Oba Lamidi Adeyemi: Aláàfin àkọ́kọ́ tí yóò lo ọdún méjìlélàádọ́ta lórí ìtẹ́

Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta

Oríṣun àwòrán, @AlaafinofOyo

Yoruba ni ori ti yoo dade, ko ni ṣe alai dade, ọrun ti yoo si lo ejigbara ilẹkẹ, ko ni ṣalai lo ó, ibadi ti yoo lo mọsaji, aṣọ ọba to jinna koro koro, ko kuku ni ṣe alai lo.

Bẹẹ ni ọrọ Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta rí,ẹni ti ori gbe de ipo awọn baba rẹ leyin ọpọ ifigagbaga laarin awọn ọmọ oye to le ni mẹwa, ti wọn dìjọ du ipo.

Ọjọ nla si ni ọjọ Kẹrinla osu Kinni ọdun 1971 ti atọbatẹlẹ ko to jọba, Lamidi Atanda Olayiwola Adeyemi gori itẹ awọn baba nla rẹ.

Gomina ologun nigba naa to ti di oloogbe, Ajagunfẹyinti Robert Adeyinka Adebayo si lo gbe ọpa asẹ le lọwọ gẹgẹ bii Alaafin Ọyọ.

Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta

Oríṣun àwòrán, Facebook/The Alaafin of Oyo

Ọmọ ọba ni Lamidi Atanda, baba rẹ si ni Alaafin Adeniran Adeyemi, koda, ọmọ ọmọ ọba tun ni pẹlu nitori baba to bi baba rẹ, Alaafin Alowolodu Adeyemi naa jẹ Alaafin.

Amọ sibẹsibẹ, eyi ko ni ki o ma figa gbaga pẹlu awọn ọmọ oye yoku to fẹ jọba nikete ti Alaafin Gbadegesin Ladigbolu keji waja lọdun 1970.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iru ẹda wo ni Alaafin Adeyemi jẹ?

Yoruba ni ajise bi Ọyọ laa ri, Ọyọ kii se bi baba ẹni kọọkan, a si lee ni asamọ yii faramọ ninu ilana igbe aye Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta ba ba wo isesi rẹ lori oye.

Oba Adeyemi ko to jọba jẹ osisẹ adojutofo ati akansẹ to dantọ, to si ni iriri ba se n se akoso eyi to wulo pupọ fun lasiko to di ọba alaye.

Àkọlé fídíò, Jẹ́ ká lọ sílu mi: Kò sí ìtàn Ibadan láìsí Efunsetan, Òkè méje, Bower's Tower àtàwọn ǹkan

Tẹ ba si fẹ mọ siwaju si nipa itan igbe aye Ọba Adeyemi, ẹ ka itan igbe aye rẹ nibi lati mọ bo se lo aye rẹ ko to jọba ati bo se dori oye.

Gẹgẹ ba se mọ pe ipo pataki ni ipo Alaafin ninu itan Yoruba, to si se asaaju ninu odiwọn ipo awọn oriade nilẹ kaarọ Oojire.

Ko si si ọba alaye ti yoo ni bawo ni ti Alaafin se jẹ nitori odu nla ni, kii se aimọ fun oloko, ko si si ẹni ti yoo kọ iyan rẹ, ti ko ni fi ewe boo.

Ta ba si n sọrọ nipa ọla, iyi ati ẹyẹ, a le sapejuwe Alaafin Adeyemi bi ọba alade to n fi ọla wu ni, ẹni to jẹ atọbatẹlẹ, ko to jọba.

Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta

Oríṣun àwòrán, @AlaafinofOyo

Oba Adeyemi bii Alaafin akọkọ ti yoo lo aadọta ọdun lori itẹ:

Ko si yẹ ko ya ẹnikẹni lẹnu pe ọba to lọla, niyi ati ẹyẹ yii lo aadọta ọdun lori oye eyi to mu agbega nla ba agbegbe rẹ.

O si yẹ ko ye wa pe ohun aseyọri gbaa ni ki ọba alade kan lo aadọta ọdun lori oye, bẹẹ si ni ko si ni akọsilẹ pe Alaafin kankan lati ẹyin wa lo aadọta ọdun nipo.

