Toyosi Adesanya: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní Kwara ní àwọn àti Fijilanté wà nínú igbó láti ṣàwárí ọ̀daràn tó ṣèkọlù náà

Toyosi Adesanya Ileyemi ati ọkọ ti wọn kọlu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja osere ori itage lobinrin, Toyosi Adesanya Ileyemi ti iroyin gbalẹ kan pe awọn gende agbebọn kọlu ti ba BBC Yoruba sọrọ.

Lasiko ti a kan si Toyosi lori aago ilewọ rẹ fun ifọrọwerọ, obinrin ti ori ko yọ ninu ikọlu naa, ti ko lee sọrọ daada, fi to wa leti pe ojora si n mu oun lọwọ nipa isẹlẹ laabi naa, to si han ninu ohun rẹ pẹlu.

Toyosi Adesanya, ẹni to ni alaafia ni oun wa, seleri pe ni kete ti ara oun ba ti bọ sipo lati sọrọ nipa bi isẹlẹ naa se waye, ni oun yoo dahuin ibeere latọdọ BBC Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ yii, aarẹ fun ẹgbẹ awọn osere ori itage TANPAN, Bolaji Amusan, ti gbogbo eeyan mọ si Mr Latin sọ fun BBC Yoruba pe oun ti ba Toyosi Adesanya sọrọ ni kete ti isẹlẹ naa waye laarọ ọjọ Aje, ti inu oun si dun pe ara rẹ le.

Ọ́kọ ti Toyosi Adesanya ati Juwọn Awẹ wa ninu rẹ tawọn agbebọn yinbọn mọ

Oríṣun àwòrán, Toyosi Adesanya

Amusan ni isẹlẹ naa ko mu inu oun dun debi pe oun yoo maa sọrọ rẹpẹtẹ lori rẹ amọ lẹyin ti ẹgbẹ awọn ba se ipade tan lori isẹlẹ yii, awọn yoo fi iroyin sita nipa oloogbe to salaisi ninu isẹlẹ naa, ati ohun ti ẹgbẹ fẹ se fun.

Wayi o, ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Kwara ti salaye lori ikọlu tawọn agbebọn kan se si osere ori itage obinrin, Toyosi Adesanya Ileyemi.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Osisẹ alarena fun ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Kwara, Geffrey Okasanmi Ajayi salaye pe aarọ ana ni isẹlẹ naa sẹlẹ, nigba ti awọn agbebọn kọlu awọn osere tiata kan, eyi ti awọn kan fi to ileesẹ ọlọpa leti.

Ajayi ni opopona marosẹ Ogbomọsọ si Ilọrin ni isẹlẹ ikọlu naa ti waye, ti Kọmisana ọlọpa nipinlẹ Kwara, Kayode Ẹgbẹtokun si pasẹ pe ki awọn ọlọpa tete dide si isẹlẹ naa.

Awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, PoliceNG

"A ti gbe oku lọ sibudo igbokusi nile iwosan, awọn to sese lati se itọju fun wọn, ta si ti bẹrẹ iwadi wa, awọn ọlspa ati fijilante ti wa ninu igbo lati se awari awọn eeyan to huwa ibi yii. Ti ọwọ wa yoo si tẹ wọn."

Nigba to n salaye lori ohun tawọn eeyan kan fisita pe awọn gende agbebọn to sọsẹ naa jẹ Fulani, Ajayi ni ohun ti awọn gbọ niyẹn, ko si ọlọpa kankan nibi isẹlẹ naa nigba to waye, amọ iwadi ti n lọ lọwọ lati mọ iru awọn eeyan to sisẹ naa.

"Ohun to se koko nipe iwa ti wọn hu yii buru jai, ẹnikẹni to wu ko jẹ, ti ọwọ sinku wa ba fi tẹ wọn, a o fi oju wọn ba ileeẹjọ."

Àkọlé fídíò, Làáhànmí: Ìwádìí ní èèyàn 219 ni ibà Lassa pa lọ́dún tó lọ́, 29 lọ́dún yìí, tètè dènà rẹ̀

Nigba to n sọrọ lori ipo ilera ti Toyosi Adesanya wa, osisẹ alarena ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Kwara ni bi o tilẹ jẹ pe oun ko tii foju kan kan osere ori itage naa, sibẹ oun gbagbọ pe alaafia lo wa.

Géńdé agbébọn mẹ́rin kọlu Toyosi Adesanya, awakọ̀ rẹ̀ dèrò ọ̀run

Toyosi Adesanya Ileyemi

Oríṣun àwòrán, Toyosi Adesanya Ileyemi

Iroyin kan to gba ori ayelujara kan ti kede pe, ori lo ko osere tiata lobinrin kan yọ, Toyosi Adesanya Ileyemi, lọwọ iku ojiji.

Amọ bi o tilẹ jẹ pe Toyosi moribọ lọwọ isẹlẹ iku naa, awakọ to wa ọkọ to wa ninu rẹ ko ye isẹlẹ naa, to si gba ibẹ lọ si ọrun alakeji.

Gẹgẹ baa se gbọ, oju ọna marosẹ ilu Omu Aran si Ilọrin la gbọ pe awọn mejeeji ti n rekọja lọ, nigba ti awọn eeyan mẹrin kan ya bo wọn, ti wọn si se wọn lọsẹ.

Nigba to n kede isẹlẹ naa loju opo Instagram rẹ, ilumọọka osere tiata mii, Ibrahim Chatta fi tẹdun tẹdun daro awakọ to jẹ Ọlọrun nipe naa, ẹni to pe orukọ rẹ ni Juwọn.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Chatta ni abẹ oun ni Juwọn yii ti n sisẹ nigba to kọkọ de si agbo isẹ tiata gẹgẹ bii alakoso ibi ti ere de duro, to si tun maa n sisẹ awakọ laarin awọn, ki owo lee to na fun.

Agba osere naa wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ọdọmọkunrin ọhun si afẹfẹ rere.

Titi di asiko yii, a ko tii gbọ ọrọ lẹnu Toyosi Adesanya, ti oun ati Juwọn dijọ rinrinajo , ti a ko si lee sọ iru ipo ti oun gan wa bayii, amọ bo ba se jẹ, a mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin.