Mali Coup: Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ èèyàn tú jáde ní Bamako láti yọ̀ pé wọ́n rẹ́yìn ààrẹ àná

Awọn eeyan to n fo fayọ ni Mali

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọmọ orilẹede Mali lo tu sita lọjọ Ẹti, ni olu ilu ilẹ naa, Bamako, lati se ajọyọ iditẹ gbajọba tawọn ologun se.

Iditẹ gbajọba naa si lo yẹ aga akoso mọ aarẹ ana, Boubacar Keita ati olootu ijọba rẹ nidi lọjọ Isẹgun.

Gbagede Independence Square ni ọpọ ọmọ orilẹede naa peju si, ti wọn n fo fẹrẹ fun ayọ, ti inu wọn si n dun pe awọn bori aarẹ Keita.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkan lara awọn eeyan naa, tii tun se olufẹ ẹgbẹ oselu alatako lorilẹede naa, Mariam Cisse to ba BBC sọrọ ni "Inu mi dun ladunju, a bori. A wa sibi yii lati dupẹ lọwọ awọn eeyan Mali ni nitori isẹgun araalu ni eyi jẹ."

Awọn eeyan to n fo fayọ ni Mali

Oríṣun àwòrán, Getty Images

"IBK ti kuna." Ajagunfẹyinti kan, Ousmane Diallo lo sọ bẹẹ, to si lo agekuru aarẹ ana naa pẹlu afikun pe "Awọn araalu ti ja ajasẹgun."

Iditẹ gbajọba naa si lo yẹ aga akoso mọ aarẹ ana, Boubacar Keita ati olootu ijọba rẹ nidi lọjọ Isẹgun.

Awọn eeyan ati ọmọ ologun to n fo fayọ ni Mali

Amọ sa, o wa sekilọ fun awọn ọmọ ologun to gba ijọba pe ki wọn mase lero pe awọn yoo pẹ lori aga akoso rara.

Kò sí ọ̀nà láti jáde tàbí wọlé sí Mali, ikọ̀ ológun ọlọ́tẹ̀ kéde ìṣéde

Ikọ ologun aditẹgbajọba

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ologun to ditẹ gbajọba ni orilẹede Mali ti kede lọjọru pe oun ti gbe igbimọ kan kalẹ, CNSP, ti yoo seto idibo mii lẹyin ti aarẹ Boubacar Keita kọwe fi ipo silẹ.

Agbẹnusọ fun ikọ ologun aditẹgbajọba naa, gagun Ismael Wague lo sisọ loju ọrọ yii lori tẹlifisan orilẹede naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"A ko fẹ fi dandan wa nipo agbara amọ ifẹsẹmulẹ orilẹede wa lo jẹ wa logun, eyi ti yoo fun wa laaye lati seto idibo gbogbo gboo laarin akoko perete, eyi ti yoo ro orilẹede Mali lagbara lati se akoso aye wa."

Laurent Gbagbo

Oríṣun àwòrán, others

Wague fikun pe, "ki orilẹede Mali maa baa ri si agbami okun aye, ni awa ta jẹ olufẹ ilu se ko ara wa jọ lati gba akoso lọna ati ri daju pe awọn ohun eelo ilu n sisẹ bo se yẹ."

Bakan naa lo tun kede ọpọ ipinnu ti ikọ naa ti se bii gbigbe ilẹkun abawọle silẹ Mali lati ori ilẹ ati oju ofurufu ti pa titi di ọjọ miran, ọjọ re.

Bakan naa lo tun ni isede ti bẹrẹ lati aago mẹsan alẹ si Marun owurọ, to si n rọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajafẹtọ ilu ati ti oloselu lati fi ọwọ sowọpọ pẹlu ikọ aditẹgbajọba naa, ki wọn lee seto idibo to pegede, ti yoo gbe ijọba silẹ fun alagbada.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Isẹgun ni ikọ ologun ditẹ gba ijọba lorilẹede Mali, to si mu aarẹ ati olootu ijọba si ahamọ.

Amọ aarẹ Boubacar Keita ti wa kọwe fipo rẹ silẹ, to si tun tu ile asofin ati ijọba rẹ ka, amọ ọpọ orilẹede lagbaye lo ti koro oju si isẹlẹ naa.Ijọba ologun lorilẹede Mali gbe igbimọ ti yoo gbe igbimọ ti yoo seto idibo alagbada silẹ

Wo àwọn ààrẹ márùn-ún tí ológun gba ìjọba lọ́wọ́ wọn l‘Afirika:

Ni ọjọ Iṣẹgun ni aarẹ orilẹede Mali, Boubacar Keita kọwe fi ipo silẹ lẹyin ti awọn ọmọogun dide tako iṣejọba rẹ lẹyin ọpọlọpọ ọjọ iwọde ati ipayinkeke ni orilẹede naa.

Amọṣa, Keita kọ ni akọkọ aarẹ tabi olori ijọba nilẹ Afirika.

Eyi ni marun ninu awọn aarẹ ti wọn ti fi tipatikuuku mu kọwe fipo silẹ ni ilẹ Afirika.

Yahya Jammeh ti Senegal

Yahya Jammeh
  • Yahya Jammeh wọle gẹgẹ bi olori ijọba ologun ni ọdun 1994 ki o to sọ ara rẹ di olori ijọba alagbada ati aarẹ orilẹede Gambia ni ọdun 1996.
  • Wọn tu u yan spo gẹgẹ bi aarẹ ni ọdun 2001, 2006, 2011 ki o to padanu idibo aarẹ fun Adama Barrow lọdun 2016.
  • Lasiko to wa ni ijọba, oniruuru iwa ijẹgaba le awọn oniroyin ti ko ba fọnrere ijọba atawọn ẹgbẹ oṣelu alatako lo waye.
  • Ni ọdun 2013, Jammeh yọ ọwọ orilẹede Gambia kuro lowo ajọ Commonwealth.

Robert Mugabe ti Zimbabwe

Robert Mugabe

Oríṣun àwòrán, others

  • Nitori ọrọ to sọ tako ijsba, wọn ran Mugabe lọ si ẹwọn laarin ọdun 1964 si 1974.
  • Oniruuru edeaiyede lo wọ tọ Mugabe lẹyin fun nnkan bi ogoji ọdun to fi lo ipo lagbo oṣelu lorilẹede Zimbabwe ti ọpọ si n fi oju wo o gẹgẹ bii akinkanju to gba orilẹede naa la lọwọ awọn amunisin Gẹẹsi
  • ọpọlọpọ awọn alatako lo n na ika aleebu sii gẹgẹ bi ẹni to tẹ oju ẹtọ ọpọlọpọ mọlẹ to si tun hiu ọpọlọpọ iwa ibajẹ gbogbo

Laurent Gbagbo orilẹede Ivory Coast

Laurent Gbagbo

Oríṣun àwòrán, others

  • Ọpọ lo fi oju aṣiwaju to ṣetan ati tu orilẹede rẹ ka nitori aifẹ gba fun esi ijakulẹ rẹ nibi idibo.
  • Lẹyin ogun ọdun to fi wa nipo alatako, Gbagbo bọ si ipo ijsba ni ọdun 2000
  • Ni oṣu kẹrin ọdun 2011 ni wọn fi tipatipa lee kuro nipo. Wọn muu ninu yara agbara to pams si ki wọn to ran an ls si ile ẹjọ agbaye to n gbọ ẹjọ iwa ibajẹ ẹda, ICC

Abdelaziz Bouteflika of Algeria

Abdelaziz Bouteflika
  • O joko si ipo aarẹ orilẹede Algeria fun ogun ọdun laarin ọdun 1999 si 2009.
  • Ohun ni aarẹ to dẹkun ogun abẹle to waye lorilẹede naa lọdun 2002.
  • Ki o to di aarẹ, minisita fun ọrọ ilẹ pokeere ni ipo to di mu laarin ọdun 1963 si 1979.
  • Ni ọjọ keji oṣu kẹrin ọdun 2019 ni Bouteflika kọwe fi ipo silẹ lẹyin iwọde ọpọ ero fun ọpọlọpọ oṣu.
  • Ohun ti olori ijọba to pẹ julọ lorilẹede Algeria.

