Coronavirus in Osun: Ìlànà tuntun fún òkú sínsin wọlé dé sí ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun

awọn bẹẹdi ni ibudo itọju awọn alaarun coronavirus kan ni ipinlẹ Ọṣun

Oríṣun àwòrán, osun state government

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gẹgẹ bi ara ọna lati dena ajakalẹ arun coronavirus ni ipinlẹ Ọṣun, ijọba ipinlẹ naa ti gbe awọn ilana tuntun jade fun oku sinsin, eleyi ti gbogbo awsn mọlẹbi oku gbọdọ tẹle.

Ninu atẹjade ilana tuntun naa ti ijọba ipinlẹỌṣun gbe kalẹ, ko gbọdọ ju ogun eeyan ti yoo maa wa nibi eto isinku ti wọn si gbọdọ lo ibomu wọn ko duro deede.

Bakan naa ni wọn ni gbogbo mọlẹbi to ba fẹ sinku ti gbọdọ nii lọkan pe awọn yoo ṣe inawo rira eroja apapkokoro sanitaisa (Sanitizer) eyi to gbọdọ wa ni ibi ti wọn ti fẹ sinku bẹẹni wọn gbọdọ rii pe awọn to ba wa nibẹ tẹle ofin ijinasiraẹni.

Bakan naa ni ilana tuntun fun eto isinku yii pọn ọn ni dandan fawọn mọlẹbi to n sinku lati fi ọrọ to ọga ọlọpaa to wa lagbegbe naa leti nipa sjs ati ibi ti wọn ti fẹ sinku ati pe oṣiṣẹ ijsba ibilẹ to n mojuto ọrọ ajakalẹ arun ni o gbọdọ lewaju eto isinku bẹẹ.

Bakan naa ni awọn to fẹ sinku gbọdọ kọ lẹta igbayọnda ti wsn gbọdọ fi iwe ẹri oku lati ileewosan ijọba tabi lẹta lati ọdọ ileeṣẹ ijọba feto ilera nipinlẹ naa, ti amugbalẹgbẹ fun gomina lori ọrọ ilera gbọdọ buwọlu.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Lara awọn oun to gbọdọ wa ninu lẹta naa ni ibi ti oloogbe naa gbe titi ọlsjọ fi de, ohun to ṣokunfa iku rẹ, ati ẹjẹ lati ọdọ awọn mọlẹbi lati tẹle gbogbo ofin ti ijọba gbe kalẹ lori ilana oku sinsin lati dena ajakalẹ arun coronavirus ni ipinlẹ naa.

Ileewosan nla LAUTECHTH fi ikede 'ẹ wa gb'oku yin sita l'Oṣogbo

Nibayii, awọn alaṣẹ ileewosan nla LAUTECHTH ni ilu Osogbo ti fun awọn eeyan to ba ni oku ni ileegboku pamọ si rẹ ni gbedeke ọsẹ meji lati wa palẹ oku wọn mọ bibẹẹkọ awọn yoo sin gbogbo wọn pọ ni.

Gẹgẹ bi atẹjade ati ikede kan ti wọn fi sita lawọn ileeṣẹ redio nipinlẹ naa lọjọ Iṣẹgun, awọn alaṣẹ ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun naa ṣalaye ile igbokupamọ si rẹ ti kun akunfaya eyi to n jẹ ko nira lati gba awọn oku tuntun wọle.

Amotekun: Ọmọ ilẹ̀ China mẹ́jọ, ọmọ orílẹ̀èdè Ghana mẹ́ta wọ gàù Àmọ̀tẹ́kùn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun

awọn ajikusa wa naa ninu ọkọ Amọtẹkun

Oríṣun àwòrán, Amiloaded

O dabi pe erongba awọn ọmọ Yoruba lori idasilẹ ikọ alaabo Amọtẹkun ti bẹrẹ si ni fidi mulẹ bayii o.

Ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹu bayii pẹlu bi wọn ti ṣe wọ awọ igbo ni ipinlẹ naa lọ lati fi panpẹ ofin gbe awọn ọmọ orilẹede China ati Ghana kan ti wọn n ji kusa wa ni ipinlẹ naa.

Awọn ọmọ orilẹede China mẹjọ, ọmọ Ghana kan atawọn ọmọ onilẹ mẹta ni ọwọ ikọ Amẹtẹkun ni ipinlẹ Ọṣun ba nibi ti wọn ti n wa kusa lọna ti ko bofin mu ni ipinlẹ naa.

Awọn iroyin ni ipinlẹ naa ṣalaye pe agbegbe It5agunmọdi, Igun ati Ariye ni ijsba ibilẹ Atakunmọsa West ni wọn ti mu awọn eeyan naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ ajọṣepọ laarin iks amọtẹkun atawọn ọmọ ikọ alaabo alajọṣe JTF ni ipinlẹ naa lo ṣokunfa mimu ti wọn mu awọn ajikusa wa naa pẹlu ajọṣepọ araalu.

Ninu ọrs rẹ, oludari agba fun iks Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Amitolu Shittu ni igbesẹ naa wa lara igbesẹ ti ijsba ipinlẹ naa la kalẹ fun pipagidina awọn to fẹ maa gbẹyin ja ipinlẹ naa lole.

