Coronavirus in Lagos: Sanwo-Olu ti ilé ẹ̀kọ́ pa, fòfin de ayẹyẹ àdúgbò àti òde fàájì torí ọwọ́jà àrùn

Aworan gomina Eko ati ọsọ ọdun Keresi

O n bọ, o n bọ, awọn laa dẹ de e, eyiun laye ijọun amọ lode toni, oju ni wọn n mu to.

Eyi lo mu ki gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu pakiti mọlẹ lati ka ọwọja itankalẹ arun Coronavirus to n pelesi nipinlẹ naa ko nipa awọn igbesẹ kan.

Lara igbesẹ to si gbe naa ni fifi fofin de gbogbo ayẹyẹ aarin àdúgbò, kánífà òpín ọdún ati gbogbo ode faaji nitori ọwọja arun Coronavirus lẹẹkeji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sanwo-Olu lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to wa loju opo ijọba ipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bi Sanwo-Olu ṣe sọ, àwọn ilé ijó kò ti di ṣíṣí títí di àsìkò yìí, ṣugbọn ki wọn ti eyikeyi to ba ti di ṣiṣi pada titi di gbedeke aláìlọ́jọ́.

Àkọlé fídíò, Zlatan: Ọ̀rẹ́ ni mo sìn lọ ‘studio’ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ orin lẹ́yìn tí mo kùnà ìdánwò WAEC

Bakan naa ni Sanwo-Olu tun pàṣẹ pé kí gbogbo ilé ẹ̀kọ wà ní títì pa titi di asiko ti ijọba yoo mọ igbesẹ to kan.

Bẹẹ naa ni kí gbogbo àwọn òṣìṣẹ̀ ìjọba lati ipele ikẹrinla si isalẹ maa ṣiṣẹ lati ile wọn fun ọjọ mẹrinla gbako, bẹrẹ lati ọjọ Aje to n bọ, àyàfi to bá jẹ́ pàjàwìrì tàbi tí wọn bá jẹ àwọn oṣíṣẹ kòṣeemáni.

Ni ti awọn ile ijọsin, o ni ki awọn adari ẹsin ri daju pe awọn eeyan to peju si ṣọọṣi àti mọ́sálásì kò kọ́ja ààdọ́tà lọ, ìsìn kò sì gbọdọ̀ kọ́ja wákàtí méjì pere.

Àṣẹ yìí jẹ́ ọ̀kan lára alàálẹ̀ ìjọba ipinlẹ Eko lórí ìlera ará ìlú to fi síta lọ́jọ́ Eti.

Àkọlé fídíò, Baruwa Gas Explosion: Àwọn tó forí sọta ìjàmbá iná ń bẹ ìjọba láti dìde ìrànwọ́

Sáájú ni gómìnà ọhun ti fara kasa ààrùn Coronavirus, sùgbọ́n ó ti n gbádùn.

Ètò kóníléógbélé alágo méjila oru si mẹ́rin ìdájú ti ìjọba àpapọ̀ gbé silẹ̀ kò ti kásẹ̀ nílẹ̀, bákan naa ni lílo ìbòmú ṣe pàtàkì láàrín èrò, nílé iṣẹ́, àti inú ọjà.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano pàṣẹ pé kí gbogbo ilé ẹ̀kọ́ ètò ìlera di títì pa

Aworan Gomina Ganduje

Oríṣun àwòrán, @Dawisu

Gomina ipinlẹ ipinlẹ Kano, Abdullahi Umar Ganduje, ti paṣẹ pe ki awọn ile ẹkọ eto ilera nipinlẹ naa ko wa ni titi pa.

Alẹ ọjọ Iṣẹgun ni aṣẹ yii jade lati ẹnu kọmisanna fun et ilera, Dokita Aminu Ibrahim Tsanyawa, to gba ẹnu gomina sọrọ.

Ṣaaju ni kọmisanna fun eto ẹkọ, Muhamaad Sanusi Kiru ti paṣẹ pe ki awọn ile ẹkọ aladani ati ti ijọba o wa ni titi pa.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ko sọ idi to fi pa aṣẹ naa, awọn kan sọ pe o ṣe e ṣe ko jẹ nitori bi awọn agbebọn ṣe ko awọn akẹkọọ nileewe Government Science Secondary School, Kankara nipinlẹ Katsina.

Ipinlẹ Kaduna naa ti kọkọ kede iru aṣẹ yii, amọ nitori itankalẹ Covid-19 ni.

Àkọlé fídíò, Iwode fun Ochanya ti won ba lopo waye nilu Eko

Nitori ọwọja keji ti aarun coronavirus n ba de bayii, ijọba ipinlẹ Kaduna ti kede pe ki gbogbo awọn ileewe titi kan fasiti o wa ni titipa bẹrẹ lati Ọjọru, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kejila ọdun 2020.

nasir El-Rufai, gomina ipinlẹ Kaduna

Oríṣun àwòrán, Twitter/ governor kaduna

Aṣẹ ti ijọba ipinlẹ naa fi sita rọ gbogbo awọn adari ileewe lati rii daju pe gbogbo idanwo wa sopin lẹyẹ o ṣọka ki wọn si ti ileewe gbogbo l'Ọjọru.

Igbesẹ yii waye pẹlu bi ajakalẹ arun naa tun ṣe n dabi ẹni to tun fẹ maa gbẹrẹgẹjigẹ sii.

aworan ajade naa

Oríṣun àwòrán, Twitter/governor kaduna

Atẹjade kan ti ileeṣẹ eto ẹkọ ijọba ipinlẹ naa fi sita rọ awọn ileewe lati rii daju pe wọn bẹgi le eto ẹkọ ninu ileewe, ki wọn wa ọna abayọ miran lati fi ṣeto ẹkọ fun awọn akẹkọọ to ba di dandan.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Mọ̀ síi nípa ìró afárànma àti agbárànmọ́ fáwẹ́ẹ̀lì Yorùbá

Bakan naa ni wọn tun fi kun un pe awọn ileeṣẹ redio ati tẹlifiṣan ipinlẹ naa yoo tẹsiwaju lati maa ṣe eto ẹkọ lori ikanni wọn gẹgẹ bi wọn ti ṣe n ṣe tẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Kollington ṣàlàyé bí orin Fuji ṣe bẹ̀rẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà