Yoruba-Fulani crisis: Miyetti ní àwọn ò ní fààye gba kíkó oúnjẹ lọ sílẹ̀ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, others
Alakoso ẹgbẹ darandaran Miyetti Allah ẹka ipinlẹ Kwara, Aliyu Mohammed sọ pe dide awọn ounjẹ ati maalu lati oke ọya silẹ Yoruba nipinlẹ Kwara yoo tẹsiwaju.
Mohammed ni ayafi ti aabo to peye ba wa fawọn Fulani nilẹ Yoruba ni awọn fi le dẹkun didena kiko ounjẹ ati maalu lọ síbẹ.
BBC Yoruba ṣabẹwo si ọja Bodija ki a mọ ohun to n ṣẹlẹ gan an ni pato:
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Mohammed ṣalaye pe eyi jẹ ìkìlọ lati ri i pe awọn Fulani to wa nilẹ Yoruba n ṣe ọwọ wọn ni alaafia lai si pe ẹnikẹni n dunkoko mọ wọn.
O ni irọ ni ọrọ tawọn kan n gbe kiri pe ọdaran ni gbogbo awọn Fulani.
- Wo ohun tí BBC rí nílé Seriki Fulani ní Igangan
- Ṣé lóòtọ́ọ́ láwọn Fulani tún ṣá aráàlú Igangan méjì ládàá nígbà tí wọ́n ń sùn?
- Ẹ̀yin tẹ́ẹ tako àgbékalẹ̀ àgọ́ Fulani, ìkórira ló ń yọ yín lẹ́nu - Ìjọba àpapọ̀
- Gbogbo ẹ̀yin Fulani darandaran tó wà ní ìgbó ìjọba ní Ondo, ọjọ méje lẹní láti pòórá - Gomina Akeredolu
- 'Iha kokanmi Buhari lewu fun Nigeria'
Mohammed ni ko si ẹya tabi ede ti ko ni awọn eeyan to dara at'awọn to buru, kii ṣe ninu ẹya Fulani nikan ni iru rẹ wa.
"Kii ṣe Fulani nikan lo n huwa ọdaran lorileede Naijiria, ṣugbọn ohun to buru ni pe Fulani nikan lawọn eeyan n sọ pe o wa nidi gbogbo laabi to n ṣẹlẹ ni Naijiria," Mohammed lo woye bẹẹ.
Alaga Miyetti Allah nipinlẹ Kwara ni ẹgbẹ ṣetan lati fa awọn Fulani ọdaran le awọn ọlọpaa lọwọ ni Kwara.
Mohammed ni "awọn fijilante wa n kaakiri igbo ijọba lati mu awọn ọdaran Fulani ti wọn n ba awọn Fulani darandaran jẹ.
Mohammed rọ ijọba apapọ lati fi ọwọ òfin mú Sunday Igboho lẹyin to ni kawọn Fulani fi ilu Igangan silẹ.
- Ẹ wo ǹkan tí a mọ̀ nípa Sheik Gumi tó ń dúnà-dúrá pẹ̀lú àwọn agbébọn ní Nàìjírìá
- Sunday Igboho gbọdọ̀ gbàṣẹ ìdáàbòbò láti iléẹjọ́ tí kò ní jẹ́ kí ọlọ́páá mú un- Amòfin Ozekhome
- Ọmọba Harry ṣọ kókó márùn ún nípa ìgbé ayé Amerika lẹyìn tóun àti Meghan fi London sílẹ̀
- Ẹ wo àwọn tí yóò kọ́kọ́ gba abẹ́rẹ́ àjẹsárá Covid-19 to bá dé sí Naijiria...
- Man United kò bá lu Chelsea mọ́lé, àmọ́ rẹfirí jà wá lólè pẹnárítì- Ole yarí





















