Àwọn gbájúẹ̀ fi ayédèrú báǹkì lu àwọn kan tó ń wá iṣẹ́ ní jìbìtì

Yadav
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni ọsẹ diẹ sẹyin, awọn ọlọpaa lorilẹede India kẹfin pe awọn onijibiti ti da ayederu ẹka banki kan silẹ - pẹlu ami idanimọ, awọn ohun elo ijoko si, koda pẹlu awn oṣiṣẹ - ni ileto kan to wa ni ipinlẹ kan ti wọn n pe ni Chhattisgarh.

BBC Hindi ṣe atupalẹ bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ.

Jyoti Yadav jẹ ọkan lara awọn ti inu wọn dun nigba to ri iṣẹ gba gẹgẹ bi oṣiṣẹ ọfiisi kan ni banki tuntun kan ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ nitosi ileto rẹ.

Ọdun mẹrin gbako lo ti fi n wa iṣẹ kiri, eyi to si ti mu ki ati rina tabi jẹun o di agbara akaka fun un.

Awọn alaṣẹ Banki naa rọ ọ lati tete wa bẹrẹ iṣẹ ni kiakia o si gba lati ṣe bẹẹ nitori pe bankiilẹ India, (SBI), banki naa si ni banki ijọba to tobi ju lorilẹede naa ti gbogbo aye si mọ.

Amọṣa, lẹyin ọsẹ kan to dara pọ mọ wọn, awọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ ẹka banki SBI to wa lagbegbe naa – ni iwn igba kilomita si olu ilu ipinlẹ Chhattisgarh, Raipur, ti wọn si sọ fun Jyoti atawọn oṣiṣẹ yoku nibẹ pe ayederu ni Banki naa ati pe wọn ti lu wọn ni jibiti.

Ọrọ naa ya Jyoti lẹnu pupọpupọ. O ni awọn to fun oun ni iṣẹ naa ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun oun , wọn fun un ni iwe igbanisiṣẹ ati kaadi idanimọ, pẹlu ileri ati san owo oṣu ẹgbẹrun lọna ọgbọn rupee owo ilẹ India iyẹn nii ọtalelọọdunrun dọla owo ilẹ Amẹrika ($357) loṣu.

Awọn ọlọpaa ti mu ọkan lara awọn gbajuẹ naa, wọn si n wa awọn mẹjọ miran.

Awọn ẹka ayederu banki ti wọn da silẹ naa.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lorilẹede India, awọn gbajuẹ to n fi iṣẹ fifun ni lu ọpọ jibiti nibi ti awọn omilẹgbẹ ọdọ ti n lakaka lati wa iṣẹ. Ni ọdun 2022, o le ni awọn ọkunrin mẹrinlelogun kan ti wọn ti ro pe awọn ri iṣẹ pẹlu ileeṣẹ reluwe ti wọn fi ọgbọn ẹwẹ mu lọ maa ṣe iṣẹ amojuto ọkọ oju irin fun ọpọlọpọ ọjọ.

Wahala aisi iṣẹ, paapaajulọ lawọn ileto kekeke nibi ti ọwọngogo iṣẹ ti n waye, to si n kan an nipa fun awọn ọdọ lati maa gbe awọn igbesẹ to lewu , bii sisan riba -eyi to lodi si ofin lorilẹede India – fun ati ri iṣẹ lati gbe ọjọ ọla wọn ro.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ peawọn oṣiṣẹ mẹfa to wa ni ayederu ẹka banki naa jẹ atapata dide, koda awọn kan ninu wọn san riba lati ri iṣẹ naa.

Ọlọpaa kan to ba BBC sọrọ sọ pe o han gbangba pe ọgbọn ẹwẹ lati gba gbọna eru gba owo lọwọ awọn to n wa iṣẹ ni.

Jyoti Yadav sọ pe oun fi ọwọ si iwe gbogbo to yẹ lati ori ayelujara, oun si da gbogbo iwe ẹri ti oun ni si ibẹ gẹgẹ bi ara ilana lati gba iṣẹ naa eleyi si jẹ oun to wọpọ kaakiri awọn ileiṣẹ nlanla lorilẹede India.

Yadav sọ pe, “Ko fi igba kankan han si mi pe mo ti bọ sọwọ awọn gbajuẹ rara. Amọ bayii, gbogbo nnkan ti mo gbọkanle ti lulẹ.”

O ni ẹgbẹrun lọna ọtalelugba o din mẹwa, (250, 000 Rupees), ti oun fi oogun kojọ loun na lati fi san riba fun wọn lati le ri iṣẹ naa gba.

Ọgbẹni Ajay Agarwal

Awọn olugbe ileto naa sọ pe ṣẹṣẹ ni inu awọn dun nigba ti wn gbe banki naa kalẹ si ilu wọn nitori ero awọn ni pe yoo tubọ mu ọrọ ifowopamọsi rọrun fun wọn nibẹ ni.

Amọṣa o, awọn olugbe ileto naa kan to fẹ ṣi aṣuwọn ifowopamọsi pẹlu banki naa ni awn oṣiṣẹ ibẹ sọ fun pe wọn ṣi n ṣe eto ifilọlẹ awọn ohun elo ayelujara gbogbo ti wọn yoo fi bẹrẹ iṣẹ ni banki naa lọwọ., nitori naa ki wọn duro de oṣu to tẹlee.

Awọn miran tilẹ ti n dunnu pe ọna idkoowo tuntun lo tun ṣi silẹ yii.

Ọgbẹni Ajay Agarwal to jẹ ọkan lara awọn olugbe ileto naa sọ pe oun tilẹ ti sare beere fun aaye lati gbe patako itaja si ayika ile ifowopamọsi naa.

Amọ o ni ni kete ti oun ti ri pe kini ọhun ti n ruju lẹyin ti oun gba aṣẹ lati gb epatako naa sibẹ, loun ti gba ẹka banki SBI to wa ni itosi ilu naa lọ lati beere awọn ibeere to ru oun loju.

Ko pẹ si asiko naa lawọn ọlọpaa ya bo banki naa, amọṣa ẹni to n pe ara rẹ ni ọga agba banki naa ti na papa bora.

Awọn ọlọpaa sọ pe arakunrin ti ọwọtẹ gan wa lara awọn ti wọn n wa tẹlẹ fun iṣẹlẹ fifi iṣẹ wiwa lu jibiti lawọn agbegbe kan ni ipinlẹ naa.