Bí ìrìnàjó ààrẹ ọlọ́dún méje nílẹ̀ Mali, Keita, ṣe lọ rèé

Boubacar Keita

Oríṣun àwòrán, Others

Brahim Boubacar Keita ti gbogbo eniyan mọ si IBK ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kini ọdun 1945.

Ilu Koutiala nilu abinibi rẹ, to si lọ ile iwe ni Lycee Janson-de-sally ni Pari at Bamako.

O tun lọ fasiti Dakar ati ti Parus, nibi to ti gboye nipa imọ ẹkọ International Relation, bẹẹ lo tun kẹkọọ gboye keji ninu imọ History.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Keita ni iyawo, Aminata Maiga, wọn si bi ọmọ mẹrin.

Ẹwẹ, ni ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2020, Keita ati olootu ijoba Mali Boubou Cisse, ni awọn ọmọ ogun gbe lasiko ti wọn ditẹ gba ijọba.

Ni ọjọ kọkandinlogun ni Keita pe awọn ọmọ igbimọ ijọba rẹ lati tun igbimọ ka nitori pe o ni oun ko nilo itajẹ silẹ, ki oun to gbe ijoba silẹ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Keita jẹ oloṣelu lorilẹ-ede Mali, to si jẹ aarẹ lati ọdun 2013 si 2020 lẹyin ti wọn ni ko kọwe fipo silẹ bi tulaasi nitori iditẹ gba ijọba.

Keita ti kọkọ se asoju ijọba Mali lati ọdun 1994 si ọdun 2000, to si tun jẹ Adari ile igbimọ asofin agba orílẹ̀-ede Mali laarin ọdun 2002 si 2007, oun ni oludasilẹ ẹgbẹ oṣelu Centre-Left Party Rally (RPM) ni Mali lọdun 2001.

Ààrẹ orílẹ̀èdè Mali, Boubacar Keita kọ̀wé fipò sílẹ̀

AaKeita

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ orilẹede Mali, Ibrahim Boubacar Keita ti kọwe fi ipo silẹ, lẹyin tawọn ologun mu un lọjọ Iṣẹgun.

Nigba to n sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan, Aarẹ Keita tun kede pe, oun ti tu ijọba oun ati ile igbimọ aṣofin ka.

''Mi o fẹ itajẹsilẹ awọn alaiṣẹ nitori ki n le wa nipo agbara,'' Aarẹ Keita lo sọ bẹẹ.

Aarẹ Mali sọ pe, oun ko lagbara kan mọ lẹyin tawọn kan ni ileeṣẹ ologun pinnu lati yẹ aga mọ oun nidi.

O ni oun ko korira ẹnikẹni ni Mali nitori ifẹ ti oun ni si orilẹede Mali ko ni jẹ ki oun ṣe bẹẹ.

Awọn ologun ni igboro

Oríṣun àwòrán, AFP

Keita gbadura pe ki Eleduwa ko fi iṣọ rẹ ṣọ gbogbo awọn ọmọ orilẹede Mali.

Aarẹ Keita wọle saa keji lọdun 2018 ṣugbọn ọpọ lo ti kọminu lori bi iwa ibajẹ ṣe n gogo sii ati bi ijọba ṣe n ṣakoso ọrọ aje Mali lọna aitọ.

Bakan naa, ọpọ lo ti n bu ẹnu ẹtẹ lu ijọba Aarẹ Keita lori bi ija ẹlẹyamẹya ṣe n pọ sii.

Àwọn ológun ti mú ààrẹ orílẹ̀èdè Mali, Boubacar Keita

Awọn ologun ti mu aarẹ orilẹede Mali ni ọjọ Iṣẹgun lẹyin wakati diẹ ti wọn bẹrẹ iditẹ mọ ijọba ni ibudo ologun Kati Camp.

Aarẹ Ibrahim Boubacar Keita wa ni ile rẹ ni agbegbe Sebenikoro, Bamko nigba ti awọn ologun kan de lati wa mu u ni nnkan bi agogo mẹrin irọlẹ.

Agbẹnusọ fun ijọba orilẹede Malli, Yaya Sangaré ṣalaye fun BBC pe aarẹ Keita, olotu ijọba orilẹede naa, Boubou Cissé, ọmọ rẹ, ati igbakeji rẹ ni wọn mu.

