2020 WASSCE: Àjọ WAEC sọ pé ìdánwò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí nàá lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ṣeto idanwo aṣekagba ileewe girama ni ilẹ Afrika, WAEC ti sọ ọjọ ti yoo gbe esi idanwo ti awọn akẹkọọ ṣẹṣẹ pari, jade.
Ọjọ Satide ni awọn akẹkọọ lorilẹ-ede Naijiria, ati awọn mẹrin miran ni iwọ oorun ilẹ Afrika, Ghana, Liberia, Sierra Leone ati Gambia, pari idanwo WAEC ti ọdun 2020.
WAEC ni laarin ọjọ marundinlaadota ni awọn yoo gbe esi idanwo naa sita.
Iye awọn to kọ̀ idanwo naa le ni miliọnu kan (1,459,463) kaakiri orilẹede Naijiria
Adari eto iroyin ni ajọ WAEC, Demianus Ojijeogu, ni laipẹ laijina ni esi idanwo naa yoo jade fun awọn akẹkọọ lati mọ bi wọn se se daradara to ninu idanwo naa.
Ojijeogu ni awọn n ṣiṣẹ karakara lati ri wipe esi idanwo naa jade lasiko ti awọn fi to awọn eniyan leti wi pe yoo jade.
Lakotan, Ajọ WAEC ni idanwo naa lọ ni irọwọ-rọsẹ kaakiri gbogbo ojuko ti idanwo naa ti waye laisi magomago tabi rogbodiyan kankan.
Àṣírí ìdánwò tú síta lóòtọ́ọ́, ọwọ́ tẹ alákòóso ìdánwò nípínlẹ̀ mẹ́ta - WAEC

Oríṣun àwòrán, @hadd1nzarewa
Olori ileesẹ to n seto idanwo asejade nile ẹkọ girama lẹkun iwọ oorun Afirika, WAEC, Ọgbẹni Patrick Areghan ti kede pe ọwọ ajọ ọhun ti tẹ awọn alakoso idanwo kan, to tu asiri idanwo ajọ naa sita.
Areghan sisọ loju ọrọ yii lasiko to se abẹwo sawọn ileẹkọ kan ladugbo Yaba nibi ti idanwo WAEC ti n lọ lọwọ, to si rọ awọn akẹkọ ibẹ lati ta kete si sise makaruru lasiko idanwo.
Olori ajọ WAEC ni ko bojumu rara ki awọn akẹkọọ maa wa orijo kiri lasiko idanwo, ohun itiju gbaa ni, idi si ree ti oun fi bọ sita lati tọpinpin bi idanwo naa se n lọ si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Ọba Seriki Abass ti Badagry, tó ní aya 128, ọmọ 144
- Kò sí ọ̀nà láti jáde tàbí wọlé sí Mali, ikọ̀ ológun ọlọ́tẹ̀ kéde ìṣéde
- Wo ibùdó arẹwà tí ọ̀pọ̀ èrò ń ya lọ ní Abuja
- Obìnrin kan dèrò ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó fi ọ̀bẹ rẹ́ ọmọ rẹ̀ lọ́rùn
- Adamu Adamu, Minista ètò ẹ̀kọ́ ti fi òfin àátẹ̀lẹ́ síta kí àwọn ilé ìwé lè wọlé
- Makinde ti sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí asekúpani Akinyele sálo mọ́ àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ ní àhámọ́
- Olólùfẹ́ mi ṣèèsì fi ọkọ́ gbá mi sí gọ́tà, mo rò pé ọlọ́jọ́ dé ni - Iya Osogbo
"Ohun to ba ni ninujẹ ni bi awọn alakoso idanwo WAEC to n gba iwe idanwo lọwọ wa, se n lọ si awọn idanwo naa lẹyin ni oju ọlọmọ ko to.
Lọjọru, ọwọ tẹ ọkan lara awọn alakoso idanwo ọdalẹ ọhun nipinlẹ Nassarawa, wọn ko mọ pe awa gan ni ọna ta fi kẹẹfin wọn.

Oríṣun àwòrán, AFP
Bakan naa nipinlẹ Bauchi, ọwọ wa tun tẹ ẹlomiran ninu awọn alakoso idanwo yii, taa ni ki wọn kin wa lẹyin, amọ ti wọn n fi ẹgun sọwọ.
Ko tan sibẹ, nipinlẹ Rivers naa, oludije kan tun san iru asọ yii soro, ọwọ wa tun tẹẹ."
Akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ìdánwò àṣekágbá WAEC ní ibùdó ìtọ́jú aláàrún COVID-19 ní Gombe
Ọrọ di iran awo dami ẹnu loni ni ipinlẹ Gombe nigba ti akẹkọṣedanwo kan to ni arun coronavirus joko ṣe idanwo pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ni ipinlẹ Gombe.
Amọṣa ni ibudo itọju awọn alaarun naa lo ti ṣe idanwo ọhun.

Oríṣun àwòrán, twitter/ Gombe PHEOC
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Gombe fi sita loju opo twitter rẹ, akẹkọo naa ti wọn ko darukọ rẹ joko ṣe idanwo iṣiro ti alamojuto rẹ si duro ninu aṣọ idaabobo lọwọ arun naa.
Akẹkọ naa ni a gbọ wi pe o jẹ akẹkọ ileewe girama GSSS Gombe.
Ki lo ti kókó sele seyin?
Oríṣi ẹbu ìwé ìdánwò ìṣìrò mẹ́ta ló dọ́wọ́ wa, àmọ́ wọn fi ń lu jìbìtì ni - WAEC
Ayederu ni iwe idanwo iṣiro WAEC, Mathematics to lu ori ayelujara pa ṣaaju akoko idanwo ọhun lọjọ Aje ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹjọ ọdun yii.

Agbẹnusọ fun ajọ WAEC, Demianus Ojijeogu lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC.
Ọgbẹni Ojijeogu ṣalaye pe, awọn eeyan lo fẹ fi iwe idanwo naa lu awọn akẹkọọ ni jibiti.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọlọ́pàá dóòlà ọkùnrin kan tí wọn so mọ́lẹ̀ fún ọdún mẹ́ẹ̀dógún
- "Àwa Emèrè Onítẹ̀síwájú la ṣèpàdé nílé Elebuibon, kìí ṣe Oṣó àti Àjẹ́"
- Nǹkan wọ̀lú! Afurasí ikú ọ̀wọọ̀wọ́ l'Akinyele jápa mọ́ ọlọ́pàá lọ́wọ́
- Wo ọmọ Nàíjíríà tí wọn fi pósí ‘₦34m’ sin
- Yéèpà, òfin ìtakété síra ẹni forí ṣánpọ́n lásìkò ọdún Osun Osogbo
- Ẹ fura, iyọ̀ onímájèlé tó dóde ti gbẹ̀mí èèyàn méje!
- Ìtàn ayé Alájọ Ṣómólú rèé, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́?
''Oriṣii mẹta irufẹ iwe idanwo naa ni mo ri fun ra mi, irọ lasan ni gbogbo rẹ,'' Ojijeogu lo sọ bẹẹ.
Agbẹnusọ fun ajọ WAEC ni akẹkọọ to ba tẹ le awọn iwe idanwo yii yoo fidi rẹmi ninu idanwo ọhun.

Oríṣun àwòrán, @hadd1nzarewa
O ni ohun ti awọn eeyan to n gbe iwe idanwo naa kiri fẹ se ni lati gba owo lọwọ awọn obi, ti ọmọ wọn wa lara awọn akẹkọọ to fẹ ṣe idanwo naa.
Ṣé ojúlówó ìwé ìdánwò ìṣìro WAEC tí yóò wáyé lónìí ló lu ayélujára pa bí?
Ọjọ pe, ọjọ si ti ko, ti eto idanwo asejade nile ẹkọ girama, WAEC, yoo bẹrẹ, gẹgẹ bi wọn se kede rẹ.
Sugbọn lọwọlọwọ bayii, oju opo ayelujara ti kun nipa awọn iwe idanwo Waec, paapaa Isiro, tawọn eeyan kan n pin kiri.
Gẹgẹ bo se n gbona lọwọ loju opo Twitter, awọn eeyan kan ti n pin iwe idanwo WAEC to wa fun isiro kiri, ti wọn tẹ ọdun 2020 sinu rẹ.
Ibeere ti ọpọ eeyan si n beere ni pe se ojulowo iwe idanwo isiro WAEC ree abi ayederu, nibayii ti awọn akẹkọọ yoo joko se idanwo Isiro naa lonii ọjọ Aje.

Oríṣun àwòrán, @hadd1nzarewa
Bakan naa ni awọn eeyan kan n bu ẹnu atẹ lu iru igbesẹ bayii, ti wọn si fẹ mọ idi ti aabo to peye ko se wa fun awọn iwe idanwo to se koko bayii.
Ẹkunrẹrẹ iwadii nipa iroyin naa laa mu wa fun yin laipẹ.

Oríṣun àwòrán, @waecngr
Wayi o, bi awọn akẹkọọ oniwe mẹwa si se n gbaradi lati joko se idanwo naa, ni ọkan awọn obi ati olukọ n poruru lori bi idanwo naa yoo se lọ.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn ijọba ipinlẹ ti kede pe eto ti to ni sẹpẹ nipa idena arun Coronavirus lawọn ibudo ti idanwo yoo ti waye, sibẹ ọkan awsn eeyan kan ko balẹ.
Sugbọn bi idanwo naa ba se n lọ ni BBC Yoruba yoo maa mu iroyin nipa rẹ wa fun yin.
Waec f'ofin de ile'we mẹtadinlaadọta
Ajọ t'o n risi idanwo lapa iwọ-oorun Afrika (Waec) ti fi ofin de ile ẹkọ Girama mẹtadinlaadọta ni ipinlẹ Kogi, ti wọn f'ẹsun sise agbatẹru magomago lasiko idanwo ajọ naa kan.
Kọmisọna f'ọrọ eto ẹkọ ni'pinlẹ Kogi, Rosemary Osikoya ti o fi ọrọ naa lede nigba ti wọn n se ipade awọn oniroyin n'ilu Lokoja lọjọ iṣẹgun, sọ wi pe ajọ WAEC fi lẹta naa ranṣẹ si ile-iṣẹ ijọba ipinlẹ naa.
Osikoya wipe awọn ile-iwe Girama ti ijọba ati ti aladani wa ninu awọn ile-iwe ti wọn f'ofin de naa kaariri ipinlẹ Kogi.
Ninu ọrọ rẹ, o wipe mẹtala ninu awọn ile iwe Girama naa ni aṣemaṣe wọpọ si, ti o si fikun un wipe ijọba ipinlẹ naa yoo fikun ijiya awọn ile ẹkọ bẹẹ.
Kọmisọna fun eto ẹkọ wipe, awọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu Ajọ awọn Olukọ Lapapọ (National Teachers Institute) lati bawọn kọ ọgọrun olukọ, pẹlu ireti wipe eleyi yoo mu ilọsiwaju ba eto ẹkọ ni ipinlẹ naa.
















