'O kì í ṣe ọba tèmi o', Sẹ́netọ ọmọ ilẹ̀ Australia pariwo lé Ọba Charles ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lórí

Oríṣun àwòrán, Reuters
Bi ọba ilẹ Gẹẹsi, King Charles, ṣe n pari ọrọ rẹ nile igbimọ Australia, lọjọ keji to ṣabẹwo si ilu naa ni ariwo kan sọ, ''o ki i ṣe ọba mi'' ni ohùn naa n ke, o si jẹ ti Sẹnatọ obinrin kan, Lydia Thorpe.
Lidia Thorpe, ojulowo ọmọ Australia to ti pẹ niluu naa lo bẹrẹ si i da eto to waye ni Canberra lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2024 yii ru, ki awọn agbofinro to o gbe e kuro nibi eto naa.
Lẹyin to ti fi ẹsun ipaniyan lọpọ yanturu kan Ọba Charles, Sẹnetọ Lidia tun n pariwo pe: "Ibi ki i ṣe ilẹ rẹ, o ki i ṣe ọba temi."
Ṣugbọn Violet Sheridan toun naa jẹ ojulowo ọmọ Australia to si ti pẹ nibẹ, ṣapejuwe iwa ti Lidia hu bii afojudi. O ni Lidia ko ṣoju oun pẹlu ọrọ rẹ, ọrọ ara rẹ nikan lo n sọ.

Oríṣun àwòrán, EPA
'Ẹni tó bá fẹ́ẹ́ darí ìlú gbọ́dọ̀ jẹ́ ọmọ onílẹ̀'
Wọn pari ayẹyẹ naa lai mẹnuba iṣẹlẹ ariwo sẹnẹtọ yii rara, Ọba Charles ati olori rẹ si lọọ ri obitibiti ero to n duro de wọn lati ki wọn.
Orilẹeede Australia jẹ ilu kan ti ọba yii jẹ olori ibẹ, ṣugbọn laipẹ yii ni ariyanjiyan kan bẹrẹ, nipa pe ki wọn yọ ọba kuro nipo olori Australia.
Thorpe, to jẹ Sẹnetọ lati agbegbe Victoria si ti n sọ ọ tipẹ pe o yẹ ki adehun ati ọrọ ajọsọ waye laaarin ijọba Australia atawọn eeyan ti wọn kọkọ n gbe orilẹede naa.
Lẹyin ariwo naa, Thorpe ṣalaye fun BBC pe oun fẹẹ k'ọrọ oun ye ọba naa daadaa ni"
''Teeyan ba fẹẹ jẹ olori, o gbọdọ jẹ ọmọ ilẹ ibi kan. Oun ki i ṣe ọmọ ilu yii. "
O ni o yẹ k'Ọba Charles ba awọn igbimọ ṣepade, ko paṣẹ ki wọn lọọ ba awọn to tẹlẹ ibẹ do.
"A le ṣe tibi, a le ṣe tọhun, a le jẹ orilẹede to daa ju awọn mi-in lọ, ṣugbọn a ko le fori balẹ fawọn to mu wa sin. Awọn ti iran wọn lọwọ ninu ipaniyan rẹpẹtẹ."
Thorpe ṣapejuwe Ọbabinrin Elizabeth keji bii amunisin.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ṣugbọn pẹlu ẹhonu yii naa, inu awọn eeyan yooku dun lati ri ọba ati olori rẹ, bẹẹ ni wọn n ju asia Australia ti wọn mu dani.
Ọmọbinrin kan, Jamie Karpas, ẹni ogun ọdun, sọ pe oun ko mọ pe ọjọ Aje ni ọba naa ati olori rẹ yoo wa. O fi kun un pe, “ Gẹgẹ bi ẹni to ti ri Harry ati Meghan nigba ti wọn wa sibi gbẹyin, inu mi dun gan-an. Ero mi ni pe idile ọba naa jẹ ọkan lara awọn to fara mọ aṣa Australia. Ipa nla ni wọn n ko lori aye wa.”
Ẹwẹ, CJ Adams, akẹkọọ ni Australian National University, sọ pe, "oun ni olori ilu ilẹ Gẹẹsi abi, o yẹ ko kọ gbogbo ẹkọ to o ba le kọ nigba to o wa ni Canberra ."
Agbarijọpọ awọn eeyan kan ti wọn ko fẹ Ọba Charles naa kora jọ siwaju ile igbimọ naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ko pọ.

Kí ni Ọba Chares sọ?
Ọba Charles ni tiẹ sọrọ lori awọn eeyan Australia ati ẹkọ to ti kọ nipa wọn.
“ Ninu gbogbo irinajo pupọ ti mo ti ṣe wa si Australia, mo ti ni iriri aforiti ati ireti to n gbe orilẹede naa ro, to si n jẹ ko ṣoro fun wọn nigba mi-in lati tọ ọna ajọṣepọ.
Bo ti jokoo ni ariwo Thorpe bẹrẹ, ṣugbọn ọpọ awọn eeyan obinrin naa ni ko faramọ ohun to n sọ.
" Ara ọba ko ya, o n gba itọju ti awọn to ni jẹjẹrẹ maa n gba (chemotherapy).
''Afojudi ni iwa ti Thorpe hu si i, ati ohun to sọ. Inu temi dun pe o wa, o si le jẹ awamọ rẹ ree bayii, ọpọ eeyan lo kuku gba ohun ti mo n sọ yii pe bẹẹ lo ri.''
Aunty Sheridan lo sọ bẹẹ.
Aafin Buckingham ko ti i sọrọ lori ifẹhonuhanThorpe, awọn ero rẹpẹtẹ to waa ki wọn kaabọ ni wọn dojukọ.
Ẹnikan ninu aafin naa sọ pe awọn eeyan rẹpẹtẹ to tu jade pade wọn naa jọ Oba Charles ati olori rẹ loju gan-an.
Àjọṣepọ̀ Australia ati ijọba Gẹẹsi
Fun ọpọlọpọ ọdun ni Australia ti n sọrọ nipa boya ki wọn kuro lara ile ọba Gẹẹsi, ki wọn si di ilẹ olominira. Ni 1999, wọn beere ọrọ yii lọwọ awọn araalu nilana ibo.
Awọn to fara mọ aba naa n pọ si i latigba naa lọ.
Ninu abẹwo ọdun yii ti Ọba Charles ṣe lọ si Australia, oun ati olori rẹ gbin igi ki wọn too lọ si ile ayẹwo National Bushfire Behaviour Research Laboratory.

Oríṣun àwòrán, PA Media














