Osun-Osogbo Festival 2020: Àwọn ẹlẹ́sìn àdáyébá rú òfin Covid-19 níbi àṣekágbá ọdún Osun Osogbo

Ojubọ Osun Osogbo

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Pupọ ninu awọn eeyan to peju sibi aṣekagba ọdun Osun-Osogbo to waye ni ipinlẹ Osun, lo tapa sofin ijinasiraẹni.

Bakan naa ni awọn eeyan ọhun kọti ikun si ofin to rọ mọ apejọjọpọ ọpọ ero ti ijọba gbe kalẹ nibi ayẹyẹ ọdun naa.

Iroyin ni, lati afin Ataoja ilu Osogbo nibi ti Arugba ti gbe igba lọ si odo Osun lati ṣetutu atawọn nnkan miran to rọ mọ ọdun naa, ni ko ti si ẹnikẹni to tẹlẹ ofin ijinasiraẹni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bo tilẹ jẹ pe ero ko fi bẹẹ pọ nibi ayẹyẹ naa bi ti ọdun to kọja, iye awọn eeyan to yọju sibi ọdun ọhun kan n ṣajọyọ ni, lai bikita nipa ajakalẹ arun to wa lode.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ naa, kọmiṣọna feto aṣa ati irinajo afẹ, Obawale Adebisi sọ pe, kii ṣe pe bi ijọba ṣe ṣadinku iye ero to pejo sibi ọdun naa wa lati ni awọn ara ilu lara, ṣugbọn lati daabo bo wọn ni.

Arugba ọdun Osogbo

Oríṣun àwòrán, Others

Kọmiṣọna ọhun to sọrọ lorukọ gomina Gboyega Oyetola ni "idi ti a ko ṣe fẹ ki ero pọ lapọju nibi ayẹyẹ ọdun yii, ni arun to wa lode, gẹgẹ bi gbogbo wa ṣe mọ, arun yii n pọ si ni ipinlẹ wa, nitori naa, a ni lati ṣọra."

O tẹsiwaju pe "A fẹ fi akoko yii bẹ Ọba Ataoja ki wọn gba fun wa lọdun yii, ṣugbọn a fi da wọn loju pe, ti ọdun to n bọ yoo dun ju bayii lọ, a o si faye gba ọpọ ero lati peju sibi ọdun naa."

Ataoja ilu Osogbo, Ọba Jimoh Oyetunji ba awọn eeyan to peju sibi ọdun naa ati gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Osun ṣajọyọ, lẹyin naa lo gbadura fun alaafia ati itẹsiwaju ipinlẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, The Polytechnic Ibadan: Ẹ̀rọ abẹ́lé tó ń fọ ọwọ́ àti ‘Ventilator’ ló ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Osun-Osogbo Festival 2020: Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun tí búwọlù ìlànà àyẹyẹ Osun-Osogbo ọdún 2020

Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun tí búwọlù ìlànà àyẹyẹ Osu-Osogbo ọdún 2020

Oríṣun àwòrán, Others

Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun ti buwọlu ìlànà ti yóò fí ṣe ayẹyẹ ọdún Osun-Osogbo ọdún 2020.

Síbẹ̀ wọ́n ti fòfin de ìpéjọpọ̀ ẹnikẹni ti kò ní ohun kohun lati ṣe pẹ̀lú ètò ayẹyẹ náà.

Wọ́n sọ èyí di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde tí kọmísọ́nnà àsà àti ìrìnàjò afẹ́, Obawale Adebisi fọ́wọ́sí.

Adebisi ní ìjọba gbé ìgbésẹ̀ yìí nítorí bi àrùn Covid-19 ṣe n peléke sii lójoojúmọ́ ní ìpińlẹ̀ Osun.

" Ìjọba ń fi àsìkò yìí sọ fún àwùjọ pé ayẹyẹ Osun-Osogbo ti ọdún yìí yóò yàtọ̀ si bí wọ́n yóò ṣe jẹ pé àwọn olùjọ́sìn Osun nikan ni yóò ráàyè láti wọ ojúbọ láti ṣe gbogbo ìrúbọ tó bá yẹ."

" Bákan náà ni àwọn olùjọsìn yoo tẹ̀lé gbogbo ìlànà ìjìnà síraẹni ti ìjọbá là sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ COVID-19.

" Nítorí ìdí èyí, ìjọba ti wọ́gilé gbogbo àyéyé to niṣe pẹ̀lú ètò náà, ó sì gbàdúrà, àwọn ètò mírà ti yóò maa wáye lọ́jọ́ ìwáju yóò lọ bí ó ṣe tọ́ àti bí ó ṣe yẹ."

