Sunday Shodipe: Ilé ẹjọ́ fi Sunday Shodipe, afurasí ìṣekúpani l'Akinyele pamọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n

Awọn afunrasi mejeeji

Oríṣun àwòrán, oyo nsight.com

Àwọn aládugbò ṣàlàyé bí Sunday Shodipe ṣe pa Funmilayo tó pa kẹ́yìn l' Akinyele.

Leyin ti ọwọ tẹ Shodipẹ, fun ẹsun ipaniyan ni ṣisẹntẹle ni agbegbe Akinyẹle ni ilu Ibadan, okiki kan nigba ti awọn agbofinro kede pe o tun ti salọ mọ wọn lọwọ.

Ohun to ba ọpọ ninu jẹ julọ ni pe kani ko sa mọ ọlọpaa lọwọ ni, Funmilayọ to pa kẹyin i ba ṣi wa laye.

Ni kete ti o kuro ni agọ ọlọpaa, lo lọ dara pọ mọ awọn ajegbọrọ lọja Elewure lagbegbe Moniya.

Awọn eeyan oja naa ni awọn n rii gegebi ọkan lara awọn to n ba wọn ko agbo ninu ọja naa.

Koda awon kan ni awọn tilẹ ṣi rii ni ọjọ to pa arabinrin naa ṣugbọn ko si ẹni to rokan pe irufẹ ọdaran bẹẹ lee tun bọ mọ ọlọpaa lasiko naa.

Awọn alabagbe Funmilayo ni l'owurọọjọ to pade iku gbigbona lọwọ Sunday Shodipẹ, ohun at'awọneeyan rẹ ni wọn jọ wa ni iyẹwu ki ki o to tọrọ gafara pe oun fẹ lọ tọ.

Leyin iṣẹju diẹ l'awọnọmọde kan to sare wọle pẹlu aruwo pe ejo ti bu u ṣan.

Nigba ti wọn yoo fi de ibẹ ni wọn baa ti wọn ti ṣaa pa.

Àkọlé fídíò, Abule Ado explosion: Irọ́ ńlá ní NNPC pa lórí ìbúghbàmù Abule Ado níbí tí ẹ̀mí èèyàn 23

Ohun ti ọpọ lagbegbe naa n sọ ni oe, aṣemáṣe olopaa nipa jijẹ ki afunrasi naa o lọ mọ wọn lowo, ti wọn ko si tun fi to ara ilu leti kun ara oun to ṣokunfa iku to pa Funmilayọ.

Wo ohun tí ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n ṣe fún Sunday Shodipe, afurasí ìṣekúpani l'Akinyele

Ile ẹjọ Majisireeti agba kan nilu Ibadan ti ran Sunday Shodipẹ, afurasi tọwọ ọlọpaa tẹ lori iku ọwọọwọ lagbegbe Akinyẹle nilu Ibadan lọ si rimandi ọgba ẹwọn.

Wọn fi ẹsun pe o ṣekupa arabinrin Funmilayọ Ọladeji kan an.

Adajọ Majisireti agba, Patricia Adetuyibi ko gba ẹbẹ 'o jẹbi tabi o ko jẹbi' lẹnu afurasi naa ki o to ni ki wọn ọs fi si ahamọ ọgba ẹwọn naa titi di igba ti ileeṣẹ eto idajọ ni ijọba ipinlẹ Ọyọ igbẹjọ rẹ yoo fi waye.

Akinyele: Ilé ẹjọ́ fi Sunday Shodipe, afurasí ìṣekúpani l'Akinyele pamọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n

Adajọ Majisireeti naa wa sun itẹsiwaju igbẹjọ naa si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.

Àkọlé fídíò, Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọlu

Olupẹjọ jẹ ko di mimọ fun ile ẹjọ naa pe Ọladeji ti Sunday pa lẹyin to sa kuro lahamọ ọlọpaa ni wọn ṣi tori rẹ gbe e wa siwaju ile ẹjọ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Sunday Shodipẹ ti kọkọ jẹwọ pe oun loun pa Barakat, Grace, Azeezat atawọn meji miran ki ọwọ ọlọpaa to tẹẹ to si tun sa lahamọ.

wọn oluwọde

Oríṣun àwòrán, Twitter/femi aladejuyigbe

Ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gíga n'Ibadan ṣèwọ́de lọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lórí afurasí tó dàwátì

Iwọde ti n waye baye ni ilu Ibadan lati fi ẹhonu han lori bi afurasi ti wọn mu fun iku awọn eeyan marun kan ni agbegbe Akinyẹle ni ilu Ibadan ṣe salọ ni ahamọ ọlọpaa.