Amọ ka ba le mọ bi ẹyẹ yii se pọ to fun Ọba Adeyemi gẹgẹ bi Alaafin akọkọ ti yoo lo aadọta ọdun nipo, o yẹ ka woju wẹyin wo iye ọdun ti diẹ lara awọn baba nla rẹ to jẹ Alaafin lo, to fẹ ẹ sun mọ adota ọdun.

Oba lamidi Olayiwola Adeyemi ati aya rẹ akọkọ, Olori Abibat Nihinlola nigba ewe wọn

Oríṣun àwòrán, v@AlaafinofOyo

Awọn Alaafin to lo ọdun to pọ diẹ nipo yatọ si Ọba Adeyemi:

Akọsilẹ fi ye wa pe Alaafin to fẹ sunmọ aadọta ọdun lori oye lẹyin Ọba Adeyemi ni Alaafin Siyanbola Ladigbolu to jọba laarin ọdun 1911 si 1944, ẹni to lo ọdun mẹtalelọgbọn nipo.

Bakan naa ni Oba Alowolodu Adeyemi Kinni, tii se baba fun baba Oba Adeyemi naa jọba laarin ọdun 1876 si 1905, to si lo ọdun mọkandinlọgbọn lori oye.

Àkọlé fídíò, Jimi Solanke: Bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ eré òṣùpá láyé àtijọ́ táa mú ìtàn Yorùbá sísọ dé America padà

Oba Atobatele Arugba naa jọba laarin ọdun 1837 si 1859, to si lo ọdun mejilelogun nipo.

Bakan naa ni Alaafin Adeniran Adeyemi keji, tii se baba ọba Lamidi Adeyemi, ẹni to jọba laarin ọdun 1945 si 1955, to si lo ọdun mẹwa pere lori oye, ki wọn to yọ nipo.

O si daju pe aye ti ẹsin Oba Adeniran Adeyemi ko jẹ, ti wọn fi yọwọ rẹ ninu awo, ni iru idi rẹ, tii se ọmọ rẹ n jẹ lori aleefa.

A si le se apejuwe Ọba Lamidi Adeyemi bii oloriire, ti Ọlọrun gba fun, to si ri aanu pupọ gba.

Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta ati meji ninu olori rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/olori_omoh_one

Awọn idagbasoke to ba ilu Oyo ati ipa manigbagbe ti Ọba Adeyemi ko ni Naijiria:

Kii se pe a sọ asọdun ta ba ni idagbasoke alailẹgbẹ ba ilu Ọyọ lati aadọta ọdun ti Lamidi Adeyemi ti wa lori itẹ bii Alaafin Ọyọ.

Awọn ileesẹ nla nla, ileesẹ alabọde atawọn ileesẹ kereje kereje lo ti lalẹ hu nilu Ọyọ lẹyin ti Ọba Adeyemi di Alaafin.

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó

Bakan naa ni eto igbayegbadun buyaari si nilu naa, to jẹ ilu to dakẹ jẹjẹ tẹlẹ ki Alaafin yii to debẹ.

Fun awọn onwoye ohun to n lọ lawujọ, alaafin kii fi ọrọ asa sere, ta si le ni o kogiri mọ ojuse rẹ bi ọba alaye lati ri daju pe awọn asa, ise ati ede wa ko lọ sokun igbagbe.

Ẹni ti itan ko ba si ye, to ba tọ Alaafin lọ, oye yoo ye kedere nipa ohun to ba fẹ mọ, ti ọba alaye naa si jẹ iwuri fun ọpọ ọmọ Yoruba, paapaa lasiko to ba n hu awọn itan manigbagbe jade.

Gomina Kayode Fayemi ati Oba lamidi Adeyemi

Oríṣun àwòrán, @AlaafinofOyo

Yatọ si eyi, ipa kekere kọ ni Adeyemi n ko si idagbasoke orilẹede Naijiria, to si maa n kopa ti kii se keremi si awọn ohun to n lọ lorilẹede yii.

Bẹẹ ba si gbagbe, ọpọ lẹta ni Alaafin maa n kọ si awọn adari to ba wa nipo boya labẹ ijọba apapọ ni abi lawọn ipinlẹ.

O yẹ kẹ ranti lẹta to kọ si aarẹ Muhammadu Buhari lati jẹ ko mọ bi ori se n ta araalu si nipa ọrọ aje to dagun ati eto aabo to mẹhẹ, eyi to lapa rere.

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí

Bakan naa ni Alaafin tun da si ọrọ aawọ ija agba to n waye nipinlẹ Ekiti, to si kọ lẹta si gomina ipinlẹ naa, Kayode Fayemi, lati pe akiyesi rẹ si ọrọ naa ati ọna atunse nipa rẹ.

Tun wẹ, ọpọ awọn gomina oloselu ati ti ologun to ti jẹ nipinlẹ Ọyọ lo mọ ipa ribi ribi ti Alaafin ko lati jẹ ki isejọba wọn se aseyọri.

A si le sọ pe Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi ti sisẹ pọ pẹlu awọn gomina to to mọkanlelogun lati ri si idagbasoke ipinlẹ Ọyọ.

Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta

Oríṣun àwòrán, @AlaafinofOyo

Awọn gomina ti Alaafin Adeyemiri ibẹrẹ ati opin saa wọn nipo:

  • Ajagunfẹyinti Adeyinka Adebayo (August 1966 - April 1971)
  • Ajagunfẹyinti Christopher Oluwole Rotimi (April 1, 1971 - July 1975)
  • Ajagunfẹyinti Akintunde Akinyooye Aduwo (July 1975 - August 1975)
  • Ajagunfẹyinti David Medayese Jemibewon (March 1976 - July 1978)
  • Ajagunfẹyinti Paul Tarfa (July 1978 -October 1979)
Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà
  • Oloye Bola Ige (October 1, 1979 - October 1, 1983)
  • Ọmọwe Victor Omololu Olunloyo (October 1, 1983 - December 31, 1983)
  • Ajagunfẹyinti Oladayo Popoola (January 4, 1984 - September 1985)
  • Ajagunfẹyinti Adetunji Idowu Olurin (September 1985 - July 1988)
  • Ajagunfẹyinti Sasaenia Oresanya (July 27, 1988 - August 1990)
Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'
  • Ajagunfẹyinti Abdulkareem Adisa (September 1990 - January 1992)
  • Oloye Kolapo Olawuyi Ishola (January 2, 1992 - November 17, 1993)
  • Ajagunfẹyinti Adetoye Oyetola Sode (December 9, 1993 - September 14, 1994)
  • Ajagunfẹyinti Chinyere Ike Nwosu (September 14, 1994 - August 22, 1996)
  • Ajagunfẹyinti Ahmed Usman (August 22, 1996 - August 1998)
Àkọlé fídíò, Ṣé o mọ̀ ipò tí ìlú Owo l'Ondo ní lórí ìtẹ́ Ile Ife? Ẹ kálọ sí ìlú mi
  • Ajagunfẹyinti Amen Edore Oyakhire (August 16, 1998 - May 28, 1999)
  • Alhaji Lamidi Onaolapo Adesina (May 29, 1999 - May 28, 2003)
  • Alhaji Rashidi Adewolu Ladoja (May 29, 2003 - May 28, 2007)
  • Otunba Christopher Alao-Akala (May 29, 2007 - May 29, 2011)
  • Sẹnetọ Abiola Ajimobi (May 29, 2011 - May 29, 2019)
  • Onimọ ẹrọ Oluseyi Abiodun Makinde (May 29, 2019 - titi di akoko yii ).
Àkọlé fídíò, Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà

A le sọ pe Ọba Adeyẹmi ri aye wa ni gbogbo ọna nitori gbogbo ohun ti eeyan maa n gbe ile aye se, ni Alaafin ti se ni aseyọri.

O ni ẹmi gigun, o ni alaafin, Ọ́ba Adeyemi tun lowo, o lọla, o ni gbajumọ, bakan naa lo n sọla ni agbala rẹ pẹlu awọn orekelẹwa obinrin, to si tun jẹ alayelugba ti awọn ọba ẹgbẹ rẹ n wari fun.

BBC Yoruba wa n ba Ọba Lamidi Olayiwola Atanda Adeyemi Alowolodu yọ ayọ aadọta ọdun rẹ lori itẹ, ta si n gbadura pe ade yoo pẹ lori, bata yoo pẹ lẹsẹ, ẹsin ọba yoo si jẹ oko pẹ. Asẹ.

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó