìwòsàn lẹ́yìn ìdigunjalè ọkọ̀ agbówórìn tó wáyé n'Ibadan - Ọ́lọ́pàá
- Ọlọ́pàá kánkan kò ku sùgbọ́n a pa ọkan ninu àwọn tó fẹ́ já ọkọ̀ agbówórìn gbà-Ọlọ́pàá
- Ìjọba Oyo gba adé lórí àwọn baálẹ́ àti Mogaji tí Ajimọbi sọ di ọba ní Ibadan
- Mo ní ẹ̀ṣọ̀ ara tó lé ní ₦300m láyé àkọ́kọ́, ti mo ń gbé òògùn olóró
Amọ nigba to jẹ pe arẹmaja kankan ko si, ajamarẹ ni ko sunwọn, ijọba ati ileesẹ amunawa ti joko sọrọ pọ, ti wọn si ti pari aawọ to wa laarin wọn.
Abajade ipade ijọba Oyo ati IBEDC:
Ijọba ipinlẹ Oyo fẹnu ko pẹlu ileeṣẹ IBEDC nibi ipade ti wọn jọ ṣe pọ ni Ọjọbọ, lati yanju aawọ to wa laarin awọn mejeeji ni itubi inubi.
Ninu atejade ti wọn fi sita lẹyin ipade ọhún, ijọba ati ileeṣẹ IBEDC fẹnu ko lati yanju ohun to mu ki ijọba Oyo ti ileeṣẹ IBEDC pa.
Ijọba Oyo ati IBEDC gba lati jọ ṣiṣẹ pọ fun anfaani awọn eeyan ipinlẹ Oyo.
Wọn ṣeleri lati da ina mọnamọna pada fun lilo araalu lẹyin ti ọpọ ti wa ninu okunkun biribiri bayii fun bi ọjọ meloo.
Bakan naa ni wọn tun fẹnu ko lati ri pe awọn araalu ri mita ina mọnamọna gba.
Kọmiṣọnna ohun amuṣagbara ati alumọọni ilẹ, agbẹjọro Temilolu Seun Ashamu ati ọga agba ileeṣẹ IBEDC, John Ayodele ni wọn jọ buwọlu atẹjade naa.
Ipa ti aawọ ijọba Oyo ati IBDEC ni lori araalu:
Yoruba bọ, wọn nibi ti erin meji ba ti ja, koriko ibẹ ni yóò fara gba.
Se ni awọn araalu fori ko wahala ija to wa laarin ileesẹ amunawa ati ijọba ipinlẹ Oyo lori owo ti wọn jẹ ara wọn.
Ileeṣẹ ina mọnamọna IBEDC ti sọ saaju pe ọpọ eeyan niluu Ibadan ni ko ni lanfaani lati lo ina ọba bayii lẹyin ti ijọba ipinlẹ Oyo gbe awọn ọfiisi wọn ti pa.
Ọrọ naa ti di gbọmi sii omi o to laarin IBEDC ati ijọba ipinlẹ Oyo lati bi ọsẹ mélòó bayii.
Idi si ree ti ọpọ agbegbe nipinlẹ Oyo se wa ninu okunkun birimubirimu, eyi to se ipalara pupọ fun ọrọ aje awọn araalu to n lo ina fun ipese isẹ oojọ wọn.

Bi aawọ to mu ki ijọba Oyo ti ọọfisi ileesẹ amunawa IBEDC pa ṣe bẹrẹ niyii:
Atẹjade kan ti ileesẹ to n pawo wọle fun ijọba ipinlẹ Ọyọ fisita lori ohun to fa aawọ laarin rẹ ati ileesẹ amunawa sisọ loju rẹ pe, oun ti gba aṣẹ Adajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ, lati sọ agadagodo si awọn ọọfisi to jẹ ti ileesẹ amunawa jakejado ipinlẹ Oyo.
Wọn ni Adajọ Olagunju lo n gbọ naa ti nọmba rẹ jẹ M/122/2022, eyi to wa laarin ajọ to n pawo wọle labẹnu nipinlẹ Ọyọ ati Ileeṣẹ adani to n ri si apinka ina ijọba, 'Ibadan Electricity Distribution Company', IBEDC.
