Sex party: Ìjọba gbé ilé ijó oníhòhò tì pa lórí ẹ̀sùn títàpá sí ìlànà àti dẹ́kun coronavirus

Aṣe\wo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa gbe ile ijo ibalopọ ti pa lori ẹsun pe wọn kuna lati tẹle ilana ati gbogun ti ajakalẹ arun coronavirus fun igba keji laarin ọsẹ kan.

Ile ijo naa to wa niluu Paal lorilẹede Belgium di titi pa lọjọ Ẹti to lọ ni deedee ago mẹsan an aabọ.

Gbogbo awọn mẹwaa to wa nibẹ ni wọn ni ki wọn sanwo itanran to din diẹ ẹgbẹrun lọna ọgọfa.

Ọpọ awọn ọkunrin ati obinrin to wa nihoho lawọn ọlọpaa ri lati oju ferese, bakan naa ni wọn paaki ọkọ sita rẹgẹdẹ.

Awọn ọlọpaa ko kọkọ raye wọle lẹyin ti wọn ti ilẹkun ile ijo onihoho naa.

Amọ awọn oṣiṣẹ panapana lo fi ipa ṣi ilẹkun naa ki awọn ọlọpaa to raye wọle.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Kikelomo Ogunboye tan ìmalẹ̀ sí ìwà olè ọ̀gá ọlọ́pàá

Eeyan mẹfa lọwọ ọlọpaa kọkọ tẹ ki wọn to mawọn mẹrin mii ninu eyi ti ọkan lara wọn ti lọ sa pamọ.

Igba keji ree tawọn ọlọpaa yon fi ipa ṣi ilẹkun ile ijo laarin ọsẹ kan lorilẹede Belgium.

Àkọlé fídíò, Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ti já àbálé Esra lábẹ́ àwáwí àyẹ̀wò wúndíá

Lọjọ kinni ,oṣu kejila, ọdun 2020 yii lawọn ọlọpaa mu ọkunrin mẹẹdọgbọn ni ihoho niluu Brussels nibi ti oloṣelu aṣofin ilẹ Hungary ti n saa lọ.

Awọn agbofinro mawọn ọkunrin naa lẹyin tawọn ara adugbo lọ fẹjọ sun ileeṣẹ ọlọpaa pe ariwo awọn ọkunrin pọ lati ile ijo ti wọn wa lẹkun tawọn ololufẹ akọ sakọ pọ si ni rue des Pierres.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Wo ìtàn ìyá kan ìyá kan àtàwọn olè ajọ́mọgbé tó n ta ọmọ ní Kenya