Boubacar Keita

Oríṣun àwòrán, Others

O ti to bii oṣu diẹ sẹyin bayii ti orilẹede naa ti n gbona jọinjọin nitori ọrọ oṣelu nibẹ ti ọpọlọpọ si n ṣe iwọde lori pe ki aarẹ naa fi ipo silẹ nitori ọkan o jọkan ikọlu awọn agbesunmọmi ẹsin ati iwa ijẹkujẹ to n waye.

Ohun to bẹrẹ gẹgẹ bi iwọde awọn ọmọogun lowurọ oni ṣe kẹrẹkẹrẹ di iditẹgbajọba.

Wo ohun tí ìrìnàjò ààrẹ Buhari fún ìgbà àkọ́kọ́ lásìkò Coronavirus lọ sí Mali yóò bá bọ̀

Buhari

Oríṣun àwòrán, Buharisallau1

Niṣe ni aarẹ Buhari de Mali to wọ ibomu fun igba akọkọ nita gbangba ni olu ilu orilẹedeMali lọsan ọjọbọ ni irinajọ ọlọjọ kan to lọ fun ijiroro.

Ibẹwo aarẹ Buhari yii da lorii ifọrọwerọ pẹlu aarẹ ana ti orilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan to jẹ ọkan lara awọn abanijiroro fun ajọ ECOWAS to lọ si orilẹede Mali lati lọ yanju ọrọ.

Aarẹ ana, Jonathan lo ṣẹṣẹ gba iṣẹ akanṣe ti ajọ ECOWAS, ohun ati aarẹ orilẹede Niger Republic, Mahamadou Issoufou ti pohun pọ lati pade ni Mali fun ijiroro lati yanju aawọ to wa laarin aarẹ orilẹede Mali, Boubacar Keita ati alatako rẹ.

O yẹ ki aarẹ orilẹede Ghana, Nana Akufo Addo ati ti orilẹede Côte d'Ivoire naa, Alassane Ouattara wa nibi ijiroro naa.

Bawo ni irinajo aarẹ Buhari si ilẹ okere fun igba akọkọ lasiko COVID-19 yoo ṣe ri?

Garba Shehu to jẹ oluranlọwọ pataki fun aarẹ Buhari sọ fun BBC pe awọn adari orilẹede lajọ ECOWAS fẹ lọ ni ọrọ pẹlu iha ti Mali ninu aawọ naa lẹyin ti ikọ ti aarẹ ana, Goodluck Jonathan ran lọ ko ri ojutuu si aawọ naa.

O ni wiwa nibẹẹ awọn adari yii lee ṣeranwọ lati yanju ọrọ to wa nilẹ - "boya ipo wọn gẹgẹ bii adari nilẹ Afirika lee mu ki wọn gbọrọ si wọn lẹnu ki alafia si jọba ni Mali.

Buhari

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Ki laa ri ti aarẹ Buhari wọ ibomu fun igba akọkọ nita gbangba?

Eyi ni igba akọkọ ti aarẹ Buhari yoo rinrinajo kuro lorilẹede Naijiria lati igba ti ajakalẹ arun Coronavirus ti bẹ silẹ.

Latẹyin wa ni awọn ọmọ Naijiria ti maa n rojọ lori bi aarẹ ṣe maa n rinrinajo kaakiri.

Lọjọ aje, aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Goodluck Jonathan ṣe abẹwo si aarẹ Buhari ni ile rẹ ni Abuja nibi ti wọn ti ṣe ipade idakọnkọ. Loju opo Twitter Buhari lo ti hande pe Jonathan ṣebẹwo si Aso Rock lati jabọ lorii ọrọ gbọnmi si i omi o to ninu oṣelu ati igbesẹ ipẹtu saawọ eyi ti ajọ ECOWAS n gbe lọ si orilẹede Mali.

Aarẹ Buhari sọ pe "mo ti gba abọ lori ọrọ aawọ inu oṣelu to n ṣẹlẹ ni Mali a o si bere lọwọ aarẹ orilẹede Niger pe ko fun wa ni ẹkunrẹrẹ alayee iṣejọba rẹ".

Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....