Isiaka Jimoh EndSars Ogbomoso: Èmí kò ní kí wọ́n pa ọlọ́pàá tó pa Isiaka, ṣùgbọ́n...- Ramota, Iya Isiaka

Àkọlé fídíò, #EndSars Ogbomoso: Èmí kò ní kí wọ́n pa ọlọ́pàá tó pa Isisaka, ṣùgbọ́n...- Ramota, Iya Isi

A ti ri awọn iranlọwọ kan gba lọdọ awọn alaanu eeyan kan ṣugbọn....- Zainab Akinbola, Iyawo Isiaka Jimoh

Awọn ọlọpaa yinbon pa ọmọ mi lati ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun2020 ṣugbọn a ko tii ri idajọ gba titi di isinyi bi ijọba ṣe leri fun wa nigba naa.

Eyi ni ọrọ Jimoh Atanda, to jẹ ba Isiaka ti awọn ọlọpaa yinbọn pa ninu iwọde EndSars to waye lọdun to kọja ni Ogbomọso ni ipinlẹ Oyo ni guusu Iwọ oorun Naijiria.

Isiaka

Ramota, iya Isiska sọ pe nitootọ ni gomina Seyi Makinde wa ba wọn kẹdun ṣugbọn owo ko le da ọmọ oun pada.

O ni gbogbo arọwa eeyan ko le da Isiaka pada fun oun ati pe idajọ ododo nikan ni oun n fẹ.

Bẹẹ kii ṣe pe ki wọn pa awọn ọlọpaa to huwa ibi naa si ọmọ oun.

Baba Isiaka ṣalaye nipa ọmọ rẹ pe abikẹyin bii akọbi ni lọwọ oun ati pe Isisaka kii muti, kii mu siga, kii huwa lile rara.

Akinbọla Zainab to jẹ iyawo Isiaka sọrọ nipa iranlọwọ to ti ri gba ati eyi to ṣi n reti lati fi ri si eto ẹkọ ọmọ to bi fun Isiaka.