Lagbaja ò kú o, ó lọ fún ìsinmi lẹ́nu ìṣẹ̀ ni- Iléeṣẹ ológun

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army
Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti wọgile iroyin ẹlẹjẹ kan to ni Ọga ologun agba lorilẹede Naijiria, Taoreed Lagbaja ti jade laye.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Onyema Nwachukwu ni Lagbaja lọ fun isinmi lẹni iṣẹ, ti gbogbo eto si ti to lati jẹ ki Ọgagun Abdulsalami Ibrahim ma sisẹ gẹgẹ bii adele Ọga ologun.
Nwachukwu ni aisi ni ile Lagbaja lọwọ ko da iṣẹ ologun duro rara.
Saaju ni iroyin kan jade pe Ọga ileeṣẹ ologun, Lt. Gen Taoreed Lagbaja ti jade laye ni ile iwosan lẹyin to ni asian jẹjẹrẹ.
“Ọpọ iroyin ẹlẹjẹ lo n lọ kiri pe ko si olori mọ ni ileeṣẹ ologun, ti o si ya ọpọ wa lẹnu. A fẹ jẹ ko di mimọ pe ko si nnkan to jọ mọ bẹ, to si jẹ irọ to jina si otitọ.
“Lati lahan gbogbo wa, ileeṣẹ ologun ni ilana ti o fi n sisẹ lasiko ti nnkan ba waye. Ki o to gba isinmi, gbogbo eto ti wa fun Ọga ologun Abdulsalami Bugudu Ibrahim lati ma sisẹ de Ọgagun Lagbaja.
“Ọpọ igba ni nnkan ti a ro ti ṣẹlẹ, ti ọga ologun si ni lati lo simi fun oṣu mẹta, ti awọn amugbalẹgbẹ rẹ si ni lati sisẹ bi adele fun un.
“Gbogbo ayisọ ọrọ to n lọ kiri lo jẹ iroyin ẹlẹjẹ.”
Agbẹnusọ ologun ni gbogbo awọn ẹka ileeṣẹ ologun ni wọn tẹsiwaju lẹnu iṣẹ wọn, ti ko si si idaduro kankan nibi kibi.
O wa rọ awọn araalu lati yago fun awọn iroyin ẹlẹjẹ bayii, to si tun jẹ ko di mimọ pe alaafia orilẹede Naijiria lo jẹ ileeṣẹ ologun logun pupọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















