Yollywood: Ọ̀pọ̀ òṣèré Yorùbá ń ṣelédè lẹ́yìn Yusuf Satia tó d'olóògbé

Yusuf Satia

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Yusuf Satia, òṣèré Nollywood Yorùbá ti di olóògbé
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ta ni Yusuf Satia ti iku mu lọ?

Oṣere yii kii ṣe ọkan lara awọn oṣere ti wọn maa n saaba gbe nkan jade lori ayelujara nipa ara wọn tabi nipa iṣẹ wọn.

Igba to gbe nkan sori ikansira ẹni facebook gbẹyin ni lọjọ kẹrin, oṣu kẹta, ọdun 2013.

Lasiko yii lo sọ nipa ifojusọna ọjọ ibi rẹ lọdun 2013.

Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....

A bi Yusuf Ojewale Satia lọjọ kẹsan, an, oṣu kẹta lọdun naa lọhun.

Ipinlẹ Eko ni guusu Iwọ Oorun Naijiria ni Yusuf gbe dagba.

Nibẹ naa lo ti ka iwe alakọbẹrẹ ati iwe ipele girama.

Koda, o ri lọ si Fasiti ijọba apapọ to wa ni Akọka nilu Eko.

O tun gba iwe ẹri jade ni John Curtin College ni Australia.

O doloogbe ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu keje, ọdun 2020.

Awọn oṣerẹ bii Toyin Adewale ati Bose alao ati awọn miran ni wọn n ṣe ilede lẹyin rẹ ti wọn si banujẹ nigba ti wọn gbọ iroyin iku Satia Yusuf

Yusuf Satia

Oríṣun àwòrán, Kunle Afod/instagram

Ikú ti yọ́wọ́ òṣèré Nollywood Yorùbá, Yusuf Satia l'áwo

Oṣere Nollywood Yoruba, Yusuf Satia, ti ku.

Ibanujẹ lo jẹ fun agbo ile tiata Yoruba, Lẹyin ti iroyin iku rẹ jade sori ayelujara.

Akẹgbẹ rẹ, Kunle Afod, lo kede iku Satia loju opo Instagram rẹ ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keje, ọdun 2020.

Ikede iku Satia

Oríṣun àwòrán, kunle afod/instagram

Afod sọ pe oun gbiyanju lati kàn si Satia ninu ọdun yii, ṣugbọn ko ṣeeṣe.

A ko ti i le sọ nkan to pa oloogbe naa.

Yusuf Satia

Oríṣun àwòrán, Yusuf_satia/instagram

Satia di mimọ fun awọn ololufẹ rẹ fun ipa to ko ninu ere agbelewo Yoruba kan, Ijinlẹ Pam Pam to gbe jade logun ọdun sẹyin.

Awọn kan figba kan n ri Satia lẹyin KWAM 1 agba ọjẹ onifuju n ni lọpọ ọdun sẹyin.

Yusuf Satia ati gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde

Oríṣun àwòrán, Yusuf_satia/instagram

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Yusuf Satia ati gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde

Awọn oṣere bi i Toyin Adewale, ati Bose Alao naa ti n ṣe idaro rẹ.

Oṣu to kọja ni gbajugbaja oṣere, Ogun Majek naa jade laye lẹyin aisan.

Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....