Sagamu Market Fire: Dapo Abiodun ṣeleri ìpèsè ìtura fáwọ́n olùtaja

Oja sagamu

Oríṣun àwòrán, Ogunstate/twitter

Àkọlé àwòrán, Sagamu Market Fire: Dapo Abiodun ṣeleri fáwọ́n olùtaja
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gómìnà Ipinlẹ Ogun ọmọọba Dapo Abiodun ti fi ọkàn àwọn òǹtàjà lọja Sabo ní ìlú Sagamu ti iná jó sọ̀ọ̀bù wọ́n, balẹ pé oun yóò ba wọ́n kọ òmíràn ni wàrànsṣesà.

Gomina Abiodun kede eyi lásìkò to ṣe àbẹwò si ibi ìṣèlẹ̀ ina náà ni ọjà Sabo ni Sagamu.

O wa rọ gbogbo awọn ọlọjà náà láti ni sùúrù pẹ̀lú ìjọba àti pe, ó ṣe pàtàkì ki àwọn ọlọ́jà náà kọ ẹko to pọ̀ nínú ina to jà ninu ọjà náà.

Abiodun ní ''ni àgbara Ọlọrun, a o tún ọjà yìí kọ, a kò si ni fi àsìkò sòfò rárá, a o ṣètò gbogbo ǹkan ti o bá yẹ, ti irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò fi ni wáye mọ."

Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, ogunstate/twitter

Àkọlé àwòrán, Sagamu Market Fire: Dapo Abiodun ṣeleri fáwọ́n olùtaja

Bakan naa lo ṣèlérí pe ìjọba oun yóò bẹrẹ si ni bu omi tutu si ibi ti bàta ti n ta àwọn olùtaja náà lẹ́sẹ.

Lówùrọ́ ọjọ́ Iṣẹ́gun ni ìròyìn tún tàn pé, ọja Sabo nijọba ìbílẹ Sagamu ni ìpínlẹ̀ Ogun jó sọọbù ọgọ́run.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ina naa tun jó dukia to le ni aimọye mílíọnù Naira.

Ina ọhun, ti wọ́n ni o bẹ̀rẹ̀ ni dédé ààgo kan oru láti sọọbu awọn alásọ, lo jo wọ gbogbo sọọbù to kù nínú ọja naa.

Dapo Abiodun laarin ọpọ ero nibi ti isẹlẹ ina ti waye ni Sagamu

Oríṣun àwòrán, ogunstate/twitter

Iròyìn sọ pé, ìná mọnamọna to dédé de laáàrin òòru lo sòkùnfa ina náà.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Olùtaja kan ti ọ̀rọ̀ náà soju rẹ sàlaye pe, o le ni ọgọrun sọọbu to jóna.

Awọn alasọ, onisu, àwọn to n ta obi àti àwọn ǹkan ikọ́le, páta ni ọ̀rọ̀ náà kan.