Prof Edwin Ijeoma: Ọ̀jọ̀gbọ́n Ijeoma ní òun kìí ṣeọmọ Nàìjíríà mọ́, South Africa tó yàn dípò bá tún lée jáde

Oríṣun àwòrán, Premium times
Ọjọgbọn ọmọ Naijiria kan ti oruks rẹ n jẹ Edwin Ijeoma kọ ipakọ si orilẹede Naijiria lọdun 1998 pẹlu ileri pe oun kii ṣe ọmọ orilẹ-ede Naijiria mọ,o si gba iwe ọmọ onilẹ ti orilẹede South Africa.
Amọṣa, nnkan ti ba ibomiran yọ fun bayii ti ọrọ rẹ si ti di ti ko gbele ko gbeta bii ti ilẹkun aganrandi.
Orilẹede South Africa to gba gẹgẹ bi orilẹede rẹ ti lee jade bayii, wọn si ti fa iwe ijọmọonilẹ rẹ ya.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o se igbeyawo alarede pẹlu obinrin ọmọ orilẹ-ede South Africa kan nigba to mọ pe oun ni iyawo alarede miran.
Gẹgẹ bi awọn iwe iroyin abẹle kan ni orilẹ-ede naa ṣe sọ, ọdun 1998 ni Ọjọgbọn Ijeoma de sorilẹ-ede South Africa lati Naijiria lati kẹkẹ ni fasiti Pretoria.
Wọn ni ọgbọn ẹwẹ ṣiṣe igbeyawo alarede pẹlu obinrin kan lorilẹ-ede naa lo fi gba iwe igbelu ati ijọmọ onilẹ to gba.
Ni ọdun 2005 lo di ọmọ onilẹ ki o to kọ iyawo rẹ to jẹ ọmọ orilẹede South Africa silẹ lọdun 2007 nitori aile bimọ wọn.
Lẹyin eyi ni wọn ni obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Anne Tomo darapọ mọ lorilẹ-ede South Africa.
Wọn si ṣakiyesi ninu ọkan lara awọn iwe ti arabinrin naa fi ṣọwọ si ileeṣẹ ijọba orilẹ-ede naa lori ọrọ iwe igbelu fihan pe oun ati ọjọgbọn naa ti ṣe igbeyawo lọdun 1993.
Eleyii to mu ki ileeṣẹ ijọba orilẹede naa o fidi rẹ mulẹ pe o ṣe igbeyawo alarede pẹlu obinrin meji ọtọọtọ.

Oríṣun àwòrán, facebook/ ijeoma edwin
Wọn ni nigba ti wọn bi Ọjọgbọn Edwin Ijeoma leere nigba to n beere fun iwe ijọmọ onilẹ lorilẹ-ede naa pe ṣe o ni mọlẹbi kankan lorilẹ-ede Naijiria, ohun to sọ ni pe aburo oun ni Anne Ijeoma, kii ṣe iyawo.
Awọn alaṣẹ lorilẹorilẹ-ede South Africa woye pe ọgbọn ati gba iwe igbelu ati ọmọ onilẹ ni Ọjọgbọn Ijeoma da to fi gbe ọmọ ilẹ South Africa to kọ silẹ niyawo.
Nibayii, wọn ti fa iwe igbelu ati iwe ọmọ onilẹ rẹ ya.
Ẹwẹ fasiti Fort Hare nibi ti Ọjọgbọn Edwin Ijeoma ti n ṣiṣẹ ni lati ọdun to kọja ni wọn ti paṣẹ ko lọ rọọkun nile fun awọn iwa aṣemaṣe kan to hu.
Agbẹnusọ fun fasiti naa, Tandi Maputa ṣalaye fun Premium Times pe ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 ni wọn ti ni ko lọ rọọkun nile.
Ati pe iwadii lori iwa aitọ to hu naa ṣi n lọ ati pe o kan ṣe kongẹ asiko ti ọbẹ ileeṣẹ ọrọ abẹle lorilẹede naa baa niru ni.
- Wo bí o ṣe lè forúkọsílẹ̀ láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsárá Covid-19 lẹ́yìn to bá dé sí Naijiria
- Sunday Igboho gbọdọ̀ gbàṣẹ ìdáàbòbò láti iléẹjọ́ tí kò ní jẹ́ kí ọlọ́páá mú un- Amòfin Ozekhome
- A ò ní kó oúnjẹ lọ sílẹ̀ Yorùbá láì jẹ́ pé ààbò wà fáwọn Fulani níbẹ̀- Miyetti Allah
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
- Nítorí 'áfúsá', àwọn nọ́ọ̀sì bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì l'Ondo
- Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó dá mi lọ́nà lọ́jọ́ Ẹtì fẹ́ pa mí ni -Sunday Igboho
















