Ìtàn Donald Trump, bàbá olówó rẹpẹtẹ tó fẹ́ẹ́ di ààrẹ America lẹ́ẹ̀kan sí i

Aworan Donald Trump ni 2022.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan Donald Trump ni 2022.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 11

Bi wọn ba n sọ pe ewuro ko fi t'ojo koro, akurọ ti lomi nilẹ k'ojo too de, ọkunrin ti wọn n pe ni Donald Trump lorilẹede America ni. Idi ni pe ṣaaju ko too dupo aarẹ lẹẹmẹta lo ti jẹ olowo nla ti a mọ si 'billionaire'

Gbogbo iwe iroyin lo maa n gbe ọrọ nipa olowo to n pawo rẹ lati ibi ilẹ ati ile kikọ naa, eyi to jẹ ko dije laaarin ọdun 2015 si 2016.

Orukọ rẹ to ti kari aye, bo ṣe ti gbajumọ tẹlẹ ati ọna to gba polongo ibo tun ran an lọwọ lati bori awọn oloṣelu nla to wa l'America, ṣugbọn ariwo ko tan lẹyin ariwo lo gbẹyin ọrọ rẹ, eyi ti ko jẹ ko le ṣe ju saa kan lọ nile ijọba gẹgẹ bii aarẹ.

Ni bayii, Donald Trump ti di ẹni ọdun mejidinlọgọrin (78), ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican naa si n wa ọna ti yoo tun fi pada si ori aga ijọba ilẹ America, ti yoo tun maa dari orilẹede naa lẹẹkan si i.

Àrẹ̀mọ

Donald Trump ree ninu ile oloke gogoro to kọ (Trump Tower)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọdun 1971 ni Trump tẹwo gba iṣakoso okoowo idile rẹ

Donald Trump lo wa nipo kẹrin ninu awọn ọmọ ti baba olowo kan ni New York,Fred Trum bi, abanikọle, ralẹ, oniṣowo ati bẹẹ bẹẹ lọ ni iṣẹ baba rẹ naa nigba yẹn.

Pẹlu bi idile naa ṣe lowo to, wọn fẹ ki Donald maa ṣiṣẹ lọdọ awọn oṣiṣẹ onipo kekere nileeṣẹ baba rẹ, wọn si ran an lọ sileewe ti yoo ti kọ nipa iṣẹ ṣọja nigba to wa lọmọ ọdun mẹtala pere, nigba to bẹrẹ si i ṣe aṣemaṣe nileewe.

Lẹyin ti Donald kẹkọọ gboye ni Yunifasiti Pennsylvania, kadara ṣe e loore lati di arẹmọ ti yoo gba ipo baba rẹ lẹnu okoowo mọlẹbi, nitori ẹgbọn rẹ, Fred Jr, to yẹ ko gba ipo naa sọ pe awakọ baaaluu (pilot) loun fẹẹ ṣe ni toun.

Fred Trump ẹgbọn Donald ku nigba to wa lẹni ọdun mẹtalelogoji pere,ọti mimu lo fa sababi iku naa. Ọti to pa Fred lo mu Donald sọ pe laye oun, oun ko ni i de idi ọti ati siga.

Donald Trump ree ni 1976.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Donald Trump ya miliọnu kan dọla lọwọ baba rẹ ko too bẹrẹ iṣẹ

Gẹgẹ bi Donald Trump funra rẹ ṣe wi, o ni oun ya miliọnu kan dọla, owo ti ko to nnkan, gẹgẹ bo ṣe sọ, lọwọo baba oun,koun too darapọ mọ ileeṣẹ rẹ.

Donald Trump sapa, o gbe ileeṣẹ abanikọle naa de ibi giga ni New York, o gba iṣakoso ileeṣẹ ọhun patapata. O yi orukọ ileeṣẹ naa pada si Trump Organization nigba to di 1971.

Koda, baba rẹ gboṣuba fun un, o si pe Donald ni 'iwuri mi' Ọdun 1999 ni baba rẹ jade laye.

Àwọn ohun tó fowó ṣe

Donald Trump ree ni 1987.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Orukọ de, okiki Donlad Trump bẹrẹ si i kan si i bi ileeṣẹ naa ṣe n gbooro si i.

Labẹ iṣakoso Donald, okoowo mọlẹbi to n bojuto gbera sọ kuro ni ile gbigbe ni Brooklyn nikan, o gbera lọ si Manhattan.

Ibi kan ti wọn n pe ni Fifth Avenue to gbajumọ daadaa, di ibi ti Donald Trump kọ ile nla rẹ si , o si gbe nibẹ fun ọpọlọpọ ọdun. Ile naa gbajumọ bii olowo rẹ ni.

Awọn dukia mi-in to tun ko jọ ni : Casino, Condominium, bẹẹ lo si tun kọ awọn ibi iṣere ati ile itura lati Atlantic City, Chicago ati Las Vegas titi de India,Turkey ati Philippines.

Bakan naa ni okiki rẹ lẹka faaji n goke agba, oun lo ṣagbatẹru idije Omidan to rẹwa ju lagbaaye, Omidan to rẹwa ju l'America, ati tawọn ọmọbinrin tọjọ ori won wa laaarin ọdun mẹtala si mọkandinlogun, oun naa lo si tun ni eto NBC reality show ti wọn n pe 'The Apprentice'

Ọgbẹni Donald Trump ree pẹlu awọn meji to dagba ju ninu awọn ọmọ rẹ, Donald Jr ati Ivanka, lori eto 'Celebrity Apprentice' ni 2010.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Donald Trump ṣe olootu eto 'The Apprentice' fun igba mẹrinla, awọn ọmọ bibi inu rẹ naa kopa lori eto ọhun.

Ìdílé Donald Trump

Iyawo Donald, Ivana ree pẹlu ọkunrin naa ni 1989

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ko si ma-jẹ- agbọ ninu igbesi aye Donald Trump, idi ni pe gbajumo ni.

Iyawo to kọkọ fẹ, Ivana Zelnickova, jẹ elere ije ati arinrinoge, o bimọ mẹta fun un.

Awọn ọmọ naa Donald Jr, Ivanka ati Eric, ki wọn too kọ ara wọn silẹ ni 1990.

Ija ajaku akata to n ṣẹlẹ ninu igbeyawo naa ki i ye jade ninu iwe iroyin nigba naa, awijare iyawo to ti di olooge bayii naa si ni pe Trump maa n lu oun.

Nigba to di 1993, Trump fẹ iyawo mi-in, Marla Maples, toun jẹ oṣere tiata.

Igbeyawo naa ko tọjọ, oṣu meji lẹyin ti Marla bi ọmọ kan ṣoṣo to da wọn pọ ti wọn sọ ni Tiffany, ni oun ati Trump kọ ara wọn.

Donald, Melania ati Barron, nibi isinku Ivana.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iyawo ile Trump lọwọ yii, Melania, bimọ ọkunrin kan, Barron, fun un. Ọmọ naa ti pe ẹni ọdun mejidnlogun bayii.

Iyawo to wa nilee Donald Trump bayii, Melania Knauss, jẹ arinrin oge Slovenia nigba kan. Ọdun 2005 ni wọn ṣegbeyawo, wọn si bimọ ọkunrin kan, Barron William Trump, to pe ẹni ọdun mejidinlogun laipẹ.

Ṣugbọn ọrọ gbogbo ki i se lori alabahun, ariwo iwa aitọ nipa ibalopọ ati nini ale nita ko tan lọrọ Donald Trum to fẹẹ di aarẹ America lẹẹkan si i.

Ni iberẹ ọdun yii, awon adajọ meji ọtọọtọ ni wọn dajọ pe Trump ba onkowe kan, E Jean Carrol , lorukọ jẹ, nigba to purọ pe ẹsun ṣiṣẹ ohun ti ko tọ si obinrin olobinrin ki i ṣe bẹẹ.

Ileẹjọ paṣẹ pe ki Trump san $88m fun obinrin naa, ṣugbọn Trump ko gba, o ti pe ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun.

Ẹṣun mẹtalelogoji mi-in ni wọn tun fi kan Trump, won lo purọ akọsilẹ okoowo rẹ lati dawo bo aṣiri owo kan to da oun ati Stormy Daniels to maa n ṣe fiimu ibalopọ po, eyi to ni i ṣe pẹlu ajọsẹ wọn ni 2006.

Ondupo naa

Ni 1980, lasiko ifọrọwanilẹnuwo kan, Donald Trump to jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (34) nigba naa, ṣapejuwe oṣelu bii, " igbesi aye to buru gbaa". O ni awon eeyan to ba kaju ẹ ki i ṣe oṣelu, okoowo ni wọn maa n ṣe "

Ṣugbọn nigba to di 1987, o bẹrẹ si i dogbọn ati ṣe oṣelu, o n wo ipo aarẹ bii pe o fẹẹ ṣe. O sare wọ ẹgbẹ oṣelu Reform party ni 2000, o si di ọmọ ẹgbẹ Republican ni 2012.

