Anthony Joshua: AJ ní òun ṣetán láti bá Tyson Fury jà lẹ́yìn tí Usyk fìyà jẹ ẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Abẹṣẹkubiojo ọmọ Naijiria to fi orilẹede UK ṣe ibuje, Anthony Joshua ti sọ pe oun ti ṣetan lati ba Tyson Fury ja.
Bo tilẹ jẹ pe ọmo ilẹ Ukraine, Oleksandr Usyk ti gba bẹniti rẹ mẹtẹẹta lẹyin to lu u lalubami, AJ ni oun si le ja lai si awọn bẹniti yii.
Usyk ya agbado ha sawọn eeyan lẹni lalẹ ọjọ Abamẹta lẹyin to fi ẹṣẹ gbade ori Joshua.
- Pẹ̀lú gbogbo ariwo Ronaldo, ìyà tún gbé Manchester United hánu ní Old Trafford
- Chelsea forí gbálẹ̀ níwájú Manchester city
- Àlàyé rèé lórí bí sọ́jà ṣe lu àgùnbánirọ̀ obìnrin, tó da omi ìdọ̀tí le lórí
- "Ìgbéyàwó wa pé ọdun mẹ́ẹ̀dógún, àmọ́ ìgbà mẹ́wàá péré la ní ìbálòpọ̀"
- Àgùnbánirọ̀ Fidelia ti sọ irú ìdájọ́ tó ń fẹ́ fún sọ́jà tó da omi ìdọ̀tí lé e lórí
- Wo ìdí tí àwọn tọkọ-taya kan ṣe ń ṣe ìgbéyàwó nínú pósí
- Agbẹjọ́rò méjì yọ ẹ̀sẹ́ síra wọn níwájú adájọ ó ku ẹni tí yóò yanjú ọ̀rọ̀
Ṣugbọn ohun ti Joshua n sọ bayii ni pe oun kọkọ fẹ gba bẹniti oun pada lọwọ Usyk.
O ni lẹyin naa ni oun le rona ati ba Fury ja.
Ó bà ni kò bàjẹ́, ẹ wo ọ̀rọ̀ tí Anthony Joshua sọ lẹ́yin tí Usyk fẹ̀ṣẹ̀ gbadé orí rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀
Iku ogun nii pa akinkanju, iku odo nii pa omuwẹ, odo ti a ba foju di nigba mii maa n le gbe ni lọ.
Abẹṣẹkubiojo Anthony Joshua ti sọrọ soke lẹyin ti akẹṣẹ jẹun ọmo ilẹ Ukraine, Oleksandr Usyk fẹṣẹ gbade lọwọ rẹ niluu London lalẹ ọjọ Abamẹta.
Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ AJ nigba ti Usyk bẹrẹ si ni rọ ojo ẹṣẹ le e lori ti ko si lee ta putu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo awọn oludajọ ija lo ni Usyk lo bori AJ pẹlu ayo 117-112, 116-112, 115-113 ni papa iṣere ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham niluu London.
Ọpọ lo ti ro pe Joshua yoo fi ẹṣẹ dabira si Usyk lara ṣaaju ija wọn, ọrọ bẹyin yọ nigba ti wọn bẹrẹ si ni lewọ sira wọn.
Ẹwẹ, Joshua ti fi ọrọ ranṣẹ sawọn ololufẹ rẹ lẹyin to fidi rẹmi tan niluu London.
AJ ni o ba ni, ko bajẹ, ''ọmọ akin, maṣe ba ọkan jẹ, koda gbogbo aye le maa wo lulẹ niwaju rẹ.
Ẹyin araalu London mo nifẹ yin gan an, ẹ ṣe mo dupẹ gbogbo eeyan, ẹ ku gbogbo igba ti ẹ n gbaruku ti mi.''
Onigbọwọ Joshua naa, Eddie Hearn ti sọ ero rẹ lori bi Joshua ṣe fidi rẹmi ninu ija oun ati Usyk.
Hearn ni o ṣeeṣe ki Joshua ti fi oju ṣeṣe tori ko le riran daadaa mọ nigba ti ija naa de ipele kẹsan an.
Usyk ti di abẹṣẹkubiojo lagbaaye bayii lẹyin to gba bẹniiti mẹta lọwọ Joshua.













