Arsenal vs Chelsea: Arteta pariwo lẹ́yìn tí Chelsea lu Arsenal bíi bàrà mọ́lé

Pierre-Emerick Aubameyang ati Mikel Arteta

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Mikel Arteta ti sọ pe iṣoro nla lo n koju Arsenal bayii.

Arteta sọrọ yii fawọn akọroyin lẹyin ti Chelsea poko iya fun Arsenal tan pẹlu ami ayo meji sodo nile wọn ni papa iṣere Emirates niluu London lọjọ Aiku.

Arteta ni ohun to n ṣe Arsenal buru debi wi pe ko si ẹni to ye.

Arsenal ti kọkọ fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba pẹlu ikọ agbabọọlu Brentford to ṣẹṣẹ goke wa si idije Premier League fun igba akọkọ lẹyin ọdun mẹrinlelaadọrin.

Ami ayo meji si odo ti Chelsea ti da ṣeria fun Arsenal mọle naa ni Brentford naa fi ṣagba wọn.

Eyi ni igba akọkọ ti Arsenal yoo fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ meji akọkọ ti wọn gba ni ibẹrẹ saa bọọlu EPL lai le gba ayo kankan sawọn. Ko ṣẹlẹ r tẹlẹ!

Arteta sọ fun BBC pe awọn agbabọọlu oun kan lugbadi arun covid-19 nigba tawọn mii fi ẹsẹ ṣeeṣe.

''N ko ro pe iru nkan bayii ti ṣẹlẹ ri si Arsenal ninu itan ẹgbẹ agbabọọlu yii.

Arsenal vs Chelsea: Arteta ta Pau! Lakuku lagi mọ́ Arsenal lórí láti gbayi fun Chelsea

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ṣugbọn a ni lati ṣe bi akin, ki a si koju iṣoro to n doju kọ wa.

Kii ṣe inu oṣu yii ni a maa mọ awọn ikọ agbabọọlu ti yoo pegede, ohun to buru ni pe ki a sọ ireti nu.

Ṣugbọn a ko ni sọ ireti nu, a o tubọ gbiyanju sii ni.

Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ meji ti o ti waye ni saa bọọlu tuntun EPL yii, Arsenal lo wa ni ipo to kangun si eleyi ko kẹyin lori tabili EPL.

Arteta ta Pàù! Lukaku lagi mọ́ Arsenal lórí láti gbayì fún Chelsea

Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lo ti korin bọnu, ti wọn si n fi ẹgbẹ agbaọọlu arsenal ṣe ẹlẹya lẹyin ti wọmn ko wọn ni bulala meji si odo

Bi o ti lẹ jẹ pe igba meji pere ni Arsenal ti gba bọọlu bi saa premiere liigi to bẹrẹ yìí, sibẹ wọn ko ti gba pọnti kankan, bakan naa ni wọn sọ oore- ọfẹ lati gba bọọlu sawọn nu ni ẹẹmẹrin.

Awọn ọmọ ikọ agbabọọlu Chelsae ti fakọyọ ni ẹẹmeji ti wọn ti dije ni saayii, ti wọn si ti jẹ nigba marun, koda, Romelu Lukaku ti wọn ṣẹsẹ kowo le lori se gudugujdu meje yaya mẹfa ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ to ti waye yii.

Lilọ bibọ Lukaku yii gan lo dabi orififọ fun ikọ agbaọọlu Arsenal

James pẹlu naa ko gbẹyin bi oun ati Mason ṣe jọ n ran ara wọn lọwọ lati goolu keji

Diẹ lo ku ki Lukaku tun jẹ goolu kẹta sùgbọn ṣe lo fi ori gba bọọlu na lu irin oju ile.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

O jọ bi ẹni pe Ben White to yẹ ko dile mu lọwọ ẹyin fun Arsenal ti ko si nibẹ nitori aarun Covid-19 to de mọọlẹ o jẹ nnkan to n yọ Arsenal lẹnu .

Nnkan ti oju Arsenal ti ri laarin ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn ti gba ni saa yii ti fẹ buru ju ti saa liigi to kọja lọ.

Igba kẹta ree, ti ikọ agbaọọlu Arsenal yoo fidirẹmi ninu idije meji ni tẹlẹntẹle ni saa liigi tuntun

Ibeere ti ọpọ n bere ni pe, ṣe Arteta ko duro gba sabuke lọwọ Pep guardiola to ti kọsẹ ni?