Sunday Igboho: Yomi Aliyu ní àhesọ ọ̀rọ̀ lásán ni pé Igboho yóò jẹ́jọ́ ní Naijiria, kò jọ́

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/Instagram
Agbẹjọro fun Sunday Igboho, Oloye Yomi Aliyu ti sọ fun BBC Yoruba pe bi igba ti eeyan n fi juuju bo eeyan loju ni ọrọ ti Agbẹjọro Agba Naijiria, to tun jẹ minisita eto idajọ, Abubakar Malami sọ.
Abubakar Malami sọ pe Sunday Igboho yoo ṣi jẹjọ ni Naijiria to ba gba ominira lorile-ede Benin.
Ọjọ Iṣẹgun ni Malami sọ ọrọ naa lori amohunmaworan Channels TV.
- Lóòótọ́ ní àṣìṣe wáyé lórí ìṣẹlẹ ìfipábọ́mọdélòpọ̀ nígbà tí mo wà lórí àkóso - Pope Benedict XVI
- Àìsàn wo ló ń ṣe Opeyemi Ayeola tó tún fi dèrò ilé ìwòsàn?
- Small Mummy, aláwàdà ọmọ ọdún mẹwàá gba ẹ̀bùn ọkọ̀ olówó iyebíye
- Onímọ̀ ẹ̀yà ara míì kéde okùnfa ikú míràn tó pa Sylvester Oromoni
- Ìjọba ti rí ibi tí àmúlùmálà epo gbà wọ Nàìjíríà - NNPC
- 13m èèyàn wà nínú ewú ìyàn torí ọ̀dá òjò ọlọ́jọ́ pípẹ̀ - UN
Àmọ́ ẹni to jẹ agbẹjọro Sunday Igboho ni Naijiria sọ pe onibaara oun ko ni ẹjọ kankan lati jẹ, ni orile-ede Benin Republic.
Eyi ni Amofin Aliyyu sọ pẹlu alaye pe ijọba Benin ko fi ẹ̀sùn kankan kan Igboho.
Ìjọba Naijria ati Benin ko ri ẹsun kankan fi kan Sunday Igboho:
"Wọn ni Sunday Adeyemo kan ń gba ilu àwọn kọja lọ si orile-ede Germany ni, eyi ti kii ṣe nkan to tako ofin".
"Wọn sọ pe ìjọba Naijiria lo ni ki awọn da a si ọdọ awọn."
Bi ìjọba Benin ko ṣe ri ẹ̀sùn kankan fi kan an, naa ni ìjọba Naijiria ko le ri ẹ̀sùn kankan."
Amofin Aliyyu sọ pe ile ẹjọ ni Naijiria si ti dajọ pe ipolongo Sunday Igboho fun idasilẹ Yoruba Nation ko tako ofin.
O ni ahesọ ọrọ lasan ni ọrọ ti Malami sọ, nitori pe wọn o mọ nkankan ti wọn tun fẹ ṣe.
Bakan naa lo sọ pe ibẹru ki Naijiria o má ti ẹnu ibode rẹ pa lo mu ki Benin má a ṣe ifẹ ọkan àwọn alaṣẹ Naijiria, ti wọn fi da Sunday Igboho duro.
Yàtọ̀ si eyi, o ni o tun seese ko jẹ nitori ki awọn ọmọ Yoruba le binu ni ìjọba fi n ṣe bayii.

Bí Sunday Igboho ṣe wà ní ẹ̀wọ̀n di àsìkò yìí fihàn pé ìjọba Benin kò bọ̀wọ̀ fún òfin - Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Sunday_igboho1/aareganiadams/Instagram
Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams, ti sapejuwe bi Sunday Adeyemo Igboho ṣi ṣe wa ni ahamọ lorilẹ-ede Benin lai gbe lọ sile ẹjọ, gẹgẹ bi ifiyajẹni.
