Ọkan lẹẹ́ fọwọ́ mú, nínú kí ẹ kọjú mọ iṣẹ́ ọlọ́pàá tàbí kí ẹ dì pasitọ ní ṣọ́ọ̀ṣì yín-Ọgá ọlọ́pàá

Aworan ọga ọlọpaa Ndeitunga

Oríṣun àwòrán, NBC

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa lorileede Namibia ti fi ikilọ sita fawọn ọmọ iṣẹ rẹ pe ki wọn ma se jẹ ki sọọṣi lilọ ṣe idiwọ fun wọn lẹnu iṣẹ.

O fi ọrọ yi lelẹ lasiko to ṣe abẹwo si awọn ọlọpaa lagbegbe Ohangwena to jẹ ọkan lara agbegbe mẹrinla orileede naa.

Ọga ọlọpaa Sebastian Ndeitunga sọ pe niṣe lawọn ọlọpaa kan n sa lẹnu iṣẹ lẹyin ti wọn darapọ mọ awọn ṣọọsi kan.

O ni oun ko tako lilọ ṣọọṣi nitori awọn ọlọpaa lẹtọ ijọsin labẹ ofin amọ wọn ni lati mu kan yala ki wọn jẹ ọlọpaa tabi ki wọn si di pasitọ.

''Awọn iwe ohun to ṣẹlẹ lagọ ọlpaa ti dawati,ko si aṣẹ ohun to yẹ ki wọn ṣe nilẹ, awọn ọkọ ọlọpaa dti,ko si amojuto kankan''

''Bẹẹ si ni awọn ọga ọlọpaa n di biṣọọbu ati pasitọ''

Àkọlé fídíò, Wo aburú àti ìpalára tí òògùn olóró Kush tuntun yí n ṣé ní Sierra Leone

O tẹsiwaju pe awọn ọlọpaa n na owo oṣu wọn nina kuna nitori awọn ile ijọsin wọnyi.

O ti wa paṣẹ ki iwadii bẹrẹ lati le mọ awọn ọlọpaa to kundun ki wọn maa sa lnu iṣẹ.

Ta ni ọga ọlọpaa Sebastian Ndeitunga

Ọdun 2005 ni wọn yan Sebastian Ndeitunga sipo ọga ọlọpaa orileede Namibia.

Ninu akọsilẹ lawọn oju opo iroyin, a ri wi pe o jẹ ọga ọlọpaa kan ti ẹnu kii si n lara rẹ.

Bi ko ba maa sọrọ nipa ki awọn ọdọ ma ṣe maa bu awọn olori ilu loju opo ayejura, yoo maa kilọ fawọn babalawo eke ati ile ijọsin to n lu awọn eeyan ni gbajuẹ

Aworan ọga ọlọpaa Ndeitunga

Oríṣun àwòrán, NBC

Ninu fọnran fidio kan taa ri loju opo ileeṣẹ amounmaworan ilẹ Namibia, niṣe ni Ndeitunga n bẹnu atẹ lu awọn eeyan to n ko owo wọn fawn pasitọ eke.

''Nibo lẹẹ ti ri ti pasitọ ti n sọ fun ọmọ ijọ lati ta ilẹ rẹ ko baa le jẹ ọmọ ijọ rere? Nibo lẹ ti ri babalawo to n sọ fun ọkọ pe iyawo rẹ tabi alabagbe rẹ lo wa nidi aarẹ to n ṣe?''

Lọpọ igba ni Sebastian Ndeitunga maa n kilọ fawọn ọlọpaa labẹ rẹ pe ki wọn ma se foju aanu wo awọn ọdaran.

Lọkan rẹẹ,pupọ awọn ile ijọsin igbalode wọnyi ko lojutu ati pe wọn maa n da ori awọn eeyan ru ni to fi mọ awọn ọlọpaa nilẹ naa.