Trump wa lara awọn to n lewaju atako nipa Barack Obama, o ni ṣe wọn bi Obama si America ṣaa.

Ko gba pe ọrọ ko ri bẹẹ titi di 2016, nigba to si ri i pe ọmọ onilẹ ni Obama, Trump ko tori ẹ tọrọ aforiji.

Donald Trump tun ree ni Trump Tower.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nigba to di 2015, Donald Trump kede lojuu gbogbo aye pe oun fẹẹ dupo aarẹ ilẹ America, o ni gbogbo ala orilẹede naa to ti doku loun fẹẹ ji pada, ko tobi ko si daa ju ti tẹlẹ lọ .

Bo ti n kede to n ṣafihan ọla rẹ lo n sọ awọn ohun to ni o ku diẹ kaato, bẹẹ lawon eeyan to feran rẹ n fi han pe awọn gba tiẹ.

Ero pọ to n sọ oriṣiiriṣii ọro nipa ipinnu Trump lati di aarẹ nigba naa, bẹẹ lawọn oniroyin naa n gbe e kikan-kikan.

Trump niyi lasiko idije ibo abele ni 2015, eyi ti i ṣe ti ẹgbẹ Republican.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu ipolongo 'Make America Great Again' ti Donald Trump yan laayo, kia lo gbayi mọ alatako rẹ, Hillary Clinton, lati ẹgbẹ oṣelu Democrat, lọwọ .

Awuyewuye pọ ninu ipolongo re yii, titi to fi kan fọn-an-ran ohun kan ti Trump ti n leri nipa ibalopọ lọna aitọ, bẹẹ ni gbogbo eyi n waye titi ti wọn fi dibo.

Ṣugbọn Trump lo pada bori, o gba ipo naa mọ oloṣelu agba to ti pẹ gidi lẹnu oṣelu lọwọ.

Nigba to si di ogunjọ, oṣu kin-in-ni ọdun 2017, wọn bura wole ijoba fun Donald Trump gẹgẹ bii aarẹ karundinlaadota (45) ilẹ America.

Ààrẹ náà

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wakati diẹ lẹyin ti Trump di aarẹ America lo ti bẹrẹ si i ṣe ohun ijọju.

Ọkunrin naa bẹrẹ si i kọ awọn ọrọ to ba yẹ ko sọ lọfiisi si oju opo X, ti wọn n pe ni Twitter nigba yẹn.

Bẹẹ lo n ba awọn aṣaaju ilẹ okeere ja lai fi bo.

O yọ ara rẹ kuro ninu awon adehun to ti wa nilẹ tẹlẹ, o fagile irinajo lo si awọn orilẹede musululumi meje ti wọn lorukọ ju lagbaaye.

O ṣe awọn ofin irinajo ti ko si iru rẹ tẹlẹ, o bere orogun okoowo pẹlu China, o ṣofin ki wọn ge owo ori ku, o si gbe ibaṣepọ awon ati apa Middle Eastern gba ọna ibo mi-in lọ

Laipẹ, Trump di aarẹ America kẹta ti wọn yọ nipo, lori ẹsun pe o bẹ awọn kan lọwe, lati maa wa idi Joe Biden to je alatako re. Wọn yọ ọ lọdo awọn Democrat, Republican si duro ti i gbagba.

Nigba to tun gbegba ibo ni 2020 , aisan Korona to bẹ silẹ ko jẹ ko rọwọ mu.

Won ba a fa ọrọ naa pupọ, wọn lo lọwọ si wahala naa pẹlu aba rẹ to daa pe boya kawọn eeyan maa gba abẹrẹ ajẹsara ti wọn fi ọṣẹ ifọṣọ lubulubu (detergent) ṣe.

Wọn ko jẹ ko kede ibo mọ titi di oṣu kẹwaa ọdun naa, nigba ti Korona nawọ gan oun funra rẹ gan-an.

Ni 2018, nigba ti Trump lọ fun ipade G7.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iṣakoso Trump yatọ gedegbe fun awọn isọngbe rẹ nile ijọba
Àkọlé fídíò, Trump n kede aba rẹ lori Corona, tiẹ yatọ gedegbe.