Adams sọ ninu atẹjade ti oluranlọwọ pataki rẹ lori eto iroyin, Kehinde Aderemi fi sita ni ọjọ Isẹgun, pe nnkan to ba ni lọkan jẹ ni bi ijọba orilẹ-ede Benin ṣe n ṣe ọrọ Igboho.
O ni fifi Sunday Igboho si ahamọ fun igba pipẹ, lai ṣe igbẹjọ kankan nipa rẹ fihan pe ijọba orilẹ-ede Benin ko bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Ọ̀nà àtijẹ lára Nàíjíríà ní orílẹ̀èdè Benin ń wá tó ṣe fi oṣù mẹ́fà kún àhámọ́ Sunday Igboho"
- Ìjọba ti rí ibi tí àmúlùmálà epo gbà wọ Nàìjíríà - NNPC
- Ọ̀pọ̀ oníbàráà yan ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ lódì láti fi ẹ̀hónú hàn sí ìjọba
- Àrídájú pé ìdájọ òdodo yóò wáyé ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fojú hàn ni lórí ikú Adegoke - Agbẹjọ́rò ẹbí olóògbé
- Ìjọba le gbé ọ̀gá ọlọ́pàá Abba Kyari lọ Amẹ́ríkà láti lọ jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn jìbìtì pẹ̀lú Hushpuppi - Malami
- Ìjọba àpapọ̀ yọwọ́ kúrò nínú ẹjọ́ tó ń bá Rahmon Adedoyin àtàwọn afurasí míì ṣe lórí ikú Adegoke
Adams sọ ọrọ naa lẹyin ti Minisita fun eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami sọ pe Sunday Igboho yoo si foju wina ẹjọ ni Naijiria, to ba gba ominira ni Benin Republic.
O ni "o fojuhan pe ijọba Benin ti n mu ọrọ Igboho kọja ọrọ ofin.
"Ko si ọ̀ràn kankan ti Sunday Igboho dá, o kan n fi aidunnu rẹ han si bi nkan ṣe n ri nilẹ baba rẹ ni, eyi to si ba ofin mu."
Oloye Adams sọ pe iwa ìjọba Benin fihan pe ko si idajọ ododo rara, paapaa bi wọn ko ṣe ri ẹ̀sùn iwa ọ̀daràn kankan ka si lẹsẹ.
O ni o ṣeni laanu pe wọn n tẹ" ẹtọ ọmọkùnrin naa mọlẹ, pẹlu bo ṣe ti wa ni ahamọ ju oṣù mẹ́fà lọ lai jẹ pe wọn fi ẹsun ọdaran kan.

Báméjì lọ̀rọ̀ Sunday Igboho lè já sí bí ó bá yanjú ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú Benin republic - Abubakar Malami

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/Instagram
Bameji lo ṣeeṣe ki ọrọ Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho o jasi lọdọ ijọba Naijiria lẹyin to ba jẹjọ tan lọdọ ijọba orilẹede Benin Republic.
Minisita feto idajọ lorilẹede Naijiria, Amofin agba Abubakar Malami lo kede bẹẹ lọjọ Aje.
Malami ni ijọba Naijiria ko lee tọrun bọ igbẹjọ Sunday Igboho lorilẹede Benin nitori orilẹede Olominira to ni ofin tirẹ ni wọn jẹ, ofin ilẹ okeere naa si ni wọn ni.
