Michelle Obama: Ààrẹ Trump kò yẹ nípò ààrẹ fún Amẹ́ríkà

Michelle Obama and Donald Trump give speeches
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Iyawo aarẹ Amẹrika ana, Michelle Obama, ti sọko ọrọ si aarẹ Donald Trump, bi ẹgbẹ oṣelu Democrat ti se n palẹmọ lati fontẹ lu Joe Biden gẹgẹ bi oludije wọn fun ipo aarẹ.

''Donald Trump kii ṣe aarẹ to yẹ fun orileede yii'' ni ọrọ ti Michelle sọ ninu fọnran kan to fi ṣọwọ sawọn to n kopa nibi apero ẹgbẹ Democrat.

Awọn ọmọ ẹgbẹ Republican to jẹ ti aarẹ Trump naa, ni inu wọn ko dun si bibu ẹnu atẹ lu aarẹ ọhun nibi ipade apero ẹgbẹ awọn Democrats.

Ni ọjọ Kẹta oṣu Kẹwa ọdun yii ni idibo aarẹ yoo waye ni Amẹrika.

Nitori ajakalẹ arun Covid-19, awọn ọmọ ẹgbẹ Democrat ko ṣe apero elero pupọ ni Milwaukee, Wisconsin, toun ti afẹfẹ yẹyẹ to maa n ba iru apejọ yii wa.

Amọ ko daju pe apero eleyi ti wọn ṣe loju ẹrọ ayelujara lọtẹ yii, yoo ṣe iwuri bi tatẹyinwa fawọn ọmọ ẹgbẹ naa.

Ààrẹ Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ẹgbẹ Democrat nikan kọ ni yoo koju ipenija yii,

Ẹgbẹ Republican naa yoo ni lati ṣe iṣẹ takuntakun ki awọn eeyan ba le tubọ dibo wọle fun wọn pada ninu idibo to n bọ lọna.

Kin gan ni Michelle sọ?

Arabinrin Obama, ti wọn ti gba ọrọ rẹ silẹ ṣaaju ki ọgbẹni Biden to kede Sẹnẹtọ Kamala Harris, gẹgẹ bi igbakeji rẹ ko ṣẹnu ku ba aarẹ Trump wi.

Ninu ọrọ rẹ to fi kaṣẹ eto lalẹ ọjọ kinni apero naa, Michelle ni ''eeyan ko le fi makaruru ṣe iṣẹ aarẹ''

Bẹẹ naa lo fi kun ọrọ rẹ pe, eto ọrọ aje ti dẹnu kọlẹ fọjọ pipẹ nitori aarẹ fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ajakalẹ arun Covid-19.

Aworan Michelle Obama

Ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ Donald Trump, àbúrò rẹ̀ Robert, dèrò ọrun

Robert Trump, aburo aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump ti dagbere faye lẹni ọdun mọkalelaadọrin.

Aarẹ Trump lo fọrọ yii lede fun ra rẹ ninu atẹjade kan fi sita nile ijọba, White House.

Lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹjọ ọdun 2020 ni Robert papoda nile iwosan kan niluu New York.

''Pẹlu ibanujẹ ọkan ni mo fi sẹ ikede yii pe aburo mi atata, Robert ti fi aye silẹ. Robert kii ṣe aburo mi lasan, ọrẹ kori o sun mi ni,'' Aarẹ Trump lo sọ bẹẹ.

Trump ni oun yoo maa ṣe afẹẹri Robert ni laelae, ṣugbọn o ni oun mọ pe awọn yoo tun pade lẹsẹ Olugbala.

Aya Trump naa, Ivanka gbadura wi pe ki Eleduwa tẹ Ọgbẹni Robert si afẹfẹ rere.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ivanka sọ loju opo Twitter rẹ pe idile Donald Trump ko le gbagbe Robert laelae.

Ko si ẹni to mọ ohun to ṣe okunfa iku to pa Ọgbẹni Robert, amọ o ti n ṣaarẹ fun igba diẹ ki ẹlẹmi to gba a.

Trump ń lérí láti ti ojú òpó ìkànsíraẹni ayélujára pa nílẹ̀ Amẹrika

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti n gbaradi lati tọwọ bọwe aṣẹ kan to ni ṣe pẹlu iṣakoso awọn ileeṣẹ to n risi oju opo ikansiraẹni lori itakun agbaye.

Igbeṣẹ yii lo n waye lẹyin ti Trump halẹ mọ awọn ileeṣẹ naa lẹyin to fẹsun kan wọn pe wọn ko fun awọn ẹgbẹ kan ni anfani lati sọ tinu wọn.

O ti to ọjọ mẹta ti aarẹ Trump ti n ni itakurọsọ pẹlu awọn ileeṣẹ ọhun, eyi tiko sẹyin iru awọn ọrọ to ma n fi lede loju opo Twitter rẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Họwuhọwu laarin Trump ati awọn ileeṣẹ ọhun bẹrẹ lẹyin ti Twitter gbe igbeṣẹ lati ṣe ọfintoto ohun to ba n fi lede loju opo Twitter rẹ lati mọ boya ootọ ni.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba Amẹrika ko ti sọ ni pato ohun ti yoo wa ninu iwe aṣẹ naa, ṣugbọn o ṣoro lati sọ igbesẹ ti aarẹ Trump lee gbe lori ọrọ to ni ṣe pẹlu oju opo ikansiraẹni lai ṣe pe ile igbimọ aṣọfin ilẹ naa fọwọ si.

Ṣe Trump lagbara lati gbeṣẹle oju opo ikansiraẹni?

Gẹgẹ bi ọrọ ti amofin kan ni fasiti Havard, Laurence Tribe ṣe sọ, Twitter kii fi ẹtọ awọn eeyan dun wọn lati sọ ohunkohun to ba wa lọkan wọn.

Trump

Oríṣun àwòrán, @gods_psych

O ni Twitter ki ṣe ileeṣẹ ijọba, nitori naa ileeṣẹ aladani lee ṣakoso ohun ti awọn eeyan le fi lede loju opo rẹ lai si họwuhọwu.

Tribe ṣalaye pe ofin ilẹ Amẹrika ko gba ijọba laye lati fi ẹtọ awọn eeyan lati sọrọ dun wọn, ṣugbọn awọn ileeṣẹ opo ikansiraẹni bi Facebook ati Twitter le yọ ọrọ ti eeyan ba fi lede loju opo wọn kuro ti ko ba jẹ ootọ.

A still image taken from a video shows Minneapolis police officer Derek Chauvin during the arrest of George Floyd

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty

Àkọlé àwòrán, Former police officer Derek Chauvin was detained on Friday

Amofin naa ni ti Trump ba le gunle iṣakoso oju opo ikansiraẹni nilẹ Amẹrika, o tumọ si pe oun funra rẹ lo n fi ẹtọ awọn eeyan lati sọ erongba wọn dun wọn.

Trump dínà mọ́ Nàìjíríà àtí orílẹ̀èdè márùn ún míì láti má wọ Amẹ́ríkà

Ààrẹ Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilẹ Amẹrika ti fi Naijiria ṣe ọkan lara awọn orilẹede mẹfa ti wọn bẹgi dina fifun wọn ni irufẹ iwe aṣẹ irina kan lọ si orilẹede wọn.

Awọn orilẹede to pẹlu Naijiria ni ni Eritrea, Sudan, Tanzania, Kyrgyzstan ati Myanmar ṣugbọn awn ọmọ orilẹede wọnyii kan ṣi le lọ ṣe ibẹwo nikan si Amẹrika.

Amẹrika ni ṣe ni awọn yoo kawọ ko lori fifun awọn eeyan to wa lati Nigeria, Eritrea, Kyrgyzstan, ati Myanmar ni iwe aṣẹ irina to lee sọ wọn di olugbe ilu naa.

Ni ti Sudan ati Tanzania, awọn ko lanfani lati kọwe gba iwe irina fun oniruuru nkan ti wọn ba fẹ ṣe eyi ti wọn maa n ri gba tẹlẹ nipasẹ "lottery".

Ki wa nidi gangan ti US fi bẹgi dina Naijiria atawọn marun mii?

Oṣiṣẹ orilẹede Amẹrika kan ti ṣalaye ọrọ pe igbesẹ tuntun yii waye nitori pe orilẹede mẹfẹfa yii kọ lati ṣe ohun to tọ ni ibamu pẹlu ofin Amẹrika nipa aabo ati pinpin iroyin.

"Gbogbo awọn orilẹede yii lo fẹ ṣe ohun ti wọn lagbara o ṣugbọn ohun to tilẹ kere ju lọ ti Amẹrika ka silẹ, wn ko ri i gbeṣe". Eyi ni ohun ti akọwe ikọ alaabo Chad Wolf sọ lọjọ ẹti.

O fi kun un pe awọn oṣiṣẹ yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu Amẹrika lati fi kun amojuto abo wọn.

Lọdun 2017 ni Aarẹ Amẹrika, Donald Trump kọkọ gbe igbesẹ bibẹgi dina m awọn orilẹede ki wọn ma wọ Amẹrika. Ni bayii, o ti di i mọ orilẹede meje ti ọpọ wọn si jẹ ilu ti Musulumi ti pọ ju.

Bẹẹ si ni lọdun 2018, o le ni ẹgbẹrun mẹjọ ọmọ Naijiria ti US fun ni iwe aṣẹ irina. Eyi si to ilọpo meji ohun ti wọn fun awọn apapọ awọn orilẹede marun un to ku.

Lọdun 2018 kan naa, o le ni ẹgbẹrun meji ti wọn fun awọn ara Sudan, ọdunrun o din mẹwaa ni wọn fun awọn ara Tanzania ti wọn si fun awọn ara Eritrea ni mọkanlelọgbọn.

Lati ọdun 2017 lorilẹede Amẹrika ti n kede pe awọn yoo gbe ote le fifun awọn ara Eritre ni irufẹ iwe aṣ irina kan pato.