Àkọlé fídíò, Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka

Ṣaaju ni Ọọni Ifẹ ti kọkọ sọrọ pé....

Osun Festival: Ooni ní àwọn ọlọ́ṣun kìí ṣe abọ̀rìṣà

Ni ọjọ Satide ni ọdun Ọsun waye nilu Ile Ife lai naani ariwo ati ofin to de iwa itakete ati ijinna sira ẹni.

Ooni

Oríṣun àwòrán, @ooniadimulaife

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ọdun bii ọdun egungun nilu Ibadan ati ayẹyẹ Ojude Ọba nilu Ijebu Ode ni ko lee waye nitori ọsẹ ti arun Coronavirus n se, sibẹ Ile Ife ko wọgile ọdun Ọsun lọdun yii.

Lasiko ọdun Ọsun naa, Ọọni tilu Ile Ife, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi, Ọjaja Keji gbalejo awọn olorisa Ọsun ni aafin rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi o tilẹ jẹ pe Ọba Ogunwusi gba pe ọwọja arun Coronavirus si n peleke si, sibẹ o rọ awọn ọmọ Naijiria lati tẹle awsn igbesẹ to yẹ fun idena itankalẹ arun naa.

Àkọlé fídíò, Hospital Wedding: Oṣù kan péré ni Tash fi ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Simon kó tó kú

Bakan naa lo salaye pe awọn to n bọ Ọsun kii se abọrisa, ajọdun omi si ni ọdun naa, nitori omi lo n gbe ẹmi wa ro.

"A n lo ọdun naa lati fi sopọ mọ awọn aṣẹda wa ni lati ipasẹ ohun ti aṣẹda da, eyi ti yoo wo aye san, paapaa lasiko ajakalẹ arun Coronavirus yii.

A n ranti awọn asẹda wa ni, ko si yẹ ka maa pe awọn eeyan to n se eyi ni abọrisa."

Ọba Ogunwusi ni wọn kan nipa fun awọn lati se adinku ọdun naa, tii se ọdun pataki nilu Ile Ife.

OONI

Oríṣun àwòrán, @ooniadimulaife

O ni eyi ko ni jẹ kawọn da wahala miran silẹ lasiko ti awọn n wa ọna lati yanju isoro kan.

Àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yoruba kò gbọdọ̀ gbàgbé àṣà ati ohun àdàyébá wọn - Ooni Ile Ife

Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi ti rọ awọn ọdọ ilẹ Yoruba lati ma gbagbe aṣa, iṣe atawọn ohun adayeba ilẹ wọn.

Alayeluwa lo sọ ọrọ naa loju opo Instagram rẹ lẹyin to gbalejo awọn ọdọ kan ninu afin rẹ to wa ni Ife.

Bakan naa ni Ooni tun sọ ninu fọran kan ti gbajugbaja oṣere ati apanilẹrin ti gbogbo eniyan mọ si Mr Macaroni, Debo Adebayo gbe jade lẹyin abẹwo naa pe "Aye ṣi n ma n kunlẹ fun agbalagba."

Ninu fidio ọhun ti Arole Oduduwa ti kopa lo ti sọ pe "Awa ti a wa lati iran Yoruba, ati kaakiri agbaye ni lati maa bọwọ fun awọn agbalagba."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O ni o yẹ ki ọmọde maa kunlẹ, ki wọn si tu maa dọbalẹ fun agbalagba gẹgẹ bo ṣe wa ninu aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba.

Arole Oduduwa ṣalaye pe inu oun dun lati gbalejo awọn ọdọ naa, ati pe o jẹ anfani nla lati ru awọn ọdọ ọhun soke ninu ijiroro wọn fun bi ọjọ ọla yoo ṣe dara.

Ooni

Oríṣun àwòrán, @ooniadimulaife

Ooni pari ọrọ rẹ pe "Awọn ọdọ ko gbọdọ gbagbe aṣa ati iṣe ilẹ wọn nitori ohun ni ọrọ ati ọla to gaju ti gbogbo wa gbọdọ ni."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Lara awọn ọdọ to ṣabẹwo si Alayeluwa ni, Mr Macaroni, Seyi Awolowo, atawọn eeyan miran.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa ọdun 2015 ni Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi gori itẹ gẹgẹ bi Arole Oduduwa Olofin Adimula Ile Ife.

Àkọlé fídíò, Ẹ wo adúrú ǹkan tí Softface ma ń tò pọ̀ láti sín àwọn òṣèré, gbajúgbajà jẹ