'Ọlọ́pàá rere ni ọkọ mi àmọ́ wọ́n pa á lásìkò ìwọ́de #EndSARS'

Oríṣun àwòrán, FAMILY
"Ọkọ mi tẹ̀lé àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ jáde ní ọjọ́ náà, nígbà tó di ìrọ̀lẹ́ ni àwọn yòókù rẹ̀ pè mí pé wọ́n ti gbe lọ sílé ìwòsàn. Àwọn dókítà kò jẹ́ kí n ri lálẹ́ ọjọ́ náà nígbà tí mo dé ilé ìwòsàn, wọ́n ní àwọn ń tọ́jú rẹ̀ lọ́wọ́. Mò ń gbọ́ bí ó ṣe ń ké látàrí ìrora tó ń ní.
“Nígbà tó di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì tí mo dé ilé ìwòsàn, wọ́n ní kí n lọ wá owó wá láti fi ṣe àyẹ̀wò kan àmọ́ nígbà tí mo fi padà dé ibẹ̀, wọ́n ní ó ti jáde láyé.”
Abílékọ Ifeoma Dorathy Ugwu tí ọkọ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò ìwọ́de #EndSARS tó wáyé lọ́dún 2020 sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ̀mí ọkọ rẹ̀ ṣe bá ìwọ́de náà lọ bí ìwọ́de náà ṣe pé ọdún mẹ́rin lónìí.
Dorathy Ugwu ṣàlàyé fún BBC News Pidgin bí ọkọ rẹ̀, Maurice Ugwu ṣe jáde láyé lásìkò tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Eko, tó sì fi ọmọ mẹ́rin kalẹ̀ fun.
Ó ṣàlàyé pé òun kò ṣiṣẹ́ kankan rí láti ọdún 1998 tí òun àti ọkọ òun ti fẹ́ ara wọn títí di ìgbà tí ọkọ òun kú, tí òun sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní tọ́jú àwọn ọmọ mẹ́rin láti ìgbà náà.
Ní ọjọ́ Kejìlélógún, oṣù Kẹwàá ọdún 2020 ni ọkọ rẹ̀ jáde láyé lásìkò táwọn èèyàn kan ṣe ìkọlù si.
Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lásìkò náà, Mohammed Adamu sọ pé ọlọ́pàá méjìlélógún ló pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò náà, báwọn olùwọ́de ṣe kọjú oro sáwọn òṣìṣẹ́ ààbò pàápàá àwọn ọlọ́pàá.
Àwọn jàǹdùkú tún dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá 205 káàkiri Nàìjíríà lásìkò ìwọ́de náà.
Ọ̀pọ̀ aráàlú ló jáde láyé, bíba dúkìá jẹ́ àtàwọn nǹkan míì ló wáyé lásìkò ìwọ́de náà.
Àjọ Amnesty International sọ pé èèyàn mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ló kú káàkiri Nàìjíríà àti pé èèyàn méjìlá ló jáde láyé ní Lekki Tollgate nínú wọn.
Ọkọ Dorathy wà lára àwọn ọlọ́pàá tó jáde láyé lásìkò náà.
Kí ló ṣẹlẹ̀ lásìkò ìwọ́de #EndSARS?