Awọn ọdọ ilu Ibadan tu sita lọpọ yanturu ya bo olu ileeṣẹ ọlọpaa ni Ẹlẹyẹle lati fi ẹhonu wọn han lori iṣẹlẹ naa.

Awọn ọdọ naa ti awọn adari ẹgbẹ akẹkọọ NANS lewaju fun ni wọn bẹrẹ iwọde naa ni iyalẹta Ọjọbọ.

Sunday Ogundipe

Ọlọ́pàá méjì wọ gàù lóri bí afurasí apanìyàn l'Akinyele ṣe sá lọ

Ile ișẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti bẹrẹ ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ọlọpaa meji ti Sunday shodipe, ọdaran to n dẹmi awọn ẹniyan legbodo lagbegbe Akinyele, bọ mọ lọwọ.

Alukoro ọlọpaa Fadeyi Olugbenga lo fidi ọrọ naa mulẹ.

Alukoro ọlọpaa ni wọn ti mu awọn ọlọpaa to yẹ ko mojuto ọdaran to salọ lahamọ, bi o tilẹ jẹ pe oun ko le sọ iye awọn ọlọpaa ti ọrọ naa kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹwẹ, Kọmisọna ọlọpaa ni ipinlẹ Oyo, Joe Enwonwu lo pada salaye pe, awọn ọlọpaa meji ti aje ọrọ naa ṣi mọ lori, ni awọn n ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun lọwọ.

Wayi o, awọn ọmọ ile igbimọ asofin ipinlẹ Oyo naa ti da si ọrọ ọhun, ti wọn si ti pe ọga agba fun ileesẹ ọlọpaa nilẹ wa, Mohammed Adamu lati ṣe iwadii finni-finni lori ọrọ naa.

Awọn ọmọ ile igbimọ asofin naa sọ ọ di mimọ lasiko ti wọn pe ipade awọn akọroyin nile igbimọ asofin ipinlẹ Oyo wipe, iyalẹnu lo jẹ pe iru ọdaran bẹẹ n bọ mọ ọlọpaa lọwọ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ wá àwọn tó gbàbọ̀dè láàrín wọn nítorí ẹ̀mí wa ò dè ní Akinyele

Ọbalaye agbegbe Akinyẹle nibi ti iṣẹlẹ iṣekupani lọwọọwọ ti n waye ni ipinlẹ Ọyọ lati nnkan bii oṣu mẹta sẹyin.

Alakinyẹle ti ilu Akinyẹle, Ọba James Ọdẹdiran ti pariwo sita pe bi afurasi ti wọn mu fun iṣẹlẹ iṣekupani naa ṣe sa mọ ọlọpaa lọwọ fihan pe ẹmi awọn olugbe agbegbe naa ko de.

Ni ọjọ Aiku ni ileeṣẹ ọlọpaa kede pe Sunday Shodipẹ ti wọn mu fun lilọwọ ninu iku Barakat Bello, Azeezat Shomuyiwa, atawọn eeyan miran lẹyin ti wọn mu u loṣu keje ọdun yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọba Ọdẹdiran ni kayeefi pata gbaa ni o jẹ pe afurasi naa lee sa kuro ni ahamọ awọn pẹlupẹlu bi wọn ṣe ni ẹwọn wa lọwọ ati ẹsẹ rẹ nigba gbogbo.

Ọba Alakinyẹle ṣalaye pe iwadii to rinlẹ gbọdọ waye o lati mọ awọn ọlọpaa to gbabọde lori iṣẹlẹ naa.

O ni iṣẹlẹ naa fihan pe bi afunrasi lori ẹsun to le bii ipaniyan ọlọwọọwọ ba lee sa mọ ọlọpaa lọwọ, ko si ẹmi ẹni to de lagbegbe naa niyẹn.

Sunday Ogundipe

Kò yé wa bí afurasí ṣe sálọ ní àhámọ́ àmọ́ ẹ ràn wá lọ́wọ́ lári ri mú padà - Ọlọ́pàá Oyo

Ile ișẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ko ti le e salaye titi asiko yii, ọna ti Sunday Shodipe, ẹni ọdun mọkandinlogun gba sa kuro ni ahamọ ọlọpaa ti wọn fi si, titi di asiko ti yoo tun pada foju ba ile ẹjọ.

