Regent female kings: Wo àwọn Adelé-Ọba aládé méje tó jẹ́ obìnrin nílẹ̀ Yorùbá

Obinrin ori ade ilẹ̀ yoruba

Oríṣun àwòrán, others

Wo àwọn ọ̀dọ́bìrin tó tún jẹ́ Ọba aládé ní ilẹ̀ Yoruba

Ni Naijiria, ọkunrin lo maa n ṣaba n jẹ ọba, paapaa nilẹ Yoruba.

Ṣugbọn lọpọ igba, awọn obinrin naa maa n gori itẹ baba wọn gẹgẹ bi adele titi ti awọn afọbajẹ yoo fi yan ẹni ti ade tọ si.

Awọn obinrin naa maa n wọ aṣọ, ṣokoto ati fila gẹgẹ bi okunrin lasiko ti wọn ba wa lori itẹ gẹgẹ bi ọba tabi adele.

Wo diẹ lara awọn adele obinrin to wa ni ilẹ Yoruba lasiko yii.

1) Moyinoluwa Olubunmi Falowo:

Falowo ni adele ọba ilu Ibulẹ, ni ijọba ibilẹ Ifedore, ni ipinlẹ Ondo.

O kọ ẹkọ nipa imọ Microbiology ni fasiti imọ ẹrọ, OSUSTECH, ni ipinlẹ Ondo kan naa.

Falowo gori itẹ gẹgẹ rẹ lọdun 2019 lẹyin ti baba rẹ papoda, oun ni yoo si wa lori oye titi ti awọn afọbajẹ yoo fi yan ẹni ti oye kan.

Àkọlé fídíò, Ojú mi ti rí lọ́pọ̀ lọpọ̀, àmọ́ mo dúpẹ́ pé mo ti pé ọdún márùn ún lórí oyé- Ooni

2)Taiwo Oyebola Agbona:

Agbona gori itẹ baba rẹ lọdun 2017 lẹyin ti Alaaye ti ilu Aaye, Oba Agbona Orimori dagbere faye lọjọ kẹrin, oṣu Karun un, ọdun 2017.

Agbona kẹkọọ nipa imọ Microbiology, ni fasiti Achievers, to wa ni ilu Owo, iyẹn ni ipinle Ondo.

3) Tinuade Babalola Adejuiyegbe:

Tinuade ni Oluboropa, ti ilu Iboropa Akoko- Akoko, ni ipinlẹ Ondo.

Wọn de Tinuade lade loṣu Keji, ọdun 2015, lẹyin ti baba rẹ Ọba Emmanuel Ayowole Adejuyigbe waja.

Lasiko ti wọn de lade, o si jẹ akẹkọọ ni fasiti ijọba ipinlẹ Ondo, iyẹn fasiti Adekunle Ajasin to wa ni Akungba-Akoko nibi to ti n kẹkọọ nipa iṣeto ilu.

O kẹkọọ jade lọdun 2018, o si lọ sinru ilu gẹgẹ bi Ọba alade akọkọ ti yoo ṣe agunbanirọ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Kikelomo Ogunboye tan ìmalẹ̀ sí ìwà olè ọ̀gá ọlọ́pàá

4) Elizabeth Olayinka Tolani Orogun:

Elizabeth ni Adele Ọba ilu Akunu-Akoko, ni ipinlẹ Ondo.

Àkọlé fídíò, Omolola Arohunmolase Welder: Mo ti fí iṣẹ́ 'Welder' gbayì láwùjọ, tó mo fi tọ́ ọmọ yanjú

5) Adekemi Omorinbola:

Omorinbola ni Asin ti ilu Oka Akoko ni ipinlẹ Ondo.

Ile iwe girama lo wa lọdun 2010 nigba to gori itẹ baba rẹ gẹgẹ bi Adele.

Lẹyin naa lo lọ kawe sii ni fasiti ijọba ipinlẹ Ekiti, to wa ni ilu Ado Ekiti, to si kẹkọọ nipa Psychology gẹgẹ bi Ọba alade.

Omorinbola ni abikẹyin baba rẹ ṣugbọn iroyin ni oun ni ifa mu ninu awọn ọmọ obinrin mẹfa baba rẹ lati gori itẹ naa.

6) Ọmọba Damilola Falegan:

Damilola ni Adele Ọba ilu Irese, ni ijọba ibilẹ Ifedore, ni ipinlẹ Ondo.

Ọjọ Kọkanla, oṣu kọkanla, ọdun 2020 yii ni Adele naa pe ẹni ọdun marundinlọgbọn laye.

Àkọlé fídíò, Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ti já àbálé Esra lábẹ́ àwáwí àyẹ̀wò wúndíá

7) Tejumade Falade Adeboye:

Tejumade ni Baalẹ Odopetu, ni ilu Akure, ko pẹ ti wọn gbe niyawo tan to gori itẹ naa.

Ọjọ kẹsan an, ọsu Kọkanla, ọdun 2020 lo ṣe ayẹyẹ ọdun kan to ṣe igbeyawo.

Iṣẹ aṣọ riran lo yan laayo.