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà pàápàá àwọn ọ̀dọ́ ló ṣe ìwọ́de káàkiri Nàìjíríà láti fẹ̀hónú hàn lórí àwọn ìwà àìtọ́ àti ìpànìyàn tó ń wáyé látọwọ́ àwọn ọlọ́pàá.
Ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹwàá ọdún 2020 ni ìwọ́de náà bẹ̀rẹ̀, tó sì ń lọ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ kó tó di pé wàhálà padà bẹ́ sílẹ̀ ní ogúnjọ́ oṣù Kẹwàá náà.
Òní ló pé ọdún mẹ́rin tí wọ́n ń ṣe àyájọ́ ìwọ́de náà.
'Mi ò tíì rí owó ìfẹ̀yìntì ọkọ mi gbà dòní láti ọdún mẹ́rin sẹ́yìn'
Dorathy Ugwu sọ pé nǹkan kò rọrùn fún òun àtàwọn ọmọ mẹ́rin láti ìgbà tí ọkọ òun ti jáde láyé.
Ní àgọ́ ọlọ́pàá Iponri, ìpínlẹ̀ Eko ni ọkọ rẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé, tí wọ́n sì ń gbé ní ilé ìgbé àwọn ọlọ́pàá tó wà ní Iponri bákan náà.
Ó ṣàlàyé pé abẹ́ bírìjì kan ni àwọn akẹgbẹ́ ọkọ òun ti ṣe àwárí rẹ̀ tó ń jẹ ìrora tí wọ́n sì sáré gbe lọ sí ilé ìwòsàn tó sì jáde láyé lọ́jọ́ kejì.
Ó ní láti ìgbà náà ni òun ti di opó àti pé Ọlọ́run ló ń rán òun lọ́wọ́ láti tọ́jú àwọn ọmọ òun.
Lẹ́yìn oṣù díẹ̀ ni wọ́n sin òkú ọkọ rẹ̀, tí èèyàn kan sì ba wá iṣẹ́ tó ń ṣe báyìí láti máa fi gbọ́ bùkátà àwọn ọmọ.
Ó sọ pé lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá san owó adójútòfò àti owó alájẹṣẹ́kù tí ọkọ òun ń ṣe fún àwọn àmọ́ àwọn kò ì tíì rí owó ìfẹ̀yìntì rẹ̀ gbà.
“A ti lọ láti gba owó ìfẹ̀yìntì náà lòpọ̀ ìgbà ṣùgbọ́n oríṣiríṣi nǹkan ni wọ́n sọ pé kí a máa mú wá. Tí a bá fún wọn ní ọ̀kan lónìí, wọ́n á tún bèèrè òmíràn lọ́la.”
Ó ní àwọn nǹkan náà ni kò jẹ́ kí àwọn tíì rí owó náà gbà àti pé òun mọ àwọn ẹbí tí wọ́n ti rí ti wọn gbà.
Ọlọ́pàá dada ni bàbá mi - ọmọ ọlọ́pàá Ugwu

Oríṣun àwòrán, FAMILY
Àkọ́bí ọlọ́pàá Maurice Ugwu, Amarachukwu Ugwu tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ kan ní ìpínlẹ̀ Enugu sọ fún BBC Pidgin pé ìyà ńlá ni ìwọ́de náà kó bá ìdílé òun.
Amarachukwu ní òun ń gbiyanju láti san owó ilé ẹ̀kọ́, ilé ìgbé, jẹun fúnra òun nítorí òun kò fẹ́ máa dààmú ìyá òun nítorí àwọn àbúrò òun tí ìyá náà ń tọ́jú.
Ó ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti pàṣẹ pé kí àwọn kó kúrò ní báràkì ọlọ́pàá táwọn ń gbé nítorí àtúnṣe tí wọ́n fẹ́ ṣe níbẹ̀.
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti kó jáde àmọ́ àwa ò mọ ibi tí a fẹ́ lọ báyìí.”
“Èèyàn dada ni bàbá mi lásìkò tó wà lẹ́nu iṣẹ́, ó sì fẹ́ràn iṣẹ́ rẹ̀ dáadáa,” Amarachukwu fi kun.
Nínú àkọ́ọ́lẹ̀ kan tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi han BBC News Pidgin, orúkọ àwọn ọlọ́pàá méje tó jáde láyé lásìkò ìwọ́de #EndSARS wà níbẹ̀ tí orúkọ Paul Maurice Ugwu náà sì wà lára wọn.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwoolu fún àwọn ẹbí ọlọ́pàá mẹ́fà tó jáde ní mílíọ̀nù mẹ́wàá mẹ́wàá náírà àti ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fáwọn ọmọ wọn títí dé ilé ẹ̀kọ́ gíga àmọ́ kò sí orúkọ ẹbí Paul Ugwu nínú àwọn tó rí ìrànwọ́ náà gbà.
Abílékọ Ugwu ń rọ ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti bojú àánú wo àwọn opó tí ìyà ń jẹ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ okòwò láti fi máa mójútó ara wọn.
Lórí ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìwọ́de ní Nàìjíríà, ó ní òun kò lè gba ẹnikẹ́ni ní ìyànjú láti ṣèwọ́de nítorí nǹkan tí ojú òun ti rí.
Láti ọdún mẹ́ta sẹ́yìn ni àwọn èèyàn máa ń ṣe ìwọ́de káàkiri Nàìjíríà láti fi ṣe ìrántí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn àtàwọn tó farapa lásìkò ìwọ́de #EndSARS.















