Ondo Election 2020: Olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Eyitayo Jegede ti yan Gboluga Ikengboju gẹ́gẹ́ bí ìgbákejì

Jegede ati Gboluga Ikengboju

Oríṣun àwòrán, other

Jegede kéde Gboluga Ikengboju gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀ nínú ètò ìdìbò tó ń bọ́ l'Ondo losu kẹwaa, ọdun yii.

Oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ondo, Eyitayo Jegede ti kede Gboluga Ikengboju gẹgẹ bi igbakeji rẹ ti wọn yoo jọ dije.

Jegede lo kede Ikengboju loju opo Twitter rẹ lọjọ Aje.

O ni "Inu mi dun lati kede Gboluga Ikengboju gẹgẹ bi igbakeji mi ti a o jọ ṣiṣẹ papọ lati tukọ ijọba ipinlẹ Ondo ninu idibo to n bọ lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020."

Ṣaaju ni ajọ to n ri si eto idibo, INEC, ti kọkọ sọ fun awọn ẹgbẹ oṣelu lati fi orukọ awọn oludije wọn ranṣẹ ko ti di ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 tabi ko gbagbe lati kopa ninu eto idibo ọhun.

Àkọlé fídíò, Blind DJ: Etu Omotayo kò ríran àmọ́ ó le to irinṣẹ́ eléré pọ̀ láti kọrin láì sí ìrànwọ́
Donald Trump

Oríṣun àwòrán, EPA

Ẹ wo ìkìlọ̀ tí ìjọba America fi léde lórí ìdìbò gómínà Ondo, Edo

Ẹ wo ìkìlọ̀ tí ìjọba America fi léde lórí ìdìbò gómínà ní Ondo àti Edo

Ijọba orilẹede Amerika ti fi aidunnu rẹ han lori bi awọn oṣiṣẹ eleto aabo ṣe n dasi eto oṣelu ni Naijiria, saaju idibo sipo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ Ondo ati Edo.

Ileeṣẹ to n soju Amerika ni orilẹede Naijiria lo fi ikilọ naa lede ni oju opo ikansiraẹni Twitter wọn.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede naa ni wọn ti sọ aidunnu wọn lori rogbodiyan to bẹ silẹ ni ipinlẹ Edo, eleyii to ti da ipaya silẹ saaju idibo sipo gomina ti yoo waye nibẹ ni osu to n bọ.

"Orilẹede Amerika ko ni dẹkun lati ma a ṣe onwoye bi eto idibo ṣe n lọ lorilẹede Naijiria lọna ati ma a gba wọn ni imọran loore-koorẹ."

" A fẹ eto idibo eleyii ti yoo lọ ni irọwọrọsẹ lorilẹede Naijiria, ti ifẹ awọn eniyan lori ẹni ti wọn fẹ ko ṣoju wọn yoo si leke."

"Inu wa ko dun rara si bi rogbodiyan ṣe n waye ni ipinlẹ Edo saaju ọjọ idibo"

"O si ba ninu jẹ pẹlu ẹsun pe awọn eleto aabo n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn oloṣelu lati da awhala silẹ ni ilu."

Ilẹeṣẹ orilẹede Amerika wa kesi gbogbo awọn oloṣelu ati awọn ti ọrọ kan lati ma ṣe jẹ ki eto idibo sipo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ Ondo ati Edo da rogbodiyan ni ilu.

Wọn fikun pe ajọ eleto idibo, INEC gbọdọ sa ipa wọn lati ri wi pe idibo ti ko ni magomago ninu lo waye ni ipinlẹ Edo ati Ondo.

Bakan naa ni wọn ni awọn yoo tẹsiwaju lati ma a ri orilẹede Naijiria gẹgẹ bi asaaju ni ile adunlawọ ati orilẹede to bọwọ fun ifẹ araalu lọna ati mu itẹsiwaju ati alaafia ba orilẹede Naijiria.

Wo àwọn ìgbẹ́sẹ̀ mẹ́wàá tí o nílò láti wò èsì ìdìbò Edo, Ondo bí wọ́n ṣe ń kàá

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti gbe ara tuntun yọ bayii lori eto idibo ati wiwo esi idibo lorilẹede Naijiria pẹlu ikede agbekalẹ oju opo ayelujara kan eyi to pe ni IreV, ti yoo wa fun ikede esi ibo.

Ikede naa n waye pẹlu bi ajọ naa ati orilẹede Naijiria ṣe n gbaradi fun eto idibo gomina ni ipinlẹ Edo ati Ondo.

Alaga ajọ INEC

Oríṣun àwòrán, Inec

Ajọ naa kede agbekalẹ oju opo ọhun lẹyin ipade ajọ naa to waye l'Ọjọbọ gẹgẹ bi ara ọna lati tubs mu ki okun akoso ibo lorilẹede Naijiria o gbopọn sii ki o ma si ni bojuboju kan ninu rara.

Kii ṣe ọrọ irọ mọ pe ọrọ esi idibo a maa fa ọpọlọpọ edeaiyede lorilẹede Naijiria, ajọ INEC ni idi niyi ti awọn fi ṣagbekalẹ oju opo naa.

Eyi ni igbesẹ ti o nilo lati maa wo esi naa bi o ba ṣe n jade loju opo INEC naa:

Igbesẹ akọkọ: Ẹ lọ soju opo https://inecelectionresults.com

Igbesẹ keji: Tẹ ori akori kan to ni "Creat new Account?"

Igbesẹ kẹta: kọ ohun gbogbo to ba yẹ si inu apoti ọrọ ti igbesẹ keji naa ba gbe sita, lẹyin eyi tẹ akori ibi to kọ "Sign in"

Igbesẹ kẹrin: Kọ orukọ ipinẹ ibinibi rẹ sibẹ ko si tun tẹ ibi ti wọn kọ akori "Continue" si.

Igbesẹ karun un: lẹta kan yoo dun ninu apo iwe atẹranṣẹ ori ayelujara rẹ ti a mọ si Email eleyi to o fi silẹ lawọn apoti to ti yọ sita loke ṣaaju.

Igbesẹ Kẹfa: Lọ yẹ apo iwe atẹranṣẹ ori ayelujara rẹ ti a mọ si Email wo ki o si kọ number to ba firanṣẹ sibẹ ti oo lo lori ayelujara naa.

Igbesẹ keje: Tẹ ori akori "Activate" loju opo naa

Igbesẹ kẹjọ: eleyii ni yoo gbe ọ wọle soju opo ibi ti ẹ o ti yan eyikeyi ibo ti ẹ fẹ yẹ esi ibo to wu yin wo.

Igbesẹ Kẹsan: o lee lo awọn bọtini ayẹwo to wa nibẹ lati fi wa esi idibo ibudo ti o fẹ mọ ni kia masa

werewere.

Igbesẹ kẹwa: Ẹ ma gbagbe lati ti oju opo naa bi ẹ ba ti ṣetan.

Àkọlé fídíò, Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀

Eto atundi idibo si aga aṣofin ipinlẹ lẹkun aringbungbun Nasarawa ti yoo waye ni ipinlẹ Nasarawa ni wọn yoo ti kọkọ lo oju opo yii.