- "Ọ̀nà àtijẹ lára Nàíjíríà ní orílẹ̀èdè Benin ń wá tó ṣe fi oṣù mẹ́fà kún àhámọ́ Sunday Igboho"
- Àwọn aráàlú Igboho bẹ̀rẹ̀ ìjà ẹ̀mí fún ìdáǹdè Sunday Igboho
- "Ajínigbé, ẹ sá kúrò nílẹ̀ Yorùbá, àwa Agbekoya ti jáde"
- Ọ̀kùnrin to tú àṣírí ohùn Olóyè Sunday Igboho lórí fóònù ti bọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou
- Afenifere ń gbèrò láti dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀, àgbà Yoòbá kan ní àbùkù ni yóò gbẹ̀yìn rẹ̀
- "Á lọ yíká gbogbo ilẹ̀ Yorùbá láti bèèrè fún ìdáǹdè Sunday Igboho"
- Ẹ gbé Sunday Igboho kúrò láhàmọ́ ọlọ́pàá wá sí ibi ìpamọ́ mìí ní Cotonou títí tí... - Adájọ́
- Akọ̀ròyìn tó fi fọ́nrán ohùn Igboho síta ti wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou
O fikun pe Sunday Igboho, tii se eekan ajafun idasilẹ orilẹede Yoruba naa tapa si ofin wọn, ti wọn se fi kele ofin gbe e.
Amọṣa, Amofina agba Malami ni ni kete to ba pari pẹlu wọn lọhun ni yoo wa bẹrẹ sii kawọ pọnyin rojọ niwaju ofin lorilẹede Naijiria.
Ko si ohun to kan Naijiria ninu ohun ti oju Igboho ba ri ni Cotonou:
Amofin agba ijọba orilẹede Naijiria naa to ṣalaye awọn ọrọ yii lori ileeṣẹ mohunmaworan Channels lọjọ Aje lasiko to n kopa lori eto kan to nii se pẹlu ọrọ oselu.
O tẹsiwaju pe ohun toju Igboho ba wu ko ri ni Benin Republic, ko si ohun to kan orilẹede Naijiria nibẹ niwọn igba to jẹ pe ofin orilẹede naa lo tapa si.
Ni oṣu keje ọdun 2021 ni awọn agbofinro lorilẹede Benin republic mu Sunday Igboho ni papakọ ofurufu Cardinal Bernadin international Airpot ni ilu Cotonou lori ẹsun pe o lo ayederu iwe irinna silẹ okeere.
Minisita feto idajọ, Abubakar Malami ko ṣai ṣilẹkun oreọfẹ silẹ pe o ṣeeṣe o ki ijọba aarẹ Buhari fi oju sunukun oṣelu wo ọna lati yanju ọrọ Igboho ni tubinubi.

Ṣé lóòtọ́ làwọn ọmọ Sunday Igboho kó COVID-19 ní Germany?

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/Instagram
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati orilẹede Benin Republic sọ pe o ṣeeṣe ki awọn ọmọ aṣiwaju ipe fun idasilẹ Yoruba Nation, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, ti ko aarun COVID-19 bayii ni orilẹede Germany.
Iroyin naa tun fidi rẹ mulẹ pe, iyawo Sunday Igboho, Rọpo funra rẹ to wa ni ilu Cotonou lati igba ti iṣẹlẹ fifi oun ati ọkọ rẹ si ahamọ ti bẹrẹ, ti tẹ ọkọ ofurufu leti gba ilu Germany lọ, nibi ti awọn ọmọ mejeeje wa, ko le lọ ree moju to alaafia wọn.
"Ọjọ Aiku to kọja lọhun ni wọn pe iyawo oloye Sunday Igboho pe ara awọn ọmọ wọn ko ya, eyi lo si mu ki iyawo rẹ, arabinrin Rọpo o kuro ni ilu Cotonou ni ọjọ Aje to kọja lati lọ si orilẹede Germany ko le lọ wo awọn ọmọ naa"
- Mo Abudu fèsì sọ̀rọ̀ tó gbòde pé o torí owó ní ìbálòpọ̀ pẹlú àwọn olóṣèlú
- Femi Falana kò gba kọ́bọ̀ fún ìgbẹ́jọ́ Timothy Adegoke àmọ́ aráàlú ń dáwó jọ - Ẹ̀gbọ́n olóògbé
- Ìná alágbára ba ẹgbẹ́ta eékà ilẹ̀ ọgbà ẹranko jẹ́
- Ipò alága n da omi àlàáfíà ẹgbẹ́ APC rù l‘Oyo
- Ọgá ọlọ́pàá kìlọ fàwọn ọmọ iṣé rẹ tó yan ṣọ́ọ̀ṣì lilọ láàyò jù iṣẹ́ lọ,ẹ gbọ́ ohun tó sọ
- "Ọ̀nà àtijẹ lára Nàíjíríà ní orílẹ̀èdè Benin ń wá tó ṣe fi oṣù mẹ́fà kún àhámọ́ Sunday Igboho"
Ọrọ idojukọ eekan aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ṣi n ja ranyinranyin nilẹ pẹlu bi iroyin tun ṣe jade lọjọ Aiku pe wọn ti fi kun ọjọ rẹ lahamọ lorilẹede Benin Republic.
