Vagina Cleansing: Dayo Amusa gba obìnrin nímọ̀ràn nípa ọ̀nà mẹ́ta láti dènà òórùn ojú ara

Oju ara obinrin ati Dayo Amusa

Ni ọpọ igba ni awọn ọkunrin maa n se asọ pe oju ara awọn obinrin maa n run, ti yoo si maa mu awọn oorun orisirisi oorun ti ko dara jade.

Awọn miran yoo maa fi apa janu pe oju ara obinrin miran n run bii ẹja, awọn miran ni o n run bii alubọsa nigba ti wọn tun maa n fi oorun naa we nnkan to ti ku, to n run.

Ọpọ igbeyawo lo ti daru nitori oorun oju ara lati ara iyawo nigba ti aimọye ibasepọ ti daru nitori ẹsun yii bakan naa.

Awọn eeyan kan ni bi oju ara obinrin ba n mu oorun aidaa jade, iwa ọbun ati aile tọju ara tabi aini imọtoto lo n faa.

Wọn ni kii se gbogbo igba ni aisan oju ara maa n jẹ ki oorun buruku maa jade lati oju ara obinrin, afọwọfa obinrin miran naa maa n faa.

Eyi lo mu ki ilumọọka osere tiata lobinrin, Dayo Amusa fi se idanilẹkọ loju opo Instagram rẹ fun awọn obinrin lori ọna ti wọn le gba lati tọju abẹ wọn, ti ko fi ni maa run.

Àkọlé fídíò, Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

Koko marun to jẹyọ ninu Idanilẹkọ oju ara lati ọdọ Dayo Amusa:

Ninu idanilẹkọ naa ni Dayo Amusa ti salaye pe oniruuru awọ ni oju ara obinrin ni, to si tun maa n tobi ju ara wọn lọ.

O fikun pe oniruuru ọna gan tun ni ọba oke fi se oju ara obinrin yii, ti aworan oju ara Lagbaja si yatọ si ti Tamẹdo, wọn kii fi bẹẹ jọ ara wọn.

"Awọn oju ara miran pupa, awọn miran dudu, awọn miran tobi nigba ti awọn miran kere pupọ.

Amọ mo n gba ẹyin obinrin nimọran pe ko yẹ ki bi oju ara yin se ri ko ipaya ba yin sugbọn ohun to yẹ ko se koko fun yin ni itọju oju ara yin, ati oorun to n jade nibẹ.

Amọ o, to ba jẹ pe inu yin ko dun si bi oju ara yin se ri, ẹ ko ni naani oorun to ba n jade nibẹ rara, boya o dara ni tabi ko dara.

Idanilẹkọ nipa ibalopọ ti Dayo Amusa gbe soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, dayoamusa/Instagram

Ẹ maa se akiyesi oju ara yin pupọ:

Gẹgẹ bi Dayo Amusa ti wi, o yẹ ki obinrin kọọkan mọ bi abuda ara wọn ti ri, ki wọn si ni oye pupọ nipa bo se maa n sisẹ si.

Bakan naa lo ni o yẹ ki obinrin kọọkan mọ bi ayipada ba ba awọn ẹya ara rẹ, paapaa oju ara.

Ki oye nipa oju ara wa yii ba le ye wa, Amusa ni o yẹ ki obinrin kọọkan maa yẹ oju ara rẹ wo, o kere tan, ẹẹmẹta ni ọsẹ kan.

Bakan naa lo daba pe ki wọn maa lo gilaasi ta tun mọ si Digi lati wo oju ara wọn, ki wọn riran ri daadaa ati awọn omi to n jade nibẹ.

Àkọlé fídíò, Tantra: Ìlànà yìí ló ń kọ́ wa láti fi èémí àti ìṣẹ́po ara gbádùn ìbálòpọ̀

Ẹ maa se imọtoto tabi afọmọ oju ara yin:

Osere tiata naa tun wa awọn obinrin akẹẹgbẹ rẹ nimọran lati maa se itọju oju ara wọn bo se yẹ lati ipasẹ imọtoto to yẹ.

O ni awọn miran fẹran ki irun pupọ wa ni abẹ wọn nigba awọn miran korira ki irun wa ni abẹ wọn, ti wọn si maa n fa irun abẹ wọn danu.

Amọ o ni eyi o wu ki wọn fẹ, boya ki abẹ ni irun pupọ ni abi bẹẹ kọ, ohun to ja ju ni pe ki wọn maa se adinkun irun to wa ni oju ara wọn, ko si maa wa ni mimọ tonitoni.

Ẹ maa jẹ sọ oju ara yii di ọtun loore-koore:

Lakotan, Dayo Amusa wa gba awọn obinrin nimọran lati maa se irun wọn lọjọ, ko maa dun wo, ko wa ni mimọ, ko si maa di ọtun si lojoojumọ.

Àkọlé fídíò, Plights of Widows in Nigeria: Abosede Ilori ní N16,000 ni òun ń gbà fi tọ́jú ọmọ méjì