Tinubu 2023: Àwọn èèkàn ilẹ̀ Yorùbá ń ṣèpàdé ṣáájú dídìbò fún Tinubu ní 2023

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Asiwaju Tinubu

Ilẹkẹ ma ja sile, ilẹkẹ ma ja sode, ibi kan ni yoo kuku pada jasi nipa ẹya ti yoo jẹ aarẹ orilẹede Naijiria to mbọ.

Gẹgẹ bi awọn ọmọ Naijiria ṣe wa n reti ibi ti ilẹkẹ ipo naa yoo jasi laarin ẹya gboogi mẹta to wa lorilẹede Naijiria, awọn tọrọ kan ti bẹrẹ si ni gbe igbesẹ.

Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ ni ilu Ibadan tii ṣe olu ilu ipìnlẹ Oyo, lawọn eekan tọrọ kan ni iha Guusu-Iwọ Oorun Naijiria yoo ti korajọ lati jiroro lorii ohun to wa niwaju fun il Yoruba ṣaaju idibo ọdun 2023.

Àkọlé fídíò, Kollington ṣàlàyé bí orin Fuji ṣe bẹ̀rẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà

Ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin Naijiria tẹlẹ, Họnọrebu Rotimi Makinde lo fi ọrọ naa lede lorukọ ẹgbẹ South West Agenda 2023 eyi ti wọn pe ni SWAGA 23.

Wọn n ṣe eyi gẹgẹ bi igbaradi lati mu ala asiko oṣelu tuntun ni ilẹ Yoruba ṣẹ.

Awọn to ṣe agbatẹru eto naa ni yoo jẹ aaye lati kede ipinu awọn to ba fẹ lati to sẹyin agba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Bola Ahmed Tinubu ki wọn lee fi orukọ rẹ ṣọwọ fun ipo aarẹ lọdun 2023.

Gbogbo awọn tọrọ kan lati ipinlẹ Eko, Oyo, Osun, Ondo, Ekiti ati Ogun yoo pade lati sọrọ lori awọn igbesẹ ti wọn yoo gbe ninu afẹfẹ oṣelu tuntun to ba fẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Mọ̀ síi nípa ìró afárànma àti agbárànmọ́ fáwẹ́ẹ̀lì Yorùbá