Couples get married inside coffin: Wo ìdí tí àwọn tọkọ-taya kan ṣe ń ṣe ìgbéyàwó nínú pósí

Oríṣun àwòrán, romancemeetslife
Lati igba iwasẹ, pẹlu ijoti ayọ ni tọkọ-taya fi maa n ṣajọyọ igbeyawo wọn, ohun ayọ lo si maa n jẹ pẹlu, fun wọn, ati fun awọn ẹbi wọn.
Ni idakeji ẹwẹ, pẹlu ẹkun ati ibanujẹ ni awọn eeyan fi maa n sin oku mọlẹbi wọn to ba jade laye, ti wọn a si gbe irufẹ ẹni bẹẹ sinu posi.
Ṣugbọn iyalẹnu nla lo jẹ pe laye ode oni, kii ṣe oku nikan ni awọn eeyan gbe sinu posi mọ, koda awọn mii a maa fi ara wọn sinu posi pẹlu fun oniruru idi.
Lara idi ti awọn eeyan ṣe n fi ara wọn sinu posi laye ode oni ni lati ṣe igbeyawo.
Bawo ni awọn to n ṣe igbyawo ninu posi yii ṣe maa n ṣe gan?
Agbegbe kan wa ti wọn n pe ni "Bang Rak" to n tumọ si "Ojuko ifẹ" niluu Bangkok ni ile ijọsin Buddha ti wọn ti maa n ṣe igbeyawo naa wa.
Aṣa ki awọn tọkọ-taya maa ṣe igbeyawo wọn pẹlu posi yii ti n di gbajumọ lawọn orilẹ-ede kan bii Thailand.
Iroyin ni ko din ni ọgọrun un obinrin to ti ṣe ayẹyẹ igbeyawo ninu posi nile ijọsin kanni Thailkand yii.

Oríṣun àwòrán, romancemeetslife
Lasiko ti adura ba n lọwọ ni awọn alufaa yoo maa kọrin bii pe awọn to fẹ ṣe igbeyawo naa ti ku, ti yoo si fi orin ọhun sọ wọn di alaaye.
Bakan naa ni igbagbọ wa pe ti awọn mejeji ba ti n dide ninu posi naa, gbogbo ibanujẹ, aisan ati iṣoro to wa ninu aye wọn tẹlẹ ko ni ba wọn dide.
Aṣa naa farajọ igbagbọ awọn ọmọlẹyin Kristi ti wọn n ṣe lasiko iribọmi, ti wọn si gbagbọ pe ti wọn ba ti wọ inu odo, gbogbo ẹṣẹ aye wọn yoo wọnu odo naa pẹlu wọn, eyii ti ko si ni ba wọn dide ti wọn ba ti kuro ninu omi naa, eyii to n tumọ si igbeaye tuntun ninu Kristi.
Bakan naa ni igbagbọ awọn lọkọlaya to n ṣe igbeyawo ninu posi yii ri.
Wọn tun gbagbọ pe bi wọn ti ṣe igbeyawo ninu posi, wọn yoo di oku si awọn ohun atẹyinwa, wọn yoo si di ọtun si igbe aye wọn tuntun pẹlu ọkọ tabi aya wọn.
Ẹwẹ, ileeṣẹ iroyin Bangkok Post jabọ pe ọkan lara awọn alufaa nile ijọsin Buddah ọhun sọ pe wọn tun maa n ṣe irufẹ isin igbeyawo bẹẹ lọna ati ran tọkọ-taya leti pe iku ni opin ohun gbgobgo, ati pe ko si bi eeyan ṣe pẹ to nile aye to, iku ni opin ohun gbogbo.














