Grace Oyin Adejobi: Ẹ̀yin òṣèré tíátà lóbìnrin tẹ́ ǹ bọ́ra sí ìhòhò, ẹ sá fún ìtànjẹ́ ayé

Iya Osogbo

Oríṣun àwòrán, Grace Oyin Adejobi

Gbajugbaja osere tiata lede Yoruba, Grace Owoola Oyin Adejobi ti sọ pe ibi tohun ba iṣẹ ere itage de bayii, ohun ko lero wi pe ohun yoo le ṣe ere mọ.

Arabinrin ẹni aadọrun ọdun naa ṣalaye pe, kii ṣe nitori nkankan bi kii ṣe pe agba ti de.

Ninu ifọrọwerọ Iya Oṣogbo lori eto ori redio kan, iyawo agba-ọjẹ oṣere Oyin Adejobi ni, nnkan bii ọdun mẹtadinlaadọta loun bẹrẹ ere ori itage.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Arabinrin Adejobi wa bẹnu atẹ lu bi awọn oṣere tiata kan paapa awọn obinrin, ti ṣe maa n mura ihoho.

Àkọlé fídíò, Nigeria movie industry: Àgbà òṣèré, Lere Paimo ní àìgbọràn ló ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn

O ni ki wọn maṣe jẹ ki yoroyoro aye tan wọn jẹ, ki wọn si gbagbọ pe ogo Ọlọrun nikan lo le gbe wọn de ipo ọla.

Lara alaye ti Iya Oṣogbo ṣe lori eto naa tun ni ere sinima ti akọle rẹ jẹ Eran Iya Oṣogbo, eyi to fi gba orukọ.

''Mo ti fi orukọ mi lelẹ ṣaaju ki ere Eran Iya Oṣogbo to jade. Kii ṣe ootọ pe ere yii lo gbe ogo mi jade''

Àkọlé fídíò, Gbajúgbajà òsèré tó tún mọ́ ọbẹ̀ sè

Nipa ọjọ manigbagbe nigbesi aye osere yii, Iya Oṣogbo ni ọjọ ti ololufẹ ere awọn kan fẹ ẹ fi ọkọ gba awọn da si gọta nilu Ibadan ni nitori inu rẹ to dun julọ.

''Mi o le gbagbe ọjọ yii nitori pe mo ro pe ọlọjọ lo de ni. Ẹni naa to fẹ ki mi, ki o to ṣeṣi fi ọkọ gba mi wa pada fun mi ẹgbẹrun mẹwa naira to fisi apo iwe''

Iya Osogbo

Oríṣun àwòrán, Grace oyin Adejobi

Lọdun 1953 ni Iya Oṣogbo ni oun bẹrẹ si ni ṣere. Nigba naa lọhun o ni oun a ma ṣere alarinjo kaakiri Naijiria paapa julọ, ni ilu Jebba ni ipinlẹ Kwara.