Alaafin Oyo: Alaafin Oyo ní àwọn onílù láàfin ló ń tú ọ̀pọ̀ àṣírí fún òhun láàfin

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oyo
Alaafin ilu Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta ti sọ pe, awọn onilu ni afin oun lo maa n ta oun lologbo ti ẹni ibi tabi ọdalẹ ba wọle tọ oun.
Alaafin lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle ede Yoruba kan.
O ni "Gbogbo eeyan lo mọ pe aafin yii jẹ ibi aṣa ati iṣe, ti ẹ ba ri ti awọn onilu ba n lu ilu wọn ninu aafin, oriṣiriṣi nnkan ni ilu naa n tumọ si."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Oyedepo àti ìjọba ń tahùn síra lórí bí ìjọba ṣe ń gba àkóso àwọn ilé ìjọsìn
- EFCC tún gbé Mompha lórí ẹ̀ṣùn lílu jìbìtì lórí ayélujára
- Ọlọ́pàá méjì wọ gàù lóri bí afurasí apanìyàn l‘Akinyele ṣe sá lọ
- Ìrìnna ọkọ́ òfúrufú s'ílẹ̀ òkèèrè bẹ̀rẹ̀ padà ní Nàìjíríà
- Jegede (PDP) ti yan Aṣojúṣòfin Ikengboju gẹ́gẹ́ bí ìgbákejì rẹ̀ tí wọ́n yóò jọ díje dupò
Kabiesi ni, "Fun apẹrẹ, ti eeyan buburu kan tabi ọdalẹ ba bami lalejo ni aafin mi, awọn onilu yoo fi ilu wọn ki mi nilọ, bo tilẹ jẹ pe ẹni naa ko ni mọ oun ti ilu naa n sọ, ṣugbọn o ye mi."
Ọba Adeyemi ni "Gẹgẹ bi olori gbogbo awọn Ọba ilẹ Yoruba, mo maa sa ipa mi lati gbe ede, aṣa ati iṣe Yoruba leke, nitori o dabi pe o ti n di ohun igbagbe."
Kabiesi tẹsiwaju pe "Ti ẹ ba ṣakiyesi, ẹ o ri pe mi o fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ aṣọ wiwọ, bi a ṣe n ki ni ati ede Yoruba."
Ọba alaye naa pari ọrọ rẹ pe o yẹ ki awọn ọmọ ilẹ Yoruba ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ gẹgẹ bi ọmọ iya kan , ki wọn ma si jẹ ki eto oṣelu oin wọn niya.
Lẹyin naa lo ṣeleri pe oun yoo tẹsiwaju lati maa gbe aṣa ati iṣe Yoruba ga, ko ma ba parun.
Àṣé àṣírí ń bẹ láàrín Alaafin àtàwọn onílù láàfin Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oyo
Otitọ ni pe ni ilana ati iṣẹṣe Yoruba, lara awọn ti eniyan ko lee fẹ ku laafin Ọba ni awọn onilu wa.
Wọn wa lara awọn ajirọba.
Awọn ni o maa n da ọba lara ya nigba to ba ku oun nikan ṣoṣo laafin rẹ.
Amọṣa lode Ọyọ, iyẹn laafin Kabiyesi Iku baba, yeye, Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi Kẹta, o fẹ jọ bi ẹni pe adehun kan n bẹ laarin awọn onilu naa ati Iku baba yeye funrarẹ.
Ninu ọrọ ti Baba Alaafin ṣe lalaye fun ileeṣẹ iwe iroyin abẹle kan, aṣiri to wa laarin wọn naa ni pe awọn onilu yii nii maa n ṣe ikilọ fun Alaafin nipa ohun to ba n lọ ni ita afin.
Ninu ifọrọwerọ naa, Kabiyesi Adeyẹmi kẹta
Alaafin Ọyọ ysju rẹ sita pe awọn onilu laafin ni wọn maa n tu aṣiri nipa irufẹ eeyan to n bs wa ri oun laafin fun oun.
O ni bi iru ẹni bẹẹ ba jẹ eeyan buruku, awọn onilu yoo tu aṣiri rẹ fun oun; bi onitọhun ba si tun jẹ eeyan rere, wọn a jẹ ki oun tun mọ pẹlu.
O ni oyun ọrọ n bẹ ninu ilu awọn onilu oun, ilu wọn kii ṣe ilu lasan. ẹni to ba leti ilu nikan lo le gbs ohun ti wọn n sọ.