Olu ileeṣẹ naa to n bẹ ni agbegbe 'Ring Road' nilu Ibadan ni awọn aṣoju ijọba kọkọ ti pa, ki wọn to ko agadagodo lọ si awọn ẹka ileeṣẹ naa to n bẹ ni agbegbe Dugbẹ, opopona Ọjọọ si Iwo Road ati Mọnatan.
Bo tilẹ jẹ pe ile ẹjọ ti fi idi rẹ mulẹ pe owo to le ni irinwo Miliọnu Naira (N400,546,111,11) ni gbese ti ileeṣẹ naa jẹ, ile ẹjọ naa tun ṣe alaye siwaju sii pe, gbese ti o to asiko lati san fun ileeṣẹ naa lọwọlọwọ bayii ni owo to le ni igba Miliọnu naira( N226,756,000.41k).
Eyii ni akotan gbese ti ileeṣẹ naa jẹ fun ọdun 2021.
Bakan naa ni alaye naa fi idi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ naa tun n jẹ awọn gbese mii bii akojọpọ owo ohun elo, owo ori ati ikede ori patako ajuwe laarin ọdun meji sẹyin.
Ileeṣẹ amunawa IBEDC bẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba Oyo lati gbe ọfiisi awọn tipa:
Nibayii, ileeṣẹ IBEDC naa ti fesi gẹgẹ bi wọn ṣe n fi ẹsun kan wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ naa jẹ gbese owo ina ti o to irinwolelaadọta Miliọnu Naira.
Ninu atejade kan ti wọn fi lede lori itakun ayelukara l'Ọjọru, ileeṣẹ IBEDC di ẹbi ru ijọba ipinlẹ Ọyọ lori igbesẹ lati ti olu ileeṣẹ naa ati awọn ẹka rẹ pa.
Ileeṣẹ naa ni ijọba gbe igbesẹ naa nitori obitibiti gbese ti wọn jẹ.
Ileeṣẹ naa tẹsiwaju wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ kan dede bẹrẹ si ni ti awọn ẹka ileeṣẹ naa pa nitori awọn gbese ati aisan owo ori ti wọn sare ko jọpọ lojiji lai fi ọrọ to awọn alakoso ileeṣẹ naa leti lasiko ti o yẹ.
Ileeṣẹ naa ṣe apejuwe ohun ti ijọba ṣe gẹgẹ bi i igbese ti ko ba ofin mu ti o si tun mu ifura lọwọ.
Ki lo mu ijọba ipinlẹ gbe ọfiisi IBEDC tipa ni Ibadan?
Ni nkan bi ọsẹ meji sẹyin ni ileeṣẹ ina mọnamọna IBEDC ja ina ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Oyo lori ẹsun pe ijọba n jẹ IBEDC ni N450m.
Ṣe ẹ mọ pe bi a ṣe gbọn nile ọkọ naa ni a gbọn nile ale.
Ijọba Oyo naa ko beṣu bẹgba nipa titi ọfiisi IBEDC pa lori ẹsun pe ileeṣẹ naa n jẹ ijoba ni owo ori miliọnu lọna irinwo, N400m.
Ọjọru ọsẹ yii gan ni ijọba lọ gbe ọfiisi IBEDC tipa niluu Ibadan.
Ara awọn ọfiisi ti ijọba tipa ọfiisi IBEDC to wa ni Ring Road, Mobil, Oluyole Extension, Dugbe, Ojoo-Iwo Road ati Monatan.
Alaye ijọba ipinlẹ Oyo ree lori titi pa ọfiisi IBEDC:
Kọmiṣọnna eto iroyin, Ọmọwe Wasiu Olatunbosun ṣalaye pe ileeṣẹ IBEDC ko fún ijọba lanfaani lati jiroro pẹlu wọn lori owo ina ti wọn mu wa ki wọn to ja ina mọnamọna ileeṣẹ ijọba Oyo ni Ibadan.
Ọmọwe Olatubosun ni ileẹjọ giga niluu Ibadan lo pàṣẹ pé ki ijọba ipinlẹ Oyo gbe ileeṣẹ IBEDC tipa nitori owo ori ti wọn o san.
"IBEDC ko figba kankan sọ pe awọn ko jẹ owo ori pẹlu iwe ti ijọba ti n kọ si wọn lati bi ọdun meji sẹyin.
Eyi gan an lo jẹ ki ijọba gba ileẹjọ lọ ki adajọ to fun ijọba Oyo lati ti ọfiisi IBEDC pa.
Ọrọ naa ni ọwọ oṣelu ninu ni, bi bẹẹ kọ, IBEDC ko ni huwa bẹyẹn.
Wọn fún wa laye lati duna dura lori owo gọbọi ti wọn mu wa fun wa lati san gẹgẹ bi owo ina ti wọn fi wa ge ina ọhún lọjọ keji.
Ọwọ oṣelu wa níbẹ tori ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ọkan lara awọn ọga agba ileeṣẹ IBEDC.
Wọn o sọ ohun kan nipa owo ori ti wọn n jẹ, ṣugbọn wọn le wa ina ileeṣẹ ijọba lai faye silẹ lati sọ asọyepọ lori iye ti ijọba le san.
Ileeṣẹ IBEDC naa fesi sọrọ ijọba Oyo:
Agbẹnusọ ileeṣẹ IBEDC, Busolami Tunwase to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe bi ijọba ṣe ti ileeṣẹ awọn pa yoo ṣakoba fun araalu.
Tunwase ni "a o le ṣiṣẹ kankan bayii, a o le da awọn onibara wa l'ohun tori ijọba ti gbe awọn ọfiisi wa tipa.
Gbogbo ibi ti ileeṣẹ IBEDC ni ẹrọ amunawa nla nla naa ni o ti wa ni titi pa.
Eleyii tumọ si pe okunkun biribiri ni ọpọ eeyan yoo wa bayii nipinlẹ Oyo.
Ọrọ naa ti wa nile ẹjọ, amọ a n woo ọna ti a le fi yanju ọrọ naa ni itubi inubi ki awọn araalu le maa lo ina mọnamọna lọ gẹgẹ bi wọn ṣe n lọ ba tẹlẹ.

Ìjọba Oyo àti iléeṣẹ́ amúnáwá wọ̀yá ìjà torí gbèsè tí wọn jẹ ara wọn

Oríṣun àwòrán, Oyo state Government
Se ni eruku ija sọ lala ni ọsan Ọjọru laarin ileesẹ to n pin ina ọba IBDEC nipinlẹ Oyo ati ijọba ipinlẹ naa lori gbese ti wọn dijọ jẹ ara wọn.
Ijọba ipinlẹ Ọyọ nipasẹ ajọ to n pa owo wọle labẹnu, lo sọ agadagodo si olu ileeṣẹ ati awọn ẹka ti o jẹ ti Ileeṣẹ adani to n ri si apinka ina ijọba, 'Ibadan Electricity Distribution Company', IBEDC, nilu Ibadan.
Igbesẹ naa ko si sẹyin ẹsun aisan owo ori to to irinwo Miliọnu Naira, ti wọn fi kan ileesẹ amunawa naa.
- Wo orílẹ̀èdè míì l‘Áfíríkà tí ìfipá gbàjọba tún ti ń rúgbó bọ̀
- "Ẹ̀rù kí Naijiria má ti bodè lo n ba Benin Republic, tó ṣe mú Sunday Igboho mọ́lẹ̀"
- Àìsàn wo ló ń ṣe Opeyemi Ayeola tó tún fi dèrò ilé ìwòsàn?
- Small Mummy, aláwàdà ọmọ ọdún mẹwàá gba ẹ̀bùn ọkọ̀ olówó iyebíye
- Lóòótọ́ ní àṣìṣe wáyé lórí ìṣẹlẹ ìfipábọ́mọdélòpọ̀ nígbà tí mo wà lórí àkóso - Pope Benedict XVI
- Onímọ̀ ẹ̀yà ara míì kéde okùnfa ikú míràn tó pa Sylvester Oromoni

Oríṣun àwòrán, Oyo state government
Ki lo de ti ijọba Oyo se ti ọọfisi ileesẹ amunawa pa?