Ọjọ ti lọ lori iwe irinna Sunday Igboho:
Bakan naa, awọn to sunmọ eekan ajafun idasilẹ orilẹede Yoruba naa n sọ pe ọjọ ti lọ lori iwe irinna orilẹede Germany to n lọ lati ọjọ karun oṣu kinni ọdun 2022.
Nibayii to si n ni idojukọ pẹlu ijba Naijiria ati ti Benin, bawo ni yoo se rọrun fun bayii lati gba iwe irinna miran, ti yoo fi rin irinajo lọ si Germany to ti fẹ gba itọju.
Ka si ni wọn fi Igboho silẹ ni ahamọ, n jẹ ijọba Naijiria setan bi lati fun ni iwe irinna miran, ko le rọrun fun lati lọ sibi to ba fẹ lọ?
Niwọn igba ti kii si se ọmọ onilu lorilẹede Benin, o daju pe ko si bo se le ri iwe iriina ibẹ gba lati lọ silẹ okeere.
Ohun ti ọpọ si n beere ni pe bawo ni yoo se wa rọrun fun Igboho lati lọ gba itọju nilẹ okeere, gẹgẹ bo se n lakaka.
Ki lo ti sẹlẹ sẹyin?
Ogunjọ oṣu kini ọdun 2022 ni wọn gbe Sunday Igboho lọ si ile ẹjọ lati lọ tọwọ bọwe pe o ti lo oṣu mẹfa ni ahamọ leyii to ṣeeṣe ko yẹna fun afikun oṣu mẹfa miran ni ahamọ ijọba ni orilẹede Benin republic.
Ni ọjọ Aiku ni agbẹjọro fun Oloye Sunday Adeyẹmọ, Amofin Ymi Aliyu SAN fi ọrọ sita pe wọn ti fi oṣu mẹfa miran kun iye ọjọ Sunday Igboho ni ahamọ.
Bakan naa lo ṣalaye fun BBC News Yoruba ninu ifọrọwerọ kan lọjọ Aje pe titi di bi a ṣe n sọrọ rẹ yii, ko tii si ẹsun kankan ninu iwe igbẹjọ rẹ to le tọka si pe ẹsun kan pato lo jẹbi rẹ.
Iroyin to n tẹ wa lọwọ n fidi rẹ mulẹ pe awọn agbaagba ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba bii Ọjọgbọn Banji Akintoye pẹlu ọjọgbọn Wale Adeniran pẹlu n lakaka lati wa ojutu si ọrọ naa.
Lara ilakaka naa lo mu wọn de ọdọ olori ileegbimọ aṣofin orilẹede Benin republic, Louis Flafono lati lee r aarẹ orilẹede naa ko da Igboho silẹ lẹyin oṣu mẹfa ti ko si daju pe wọn ri ẹsun kankan ka sii lẹsẹ.
Iroyin to n ja ranyinranyin ni orilẹede Benin bayii ni pe o ṣeeṣe ko jẹ pe awọn alagbara kan lorilẹede Naijiria n ran koko mọ awọn alaṣẹ orilẹede Benin lati lee fi Igboho si ahamọ titi di ẹyin idibo apapọ orilẹede Naijiria lọdun 2023.



















