Adigun Olowe: Ọmọ ọdún márùn-ún, Adigun Olowe jẹ oyè nílùú Eko

Oríṣun àwòrán, Adigun olowe/instagram
Ọdọmọde agbede-gbẹyọ Yoruba, Adebayo Olamilekan Israel, ti ọpọ mọ si Adigun Olowe ti jẹ oye 'Ọdọ Agba Aṣa Ga' ti ilu Solu Alade, Ibeju-Lekki nipinlẹ Eko.
Ọmọ naa to gbajumọ fun bo ṣe ma n pa owe Yoruba loriṣiriṣi, to si tun ma n tumọ wọn.
Ọmọ ọdun marun-un ni ọmọ naa.
Ninu ọrọ to kọ si oju opo Instagram rẹ, lati kede ifinijoye naa, Adigun Olowe sọ pe ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021, ni Oba Muyideen Isgola Balogun, Onisolu ti Solu Alade, Ibeju-Lekki, fi oun jẹ oye naa.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
O ni pẹlu ifinijoye yii, oun ni ẹni ti ọjọ ori rẹ kere ju ninu awọn to jẹ oye ibilẹ ni Naijiria.
Adigun Olowe sọ pe oun ko le sọ bi inu oun ṣe dun to o si ifinijoye naa.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti BBC Yoruba ṣe fun Adigun Olowe, baba rẹ, Adebayo Oladimeji Ishola ni lati kekere ti awọn ti bi ọmọ naa lo ti maa n ṣe awọn nkan to jẹ iyalẹnu, eyi to si mu ki iya iya rẹ fun un ni alajẹ "Ara".
O ni ọjọ kan lo kọkọ bẹrẹ rẹ tawọn ṣaadede ri i to tun ọrọ ti oun sọ lede Yoruba ati gẹẹ́si sọ papọ lẹẹkan ṣoṣo titi to fi dori pe o lee sọ owe ọgbọ̀n ati itumọ rẹ lede gẹẹ́si.













