Man United vs Aston Villa: ìyà tún gbé Manchester United hánu ní Old Trafford, góòlù kan sódo ni Aston Villa nà wọ́n mọ́lé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O dabi ẹni pe lọwọ yii, ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti ṣe awure iya bayii pẹlu bi wọn ṣe n fidirẹmi lawọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn n gba lẹnu lọwọlọwọ yii.
Ni ifẹsẹwọnsẹ wọn ti wọn gba pẹlu Aston villa ni idije Premier league lọjọ Satide, Manchester united tun fidirẹmi lojude wọn ni Old Trafford, goolu kan sodo ni Aston villa fi na wọn.
Agbabọọlu Aston Villa, Kortney Hause lo fi ori gbe goolu wọle fun Aston villa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kejidinlaadọrun.
Amọṣa oreọfẹ to yọ fun Manchester united lati daa pada tun bọ mọ wọn lọwọ nigba ti Bruno Fernades tun gba pẹnariti ti wọn fun wọn soke fiofio nigba ni ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju to pari rẹ.
Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ, Manchester United lo kọkọ n ta biọbiọ.
Ko pẹ pupọ ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ ti wọn padanu Luke Shaw to jẹ eekan adele wọn lẹyin to ṣeṣe.
Bakan naa ni adele ẹyin wọn miran, Harry Maguire naa tun ṣeṣe ti wọn si gbe e jade ni ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa.
Igba keji niyi ti Aston Villa yoo ma bori Manchester united laarin ifẹsẹwọnsẹ mẹrindinlaadọta ti wọn ti gba ni Premier League.