Wọ́n ti fi ẹ̀sùn "ghost worker" kan ọmọ olórí òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlè Oyo

Makinde

Oríṣun àwòrán, Makinde

Àkọlé àwòrán, Oyo LGA Chairmen: Malami, IGP àti alága APC ni yóò káwọ pọ̀'yìn rojọ l'Oyo

Wọn ti fẹsun kan ọmọ olori oṣiṣẹ ìjọba ìpínlè Oyo pé o gbiyanju lati lo ipo iya rẹ lati gba "ghost worker" siṣẹ.Ojú òpó Twitter lawọn èèyàn kan ti bi ẹnu àtẹ lu Ayobami Agboola to jẹ ọmọ olori oṣiṣẹ ìjọba ìpínlè naa, Amidat Agboola lẹyìn tí ọgbẹni kan, Sulaimon Adesola ni o ṣèlérí láti fi orúkọ oun sara àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ti yoo máa gba owo oṣù lai yọju si ibiṣẹ.Awuyewuye ọhún bẹrẹ nígbà tí Ayobami ati ọrẹ rẹ, Sulaimon n jiyàn lori iha ti ìjọba ìpínlè Oyo, labẹ iṣakoso Gomina Seyi Makinde kọ sí àjàkálẹ̀ àrùn Coronavirus to ń ba gbogbo agbaye fínra.

Itakurọsọ wọn fi han pe Ayobami naka abuku sí Sulaimon pe idi to fi n bù ẹnu àtẹ lu ìjọba tó wà lori alefa l'Oyo ni pe ko rí anfaani láti ṣiṣẹ gẹgẹ bí "ghost worker" labẹ iṣejọba naa.Ti Sulaimon si fesi pe Ayobami fúnra rẹ lọ ṣèlérí fún òun pé yóò lo ipò ìyá rẹ̀ to jẹ adari oṣiṣẹ ìjọba láti fún òun ní iṣẹ "ghost worker" ọhun.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Bó tilẹ jẹ Ayobami ní ootọ ni pé wọn ní ajọsọ lori ọrọ iṣẹ, òun ko ṣèlérí fún pe òun yóò lo ipò mama oun ninu ìjọba láti sọ di oṣiṣẹ to ń gba owo oṣù lai yọjú sí ileeṣeẹ ìjọba kankan.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ileeṣẹ iroyin abẹle kan pe Ayobami sọ fun akọroyin wọn pe lootọ l'oun ṣèlérí iṣẹ fún arákùnrin náà gẹgẹ bi "ghost worker," ṣugbọn ko ṣẹyin bo ṣe ma n yọ oun lẹnu ni gbogbo igba fún iṣẹ, ti òun sì má n sọ fun pe òun yóò wà nkan ṣe si, ko le fún òun ní ìsinmi.Ni bayii, itakurọsọ awọn ọkunrin mejeji ti da gbas gbos silẹ loju opo Twitter ti ọpọ eeyan sit i n da si ọrọ na gẹgẹ bi iwoye wọn.

Malami, IGP àti alága APC Oyo ni yóò káwọ pọ̀'yìn rojọ nítori àwọn alaga Kansu tẹlẹri

Ilé ẹjọ gíga kan nípìnlẹ Oyọ to fi Ibadan ṣe ibùjóko ti dá àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ àti àwọn ìgbìmọ ìdàgbasoke agbegbe méjìdínláàdọrin lẹkun láti maa fi tipa àti ọ̀nà ti kò ba òfin mu pada si ọọfiisi wọ́n.

Igbẹjo tí adajo Moshud A.A Abass saaju èyi ti àgbẹjọrò àgbà Akin Onigbinde ti mu iwe idaduro lori igbẹ́sẹ̀ àwọn alága ti wọ́n le kuro lori oye lati ma fi tipátipa pada si ẹnu iṣẹ́ nitori o le da omi àláafi ru ni ìpínlẹ̀ Oyo.

Idajọ náà ti ile ẹjọ gíga ìpińlẹ Oyo gbe ìdájọ kalẹ pe awọn àlága àti minisita fun idájọ àti agbejoro àgbà fun ijọba apapọ Abubakar Malami, Isipẹtọ ọlọpàá Mohammed Abubaka, to fi mọ kọmisọna ọlọpàá ìpínlẹ Oyo Shina Olukolu àti alaga ẹgbẹ òṣèlú APC ọgbẹni Akin Oke lọ ki ọwọ́ ọmọ wọ́n bọ aṣọ.

O fi kun pe ki gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àti àwọn olólùfẹ wọ́n ma gbe ìgbésẹ̀ kankan titi gbogbo àwọn ti ijọba ibilẹ Oyo pe ki wọ́n wa jẹ́jọ ni ọjọ káàrun osù keji ọdun yií yóò fi wá sọ ti ẹnu wọ́n.

Ní àsìkò ti BBC Yoruba ba akowe ikéde fun Gomina ipinlẹ Oyo sọ̀rọ̀ ọgbẹ́ni Taiwo Adisa sàlàye pé ẹjọ too wà nilẹ kìí ṣe ọ̀rọ̀ òni, biko ṣe pé ẹjọ ti wà lori àwọn alága ijọba ibilẹ Oyo lati àsìkò ijọba Senator Ajimobi.

Adisa sàlàye pé ìdájọ yìí yóò fun àwọn òṣìsẹ́ ijọba ìbìlẹ ni ore-ọ̀fẹ́ láti pada sẹnu iṣẹ́ nítori gbogbo ìgbà ti hílahilo àwọn alága ìjọba tẹlẹ̀ri ti bẹ̀rẹ̀ ni gbogbo òṣìṣẹ́ ti ni àwọn ko fẹ fi ẹmi awọn sòfò ti wọ́n si ti gbe ilé Joko.

O ní nibayìí àwọn alaga fidhẹ ti Makinde yan yóò ppada si ẹnu iṣẹ́ ti gbogbo ǹkan yóò si maa lọ ni ìrọwọrọṣẹ ni ìpińlẹ Oyo.