Atẹjade kan ti ileesẹ to n pawo wọle fun ijọba ipinlẹ Ọyọ fisita lori ohun to fa aawọ laarin rẹ ati ileesẹ amunawa sisọ loju rẹ pe, oun ti gba aṣẹ Adajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ, lati sọ agadagodo si awọn ọọfisi to jẹ ti ileesẹ amunawa jakejado ipinlẹ Oyo.
Wọn ni Adajọ Olagunju lo n gbọ naa ti nọmba rẹ jẹ M/122/2022, eyi to wa laarin ajọ to n pawo wọle labẹnu nipinlẹ Ọyọ ati Ileeṣẹ adani to n ri si apinka ina ijọba, 'Ibadan Electricity Distribution Company', IBEDC.
Olu ileeṣẹ naa to n bẹ ni agbegbe 'Ring Road' nilu Ibadan ni awọn aṣoju ijọba kọkọ ti pa, ki wọn to ko agadagodo lọ si awọn ẹka ileeṣẹ naa to n bẹ ni agbegbe Dugbẹ, opopona Ọjọọ si Iwo Road ati Mọnatan.
Bo tilẹ jẹ pe ile ẹjọ ti fi idi rẹ mulẹ pe owo to le ni irinwo Miliọnu Naira (N400,546,111,11) ni gbese ti ileeṣẹ naa jẹ, ile ẹjọ naa tun ṣe alaye siwaju sii pe, gbese ti o to asiko lati san fun ileeṣẹ naa lọwọlọwọ bayii ni owo to le ni igba Miliọnu naira( N226,756,000.41k).
Eyii ni akotan gbese ti ileeṣẹ naa jẹ fun ọdun 2021.
Bakan naa ni alaye naa fi idi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ naa tun n jẹ awọn gbese mii bii akojọpọ owo ohun elo, owo ori ati ikede ori patako ajuwe laarin ọdun meji sẹyin.
Ijọba Oyo sare ko gbese owo ori ojiji jọ si wa lọrun ni lati gbẹsan gbese gọbọi to jẹ wa - IBDEC
Nibayii, ileeṣẹ IBEDC naa ti fesi gẹgẹ bi wọn ṣe n fi ẹsun kan wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ naa jẹ gbese owo ina ti o to irinwolelaadọta Miliọnu Naira.
Ninu atejade kan ti wọn fi lede lori itakun ayelukara l'Ọjọru, ileeṣẹ IBEDC di ẹbi ru ijọba ipinlẹ Ọyọ lori igbesẹ lati ti olu ileeṣẹ naa ati awọn ẹka rẹ pa.
Ileeṣẹ naa ni ijọba gbe igbesẹ naa nitori obitibiti gbese ti wọn jẹ.
Ileeṣẹ naa tẹsiwaju wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ kan dede bẹrẹ si ni ti awọn ẹka ileeṣẹ naa pa nitori awọn gbese ati aisan owo ori ti wọn sare ko jọpọ lojiji lai fi ọrọ to awọn alakoso ileeṣẹ naa leti lasiko ti o yẹ.
Ileeṣẹ naa ṣe apejuwe ohun ti ijọba ṣe gẹgẹ bi i igbese ti ko ba ofin mu ti o si tun mu ifura lọwọ.
Ninu atejade ti ileeṣẹ naa buwọlu, akakoso agba, Onimọẹrọ John Ayọdele ṣe alaye wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ n jẹ ileeṣẹ naa ni gbese irinwolelaadọta Miliọnu Naira laarin ọdun mẹta.
O ṣe alaye wi pe gbogbo ipa ni ileeṣẹ naa ti sa lati gba owo naa, ṣugbọn pabo ni gbogbo igbiyanju wọn jasi.
Ayodele ni igbesẹ naa yoo ko ipa buburu lori okoowo ileeṣẹ naa ati gbogbo anfani ti awọn onibara wọn ni ẹtọ si.
O parọwa si Gomina Ṣeyi Makinde lati ṣe agbeyẹwo ọrọ naa fun anfani awọn ti ọrọ kan nitori aiṣe bẹẹ yoo pakun iṣoro aini ina ọba nipinlẹ Ọyọ.