Isinkan regent: Mo pa màálù, àgùtàn àti àwọn ètùtù míì kí ń tó di Adelé Oba ní Isinkan- Adelé Florence Aladetoyinbo
Inu mi dun pe mo gbeyin Oba to je baba mi- Adele Margret Ifedayo
Dandan ni ki Adelé fi orí ìtẹ́ sílẹ̀ ní kété ti ìlú bá ti yan Oba tuntun- Adele Ifedayo.
Ilu Isinkan jẹ ọkan lara ilu mẹta to gbe Akurẹ ro nipinlẹ Ondo.
BBC Yoruba ṣabẹwo sibẹ lati mọ bi nkan ṣe n lọ lẹyin ti Oba Joseph Olu Ojo ti Iralepo waja lọjọ kẹta, oṣu keji, ọdun 2021.

Iyaafin Omonije Margret Ifedayo lo n dele gẹgẹ bi Oda bayii ni ilu Isinkan, ijọba ibilẹ guusu Akurẹ, nipinlẹ Ondo.
O salaye nipa bi wọn se n sin oku ọb ato waja lori ijoko rẹ ati awọn igbesẹ to rọ mọọ.

Bakan naa ni Adele Margret Ifedayo yii menuba idi ti wọn fi n yan adele nipo naa ki ori apeere ma baa ṣofo.
O sọ nipa arẹmọ obinrin Oba to maa n fi gun Okiti Omolore lasiko ti Oba ba fẹ gba ade ati ipo ti ọmọ akọbi obirin naa n ni lawujo ati ninu eto iṣejọba.
- O lé rí ìrànwọ́ gbà lórí ìwà ipá nínú ìdílè àti ìfipábánilòpọ̀ nípasẹ̀ lílo UNSUB App
- Àwọn kànga ìṣẹ̀ǹbáyé rèé ní Badagry tó ń pa ẹrú níyè
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìlú Ondo fọkọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá
- Ọmọ tí wọ́n bá fi èdè Yorùbá kọ́ ní ẹ̀kọ́ máa ń pegedé jú tí èdè míràn lọ- Ọjọgbọn Ogundeji
Adele Isinku ni lati ọdun 1978 ti baba oun ti joba loun ti mọ pe oun naa a gu ori itẹ naa ki ẹlẹmi ma gba a.
O tun sọ nipa pataki Ifa dida lasiko yiyan ọba tuntun ni Isinkan, ni ijọba ibilẹ guusu Akurẹ nipinlẹ Ondo.
O gbadura fun ọgbọn Olorun ati ootọ inu lati dari awọn eeyan naa bi o ti yẹ.

Iya agba Florence Aladetoyinbo to ti fi igba kan jẹ Adele ni ilu Isinku ni ipinlẹ Ondo na ba BBC soro, ilẹ kun!
Iya Adele naa sọrọ nipa eto inu jijẹ adele bii pipa malu kan, agutan kan, titẹ ẹjẹr rẹ mole lẹnu ọna pẹlu ẹsẹ ọtun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Mama Florence mẹnuba gbogbo igbesẹ yiyan ọba ati pataki titẹlẹ iṣẹṣẹ nilẹ Yoruba.
Iya naa fi ayọ rẹ han si awọn iṣẹ to ri ṣe yanju laisko to n dele lẹyin ti baba rẹ waja ki ilu Isinkan to yan Ọba miran nigba naa.
O ni atubọtan ẹni to ba ṣe ipo adele daadaa maa n dara pẹlu ere to pọ.
Ki Olorun yan ọba rere fun awọn eeyan Isinku laipẹ ki ẹmi awọn Adele naa si gun sii.
- Ọmọ tí wọ́n bá fi èdè Yorùbá kọ́ ní ẹ̀kọ́ máa ń pegedé jú tí èdè míràn lọ- Ọjọgbọn Ogundeji
- Ọkùnrin kan gún olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́bẹ lórí N85,000 lẹ́yìn tó kọ̀ láti ṣèyàwó pẹ̀lú rẹ̀
- Awolọwọ ní tí àsìkò bá tó, ọ̀dọ́ á jà fúnra wọn- Sunday Igboho
- Mo kọ̀ láti gbọ̀jẹ̀gẹ́ tàbí bẹ̀rù ẹnikẹ́ni nítorí ìjà òmìnira ìran Yorùbá- Igboho
- Mi ò gba kobo ní gbogbo ọ́dún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Osun - Aregbesola




