Premier league: Manchester city ti fojú Chelsea gbolẹ̀ pẹ̀lú góòlù kan sódo

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ṣango Ikọ agbabọọlu Chelsea to n paraba to n fa igi iroko ya ni idije Premier league ilẹ Gẹẹsi lati igba ti saa bọọlu 2021/2022 ti bẹrẹ ko igi nla Manchester city lọna loni.
Goolu kan dondo ni Manchester city fi ṣe agba Chelsea lojude rẹ ni Stanford Bridge.
Atamatase Ikọ Manchester City, Gabriel Jesuit lo gba goolu naa wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtalelaadọta.
Igba akọkọ niyi ti Gabriel Jesuit yoo gba bọọlu sawọn Chelsea. O si ṣalaye ninu ọrs rẹ lẹyin ifẹsẹwọnsẹ rẹ pe ariire lo jẹ nitori oun ko mọ pe oun lee raye yi gba goolu naa wọle.
O fi kun pe lootọ wọn na awọn ni ipele aṣekagba Champions league ṣugbọn awọn ko mura ẹsan wa biko ṣe lati gba bọọlu to dangajia.
Lati igba ti Tuchel ti gba iṣakoso gẹgẹ bi akọnimọọgba ni Chelsea, igba kẹrin ti Chelsea yoo maa koju Manchester city niyi, igba mẹtẹẹta iṣaaju si ni Chelsea ti fi oju wọn gbolẹ titi kan aṣekagba idije Champions League loṣu karun ọdun 2021.








