Mompha: Dúkìá rẹ̀ ní Mompha lọ gbà lọ́dọ̀ EFCC, ló bá kó sí àhámọ́

Mompha

Oríṣun àwòrán, Instagram/mompha

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati iṣowo ilu kumọkumọ, EFCC tun ti gbe Ismaila Mustapha ti inagijẹ rẹ njẹ Mompha pada.

Mompha to jẹ ilumọọka lori ayelujara, to si n jẹjọ lori ẹsun ikowo tuulu lọ si oke okun.

Ohun ti a gbọ ni pe, EFCC mu Mompha pada lọjọ Ẹti to kọja nigba to lọ si ọfiisi ajọ naa to wa ni Ikoyi niluu Eko lati gba aago ọwọ rẹ marun un, ẹrọ ibanisọrọ rẹ, iPhone 8 ati awo rẹ kan, ti ajọ naa gba lọwọ rẹ.

Lẹyin atotonu agbẹjọro rẹ, Gboyega Oyewole (SAN), adajọ Mohammed Liman ti paṣẹ tẹlẹ lọjọ kẹrinlelogun oṣu keje wi pe, ki EFCC jọwọ awọn nkan rẹ fun un.

Adajọ ni awọn nnkan ini rẹ ajọ EFCC gba ko ni ohun kankan ṣe pẹlu ẹsun ikowo tuulu lọ si oke okun ti wọn kan an.

Ṣugbọn kete ti Mompha ti gba awọn nnkan yii tan to si ọfiisi EFCC silẹ ni wọn tun gba a mu.

Olowo ori instagram

Oríṣun àwòrán, @omotimehinnelso

Amọ agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Oyewole sọ pe oun yoo sọ fun ileẹjọ lati paṣẹ pe ki EFCC fi silẹ.

Ẹwẹ, agbẹnusọ fun ajọ EFCC ṣalaye pe, ẹsun nii ṣe pẹlu jibiti ori ayelujara lo jẹ ki ajọ naa tun mu Mompha yatọ si ẹsun to wa niwaju ileẹjọ tẹlẹ.

Ojú alábaṣiṣẹ́pọ̀ Mompha rèé, EFCC ṣí i síta

Arakunrin afurasi to jẹ igbakeji Ismaila Mustapha ti inagijẹ rẹ njẹ Mompha, Kolade Phillip ṣaadede fara han nile ẹjọ lọjọ aje kan naa ti Mompha lọ fara han.

Toun ti gbajugbaja oyinbo mii, Hamza Koudeih ti ọwọ tẹ lagbegbe Banana Island lEko.

Hamza Koudeih ati Kolade Phillip

Oríṣun àwòrán, @efcc

Ṣugbọn wọn ko ri bi brẹ ìjẹ́jọ́ ti awọn mejeji yii bii ti Mompha ti wọn fi ẹsun ọtọ kan to si ni oun ko jẹbi ẹsun iye owo to to biliọnu mẹtalelọgbọn ti wọ́n fi kan an atipe o ni ile iṣẹ to n ṣe pasiparọ owo ilẹ okere kan lai gbaṣẹ lọwọ banki to ga ju lọ ni Naijiria. Lori eyi, Mompha to wa latimọle bayii.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Ẹwẹ, adajọ Muslim S. Hassan ti ile ẹjọ giga kan nipinlẹ Eko sun igbẹjọ awọn alabaṣiṣẹpọ Mompha yii siwaju di jọ kejidinlgbọn oṣu kẹrinla ọdun 2019.

Lọjọ aje ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC ti gbe gbajugbaja olowo ori Instagram ọhun, Ismaila Mustapha ti wọn n pe ni Mompha lọ ile ẹjọ lonii.

Ṣaaju igbẹjọ yii, wọn fẹsun kan Mompha ti o ma n gbe igbe aye olowo pẹlu bii o se ma n fi aworan owo ilẹ okeere si ori ikanni Instagram rẹ, ati adura ni ọpọ igba.

Mompha

Oríṣun àwòrán, @efcc

Àkọlé fídíò, Ọmọ Yahoo tú àṣírí ara rẹ̀ fún, bí wọ́n ṣe ń ṣe é BBC Yorùbá

Ẹwẹ, lonii ọjọ aje, ajọ EFCC wọ ọ lọ si ile ẹjọ giga to wa ni Ikoyi, ilu Eko. Ẹsun mẹrinla ọtọọtọ ni wọn fi kan Mompha eyi to da lori jibiti lori ayelujara.

EFCC ni isẹ pipaarọ owo Naijiria si tilẹ okeere ni Mompha fi n boju lati fi se isẹ gbajuẹ ati 419 ti wọn fi kan an.