Lasiko to n ba ile ișẹ BBCYoruba sọrọ, alukoro ile ișẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Fadeyi Olugbenga salaye pe, gbogbo nkan to jẹ ile ișẹ wọn logun julọ ni bi wọn yoo se gba afurasi naa mu.

"Nnkan to jẹ wa logun nisin yii ni bi a se maa mu u, gbogbo wa la n gbiyanju lati wa ọna bi a se maa mu.

Gbogbo igbesẹ bi a ṣe maa mú ni a n ṣe lọsan lorun, ti ẹnikẹni ba gbọ nnkan nipa rẹ ati ibi to n rin si, ki wọn tete fi to wa leti "

O ni ile iṣẹ ọlọpaa yoo ba àwọn ara ilu sọrọ laipẹ lori ọrọ naa, pẹlu afikun pe, iwadii n lọ lọwọ lori akọtun isẹlẹ ipaniyan to tun waye ni Akinyele lọjọ Ẹti to kọja.

Lori gbogbo awọn to ku ti ile iṣẹ ọlọpaa foju wọn han pẹlu Sunday nigba naa, alukoro ọlọpaa salaye pe, gbogbo wọn si wa ni ahamọ.

O ni wọn ti n lọ si ile ẹjọ tẹlẹ sugbọn nitori ọrọ Coronavirus lo faa, ti ile ẹjọ fi ni ki wọn lọ fi wọn pamọ si ahamọ ọlọpaa nitori awọn ẹwọn ti kun.

Ile ișẹ ọlọpaa, ninu atẹjade ti kọmisọna ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Joe Nwanchukwu fọwọsi, wa rọ ara ilu lati se atilẹyin fun wọn ki wọn le e ri afurasi naa mu nitori iranlọwọ ara ilu ṣe pataki pẹlu.

Àkọlé fídíò, Blind DJ: Etu Omotayo kò ríran àmọ́ ó le to irinṣẹ́ eléré pọ̀ láti kọrin láì sí ìrànwọ́

Bakan naa lo rọ awọn ọdọ ilu lati maa ni suuru, ki wọn maa si ja fun ara wọn nitori pe gbogbo akitiyan ni ọlọpaa n sa, lati fọ ilu mọ kuro lọwọ awọn onisẹ ibi gbogbo.

Titi di asiko ti a ko iroyin yii jọ, ile ișẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ko ti se alaye bi Sunday se bọ mọ wọn lọwọ ni ahamọ.

Nǹkan wọ̀lú! Afurasí ikú ọ̀wọọ̀wọ́ l'Akinyele jápa mọ́ ọlọ́pàá lọ́wọ́

Ṣe ẹ ranti, Sunday Shodipe, afurasi ti ọwọ awọn ọlọpaa tẹ lori awọn iṣekupani to waye lagbegbe Akinyẹle ni ilu Ibadan?

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ti kede pe, arakunrin naa ti sa lọ kuro ni ahamọ awọn ọlọpaa nibẹ.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita latọdọ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa, ni eyi ti jẹyọ.

Sunday Shodipe

Oríṣun àwòrán, Others

Atẹjade naa fi jẹ ko di mimọ pe, Sunday Shodipẹ ni afurasi ti wọn mu fun ipaniyan ṣisẹ-n-tẹle to waye lagbegbe Akiyẹle ti wọn ṣe afihan rẹ pẹlu awọn meji miran lọjọ kẹtadinlogun, oṣu keje ọdun 2020, ti wọn si gbe lọ si ileẹjọ, ki wọn to da a pada si ahamọ ọlọpaa.

Amọ ṣa, ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla oṣu kẹjọ ni afurasi naa sa lọ kuro ninu ahamọ ọlọpaa, ti awọn ọlọpaa si ni awọn ṣi n wa a.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, iku Wasilat Adeola, Barakat Bello, Grace Oshiagwu, Mojeed Tirimisiyu to jẹ ọmọ ọdun marun wa lara awọn ti awọn ọlọpaa ni arakunrin naa jẹwọ pe oun pa.

Àkọlé fídíò, Ibadan Murder: Oyún oṣù méje ló ń bẹ nínú Azeezat, kí wọ́n tó f'òkúta fọ́ ọ lórí

Bakan naa lo gbiyanju ati pa Adeọla Azeez ati ọmọ rẹ obinrin Dọlapọ Oyeyẹmi ti ori ko yọ.

Nibayii ileeṣẹ ọlọpaa ti jẹ ko di mimọ fun araalu pe ẹnikẹni to ba kofiri rẹ ko fi to ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa lagbegbe rẹ leti.