Bo tilẹ jẹ pe Trump ri ibo miliọnu mẹrinlelaadọrin (74m), ibo to ṣoro fun aarẹ to ba lori ipo paapaa lari ri, sibẹ, o padanu sọwọọ Joe Biden, ibo tiyẹn ju tiẹ lọ gidi.

Lati oṣu kọkanla ọdun 2020, titi di oṣu kin-in-ni ọdun 2021, Trump ko yee pariwo pe wọn ji ibo oun, o ni awọn eleto idibo lo ṣe eru, ṣugbọn gbogbo ile ẹjọ to gbe e lọ ni won so pe ko si ọro nibẹ, won fawe ẹjọ rẹ naa ya.

Nitori ko fẹẹ gba esi ibo naa wọle, Trump pe fun iranwọ lati Washington lọjọ kefa, oṣu kin-in-ni , o rọ awọn alatilẹyin rẹ naa pe ki wọn pejọ si gbagede bi wọn ṣe fẹẹ gbe agbara fun Biden.

Iwọde naa pada di wahala, o ko awọn aṣofin ati ẹni to ṣe igbakeji rẹ si iyọnu gidi.

Won tun gbe igbesẹ ati fiya jẹ ẹ, ṣugbon ile igbimọ aṣofin tun gbeja rẹ, bo tilẹ jẹ pe o fẹrẹ ma ṣee ṣẹ nigba naa.

Iwa rẹ lọjọ naa ṣi wa lara awọn ẹsun iwa ọdaran ti won fi n kan an

Ìpadàbọ̀

Àkọlé fídíò,

Awọn eeyan ti Trump ko jọ lati da eto Biden ru yii, ṣ'akoba irinajo oselu rẹ pupọ, ọpọ alatilẹyin rẹ ni won ni awọn ko ni i ti i lẹyin mọ laye. Koda, awọn to sunmọ ọn ju paapaa kede ni gbangba pe awọn ti pada lẹyin rẹ.

Trump ṣe bii pe ko si eyi to kan an lasiko ti wọn n bura fun alatako rẹ, o kuro nitosi pẹlu ẹbi rẹ, won gba Florida lọ.,ṣugbọn awọn ikọ kan ṣi wa ti wọon fẹran rẹ sibẹ, wọn lawọn yoo durti i bii ọmọ Republican gidi.

Pẹlu gbogbo awuyewuye yii, Trump kede pe oun tun n pada bọ waa dije fun ipo aarẹ America lẹẹkan si i.

Ẹgbẹlẹgbẹ alatako , titi to fi mọ igbakeji rẹ tẹlẹ ni wọn tako o, ṣugbọn Trump ko wo oju wọn, Biden lo doju atako tiẹ kọ.

Àkọlé fídíò, We ask Trump fans at CPAC if they like anything about Biden

Ìdìbò ń súnmọ́ etílé, ọjọ́ karùn-ún, oṣù kọkànlá ọdún 2024 ni

Idibo naa ti wọle de tan, ọjọ karun-un, oṣu kọkanla ọdun 2024 yii ni wọn yoo dibo aarẹ nilẹ America.

Ẹsun mọkanlelaadọrun-un (91) lo wa lọrun-un Trump lati jẹjọ rẹ, ṣugbon wọn ti ba a sun awọn kan siwaju latari ọna to maa n gba lati sun igbẹjọ siwaju.

Awọn igbẹjọ kan ko ni i waye titi di ẹyin ibo yii.

Lojọ kẹtala, oṣu keje ọdun yii ni ọmọkunrin ẹni ogun ọdun kan yinbọn mọ Trump nibi ipolongo ibo, ni Butler, Pennsylvania. Thomas Matthew Crooks ni wọn pe orukọ ọmọ naa to yinbọn ilewọ lati ori oke ile, to si ṣe Trump leṣe nibi ẹgbẹ eti rẹ ọtun, ko too di pe won pa ọmọkunrin to yinbọn naa.

Latigba ti Biden ti loun o dupo mọ, to yan igbakeji rẹ , Kamala Harris, lati maa ṣe e lọ ni Trump ti n sọ pe obinrin naa ko mọ bi wọn ṣe n ṣe akoso.

Trump ti sọ fun awọn alatilẹyin rẹ pe ibo ti yoo waye lọjọ karun-un oṣu kọkanla yii, yoo jẹ ọjọ ma ni gbagbe ninu itan ilẹ America.

Aworan to n kede ibo naa, pẹlu ori Kamala Harris ati Donald Trump.