Private Parts Cleaning: Ṣé ó yẹ kí obìnrin àti ọkùnrin máa fi ọ̀sẹ̀ fọ ojú ara?

Oju Ara obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ wà ní mímọ toni toni láì sí òórùn kankan tó ń jáde lójú ara àti gbogbo ara rẹ.

Àmọ́ kìí se gbogbo ènìyàn ló mọ pe kò yẹ kí àwọn máa fi ọ̀sẹ̀ fọ ojú ara nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu tó wà nínú rẹ.

Lára àwọn àgbègbè ojú ara tó léwu láti máa fi ọ̀sẹ̀ fọ ni ihò tó wà láàárín awẹ ojú ara obìnrin méjèèjì (Vagina Opening).

Àkọlé fídíò, 'Mo ti gba kádàrá lórí bí Ọlọrun ṣe dá mi'

Bákan náà ni ewu ń bẹ nínú fífi ọ̀sẹ̀ fọ ojú ibi tí nǹkan ọkùnrin tí la ẹnu ni òkè téńté.

Kò tán síbè o, kò tún yẹ rárá láti máa fi ọ̀sẹ̀ fọ ihò ìdí wa nibi ti a ti ń ya ìgbé nitori ihò tó wà níbè.

Gẹ́gẹ́ bá ṣe mọ̀ pé láti ìgbà èwe ni wọ́n ti kọ wa lati máa wà ní imototo.

Àkọlé fídíò, Tantra: Ìlànà yìí ló ń kọ́ wa láti fi èémí àti ìṣẹ́po ara gbádùn ìbálòpọ̀

Ìdí sì rèé ta ṣe máa ń naani àwọn ẹ̀yà àti ojú ara wa, kí wọ́n le wà ní mímọ toni toni.

Ó sì yẹ ká le dá ara wa lẹkọọ nípa ba ṣe ń fọ àwọn ibi kọlọfin wa tí kò hàn síta.

Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ kan tí wí, omi nìkan ló yẹ ká máa fi fọ ojú ara wa nítorí àwọn ìdí wọn yìí:

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Idi ti ko fi yẹ lati maa fi ọṣẹ fọ oju ara:

Àwọn ibi kọlọfin kò ní òróró tàbí epo ti yòò jẹ kó máa yọ

Ihò ojú ara obìnrin àti ihò orí nnkan ọkùnrin pẹ̀lú ihò ta fi ń yà ìgbẹ ni kò ní òróró tó le mú kó máa dán tàbí yọ.

Ìdí rèé tí kò fi dára ká máa fi ọ̀sẹ̀ fọ àwọn abala mẹtẹẹta yìí nínú agọ ara wa.

Àwọn kòkòrò kékeré tí a kò le fi ojú rí lo ń ṣe okùnfà àrùn nínú ara wa

Àwọn abala tó ń dán nítorí òróró ara to wà níbẹ̀ sì lo ń gba abọde àrùn fún agọ ara wa.

Ìdí sì rèé tó fi yẹ ká máa lo ọ̀sẹ̀ láti fọ àwọn àgbègbè náà dáadáa.

Àwọn abala tá ń sọ yìí kò nílò ààbò kankan nítorí a ti lo ọ̀sẹ̀ to ń pa kòkòrò láti fọ àwọn kòkòrò kékeré tí a kò le fi ojú rí náà dànù.

Àwọn àrùn tó le jẹyọ ta bá fi ọ̀sẹ̀ fọ ojú ara wa:

Gbígbẹ furu furu:

Níwọ̀n ìgbà tí ojú ara kò ti ní òróró tó le mu kó máa dán bọrọbọrọ, bí a bá fi ọ̀sẹ̀ fọ ó, ojú ara náà yóò gbẹ furu-furu ni.

Bí ojú ara bá sì gbẹ furu furu, eleyi lewu pupọ, tó sì lè ṣe okùnfà àwọn àkóbá kan fún ojú ara yìí, bóyá tí ọkùnrin ní tàbí obìnrin.

Ìdí tó fi dára láti máa fi omi nìkan fọ ojú ara:

Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ tí ṣàlàyé, omi lásán láì ní oogun kankan lo dára láti máa fi fọ ojú ara.

Omi yìí le jẹ tútù, gbígbóná tàbí kó lọ wọ wọ.

Àmọ́ to bá fẹ́ kí àwọn ojú ara yìí túbọ̀ mọ toni toni, o lè lú iyọ̀ díẹ̀ mọ omi láti fi fọ ojú ara naa.

Lákòótán, ó yẹ ká tẹ mọ ara wa leti pé ojú ara obìnrin máa ń fọ ara rẹ fúnra rẹ, omi nìkan ló sì nílò, kii ṣe ọ̀sẹ̀.

Àkọlé fídíò, Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT