Oyo Coronavirus: Makinde ní kò sí ọwọ́jà Coronavirus ẹlẹ́ẹ̀kejì ní ìpínlẹ̀ Oyo

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọ pe akọsilẹ fihan pe ọwọja keji arun covid-19 ko tii wọ ipinlẹ naa.
Makinde ni lootọọ ni akọsilẹ NCDC ṣe afihan pe ọwọja coronavirus ẹlẹẹkeji n peleke sii ni Naijiria lojojumọ.
Amọ, Makinde sọ pe iwadii ati ayẹwo ti ipinlẹ Oyo ṣe lori bi coronavirus ṣe n ran nipinlẹ naa fihan pe, ko buru ju ti at'ẹyin wa lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
- Njẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa àríyá oníhòhò àti ìbálòpọ̀ tó fẹ́ wáyé ní Kaduna lásìkò ọdún?
- Ìjọba gbé ilé ijó oníhòhò tì pa lórí ẹ̀sùn títàpá sí ìlànà àti dẹ́kun coronavirus
- Ilé aṣòfin Amẹ́ríkà yọ ààrẹ Donald Trump nípò fún ìgbà kejì
- Ìdí mẹ́fà rèé tí Instagram, Facebook le fi wọ́gilé ojú òpó ìkànsíraẹni rẹ
- Ìdí tí àwọn èèyàn kan kò fí le ni àrùn Coronavirus
Gomina makinde sisọ loju ọrọ yii lasiko to n se ipade akọroyin lori arun Coronavirus ati eto aabo ipinlẹ Oyo.
Atẹjade ajọ NCDC fihan pe eeyan to le ni irinwo lo ko coronavirus laarin ọsẹ meji nipinlẹ Oyo.
Makinde ṣalaye pe ipinlẹ Oyo ṣe ayẹwo Coronavirus fun ẹgbẹrun lọna ogun eeyan láàrin oṣu kẹta si oṣu kejila ọdun 2020.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Makinde ni ẹgbẹrun mẹta ninu awọn eeyan ọhun ni ayẹwo fihan pe wọn ni covid-19.
"A tun ti ṣe ayẹwo fun ẹgbẹrun mẹrinla eeyan mii nipinlẹ Oyo lati oṣu kejila ọdun 2020 si akoko yii, eeyan mẹrindinlẹẹdẹgbẹrin(696) ni ayẹwo fihan pe wọn larun coronavirus," Makinde ṣalaye.
Gomina Makinde ni ijọba oun ko ni kaarẹ nipa eto ilanilọyẹ lori ati dena Coronavirus nipinlẹ Oyo.
O ni ajakalẹ arun covid-19 si wa ni Naijiria, amọ "sayẹnsi n sọ fun wa pe a le bori arun naa nipa ṣiṣọra."
Makinde ni ohun to tọ ni pe ki onikaluku tẹle sayẹnsi.
Gomina ko ṣai rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati maa tẹle Ilana idaabo bo ara ẹni lọwọ covid-19 nípa wíwọ ibomu, fifọwọ deede ati itakete sí ara ẹni.
Gomina ipinlẹ Oyo ni ijọba n ṣiṣẹ lati rii pe ajọṣepọ to dan mọran wa si laarin ile iwosan UCH ati ile iwosan ajakalẹ arun to wa ni Olodo n'Ibadan.
Bakanna lo ṣọ pe ijọba n ṣe eto ilanilọyẹ fawọn ile iwosan aladani lori ati maa tẹle Ilana ati gbogun ti ajakalẹ arun covid-19.
Gomina ni ijọba tun ti n ba ileeṣẹ aladani kan sọrọ lori ipsese afẹfẹ emi "oxygen" fawọn alarun Covid-19 to ba nilo rẹ.
"Ẹ̀yin tẹ̀ ń parọ́ ẹlẹ́yà-mẹ̀yà mọ́ Amotekun Oyo, Seyi Makinde lẹ̀ ń dojú ìjà kọ"

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde
Ijọba ipinlẹ Oyo ti bẹnu atẹ lu bawọn kan ti se n gbe irọ kiri nipa ikọ Amọtẹkun, lati le foju kere aseyọri wọn, ki wọn si fi da wahala silẹ nilu.
Agbẹnusọ Gomina Seyi Makinde lori ọrọ ẹrọ ayelujara Jide Ajani lo sọrọ yii, pẹlu bi awọn eeyan kan se n fi ẹsun kan Amotekun Oyo pe wọn n pa eeyan lainidi.
Lara ẹsun naa ni ọkan to ni se pẹlu iku awọn eeyan meje kan, to fi mọ arakunrin kan ati awọn ọmọ rẹ meji ti wọn pa lọjọ Abamẹta, lẹyin ikọlu to waye laarin ikọ Amọtẹkun pẹlu awọn agbebọn ni Aiyete Ibarapa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- N kò jà fún ìṣọ̀kan Yorùbá láti wá ipò tàbí orúkọ - Sunday Igboho
- Afurasí agbébọn 47 bọ́ sọ́wọ̀ ikọ̀ ‘Operation Burst’ l‘Oyo
- Iye àwọn tó ń ní Covid-19 ti ń pọ̀ ju ilé ìwòsàn lọ, tó bá yá ọwọ́ wa ò ní ka mọ́ - NCDC
- Kí ló ma n fa Àkúfà nílẹ̀ Yorùbá, àti ọ̀nà àbáyọ?
- À ó ṣe àtúngbéyẹ̀wò àsìkò ìwọ́le àwọn akẹ̀kọ̀ọ́-Ìjọba apapọ̀
- Báwo ni #stingymenassociation ṣe gba ojú òpó twitter kan?
- Àfàìmọ̀ ká máa dá ìforúkọsílẹ NIN dúró tórí ewu coronavirus- Mamora
- Pásítọ̀ Adeboye kéde ààwẹ̀ ọjọ́ 63 fọ́mọ ìjọ rẹ̀, ariwo sọ lórí ayélujára
Losu Kejila ọdun to lọ, ikọ Amọtẹkun tun ni wọn lo pa akẹkọọ kan ti wọn ni adigunjale ni.

Bẹẹ naa ni ẹnu ko sin lẹyin ikọ naa lori iku ọlọpaa kan to waye ni agbegbe Sango ni ilu Oyo lọjọ Kẹrin osu Kini.
Ohun ti Ajani sọ si gbogbo awọn ẹsun tawọn eeyan fi n kan Amọtẹkun ni pe, wọn n lo ẹsun ẹlẹyamẹya lati fi doju ija kọ Amọtẹkun lọna a ti bawọn jẹ.
O ni ahesọ tawọn eeyan n gbe ka paapa lori isẹlẹ to n waye ni Ibarapa jẹ ọna ati da omi tutu sookan aya Gomina Seyi Makinde.
Ninu atẹjade to fi sita, Ajani sọ pe''Ki lo de tawọn eeyan fi n ti irọ ẹlẹyamẹya mọ Amọtẹkun pẹlu bi wọn se koju awọn ọdaran? Se wọn fẹ pa ikọ naa rẹ ni? Wọn o ti se aseyọri.''
O tẹsiwaju pe, awọn to n gbe ahesọ ọrọ kiri fẹ si Gomina Makinde lọna ni. Wọn ti kuna wọn si ti mu ofo. Awọn to fẹ lo Amọtẹkun lati fi maa kọrin ẹlẹyamẹya yoo kan idin ninu iyọ. Ala ti ko ni le sẹ ni''
Gẹgẹ bo ti se sọ́, isẹ yi Amọtẹkunse lawọn ijọba ibilẹ mẹrin to ja si iku eeyan mẹjẹ wọn ko da nikan se.
O ni awọn ati ẹgbẹ Miyetti Allah awọn fijilante ati ọlọde ni wọn gbarijọpọ koju awọn ọdaran nibẹ.
O fi kun pe ko si ootọ ninu ọrọ pe awọn n doju ija kọ awọn eeyan ẹya kan ni.
O salaye pe o yẹ ki wọn gbosuba kaare fun ikọ Amọtẹkun ni pẹlu bi wọn ti se doju ija kọ awọn ọdaran ni lawọn ijọba ibilẹ mẹrin.
''Ohun to tun yẹ ki a gboriyin fun ni ajọsepọ laarin Amọtẹkun ati awọn fijilante ọlọdẹ ati Miyetti Allah. Koda kii se Miyetti Allah lasan, awọn Fulani bawọn lọwọ ninu ibasepọ yii, ti wọn si fi ọrọ to Seriki awọn Fulani leti''
Wo àwọn ohun tí Amotekun kò ní le è ṣe mọ́ ní ìpínlẹ̀ Oyo...

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde
Alaga ajọ alaabo nipinlẹ Ọyọ, Oyo State Security Network ti ọpọ mọ si Amọtẹkun, Ọgagunfẹyinti, Ajibọla Toogun ti alaye awọn ohun ti awọn oṣiṣẹ amọtẹkun ko ni ṣe .
Oniruuru ahesọ ọrọ lo ti n waye nipa ipa ti awọn oṣiṣẹ Amọtẹkun yoo maa ko gan ti ẹru si n ba ọpọ pe ṣe wọn ko ni tọ ipasẹ aṣiṣe ọlọpaa pẹlu.
- Lóòtọ́ ni mo yìnbọn níbi yánpọnyánrin tó wáyé ládúgbò mi-Seun Kuti
- ''Buhari àti Tinubu ṣ'àdéhùn pé Yorùbá ni yóò jẹ́ olùdíje ipò ààrẹ APC lọ́dún 2023''
- Àṣeyọrí Anthony Joshua fi hàn pé owó tí à ń ná lórí eré ìdarayá kò lọ lásán - Dapo Abiodun
- Ṣé lóòtọ́ọ́ làwọn ọlọ́ṣà tún gbẹ̀mí èèyàn kan ní Moniya, Ibadan?
Ọgagunfẹyinti Toogun ni amọtẹkun ko si fun ṣiṣọ awọn dukia tabi ileeṣẹ aladani.
Bakan naa lo ni wọn ko lee di ohun elo fun sinsin tabi gba gbese pada fun awsn ileeṣẹ.
O ni laipẹ igbimọ agbohungbaroye kan yoo di gbigbekalẹ fun araalu lati maa fi ariwisi wọn nipa iṣẹ ati iṣe Amọtẹkun ṣọwọ si.
O ni idi niyi ti wọn fi rii pe wọn lẹ orukọ ati nọmba idanimọ ọkọọkan wọn mọ aya aṣọ ti wọn ba wọ.





















