#EndViolenceAgainstWomen: Àwọn àmì mẹ́fà tó ń sàfihàn ọkùnrin tó ń hùwà ipá!

#EndViolenceAgainstWomen

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, Osù Kọkànlá, ọdọọdún ní Àjọ Isòkan Àgbáyá,UN láti lẹ̀ kéde òpin sí ìwà ipá sí obìnrin.

Agbẹjọrọ ati olukọ ni Ile Iwe Giga Leads University, Arabinrin Abiade ti parọwa si awọn obinrin lati mọ wi pe ẹni iyi ni wọn nitori naa ki wọn ma fi aye gba iwa ipa.

Agbẹjọro Abiade parọwa naa lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni Ọjọ Ayajọ ifopinsi ifiyajẹ obinrin ni agbaye.

#EndViolenceAgainstWomen

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arabinrin naa se akawe awọn ami ti o ma n safihan wi pe o seese ki okunrin naa ko wuwa ipa si obinrin ti o ba fẹ ẹ si ile.

#EndViolenceAgainstWomen

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn àmì mẹ́fà tó ń sàfihàn ìwà ipá lára ọkùnrin

  • Sọra fun ọkunrin ti o ba soro fun lati jẹ ki ọrẹbinrin rẹ da nkankan se
  • Sọra fun ọkunrin ti ko ba ti ni ero rere nipa obinrin, tabi ti ko mọ apọnle obinrin
  • Sọra fun ọkunrin to ba fẹran lati ma a pasẹ, amọ ti ko fẹ ki obinrin ni ero tirẹ.
  • Sọra fun awọn ọkunrin ti inu wọn kii dun si isẹrere obinrin rẹ.
  • Sọra fun ọmọkunrin to ba wa lati ile ti wọn ti ri iwa ipa gẹgẹ bi igbesi aye to dara.
  • Ọkunrin to ba n tẹnbẹlu iwa ipa si obinrin, okunrin naa a wu iwa ipa si obinrin niyẹn.
Àkọlé fídíò, 'Buns ni ọmọ mi jẹ tán ní ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá di àwátì'
#EndViolenceAgainstWomen

Oríṣun àwòrán, UN WOMEN

Bakan naa ni ẹka to n risi oro obinrin ni Ajo Isọkan Agbaye, UN ti kede wi pe ọjọ mẹrinlelogun ni awọn yoo fi jijagbara fun eto awọn obinrin lagbaye, ati ifopin si iwa ipa si obinrin kaakiri orilẹede to wa ni agbaye.