Amotekun: Aro tó wá láti ilú Ọyọ ló máa ń fi ẹranko náà dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá

Oríṣun àwòrán, Wikipedia
Kii se tuntun mọ pe awọn gomina lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria sefilọlẹ igbimọ alaabo kan ti wọn pe ni Amotekun, eyi ti yoo maa mojuto eto aabo ilẹ Yoruba.
Sugbọn ohun to wa ya ni lẹnu julọ ni wipe iwadi ati itan ti jẹ ko ye wa pe, ikọ alaabo Amotekun kii se tuntun nilẹ Yoruba, o ti wa lati igba ọdun o le diẹ sẹyin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Itan naa, gẹgẹ baa ti kaa loju opo itakun agbaye Wikipedia, ni nilu Ilaro, to wa ni agbegbe Yewa, taa mọ si Ẹgbado tẹlẹ ni ikọ Amotekun ti gberasọ lati ọdọ ẹnikan to da ilu naa silẹ.

Oríṣun àwòrán, @wunmy5
Gẹgẹ baa ti gbọ, Aro ni orukọ ọkunrin naa, to da ilu Ilaro silẹ, to si ni Amotekun kan to n sin bi ẹran ile, eyi to maa n mu kiri.
Ilu Ọyọ la gbọ pe Aro ti wa, lasiko ti iroyin gbalẹ kan pe awọn agbesunmọmi lati ilẹ okeere n dunkooko mọ awọn ọmọ Oduduwa to wa layika.
Aro si tẹdo si ilu kan ti wọn n pe ni Igbo Aje, eyi to wa lori oke, ti yoo si mu ko rọrun fun oun ati awọn akẹẹgbẹ rẹ lati mọ igba tawọn ọta ba sunmọ tosi, lati wa sisẹ ibi wọn.

Agbẹ gidi ati ọdẹ haun-haun ni Aro, ti awọn eeyan si bẹrẹ si fi orukọ rẹ pe ilu Igbo Aje. Wọn n pe ilu naa ni ilu Aro, eyi to wa pada di Ilaro ni oni.
Amotekun ti Aro si maa n mu kiri lo maa fi n daabo bo ilu naa ati awọn agbegbe ilẹ Yoruba yoku, ti awọn ọta ba si de lati wa fi ogun ko ilu Aro, Amotekun yii ni yoo doju ija kọ wọn, ti yoo si ba wọn ja ni ajasẹgun.
Nigba ti ogbo de, Aro fẹ fi han awọn eeyan bi agbara oogun rẹ ti pọ to, Aro ati Amotekun rẹ ni wọn dijọ wọ ilẹ lọ ni aaye, ti wọn ko si ri wọn mọ titi di oni.
Ọ̀daràn tó bá ta féle-fèle yóò bọ́ sọ́wọ́ Amotekun - Ìjọba Ekiti

Oríṣun àwòrán, Oba Adeoye
Agbẹjọro agba nipinlẹ Ekiti, to si tun jẹ kọmisana feto idajọ, Wale Fapohunda ti sọ pe ipinlẹ Eko, Ogun ati Ekiti lo n lewaju lati ṣe agbekalẹ ofin ti yoo ṣe atọna ikọ alaabo Amotekun.
Fapohunda fi ọrọ yi lede fawọn akọroyin lọjọ Aiku, pẹlu afikun pe Amọtẹkun yoo lagbara lati mu awọn to ba tasẹ agẹrẹ sofin.
Ninu alaye rẹ, Fapohunda sọ pe awọn agbẹjọro agba lawọn ipinlẹ ta darukọ ṣaaju, yoo ṣe ipade lọjọ kẹfa oṣu Keji, lati se akojọpọ gbogbo abadofin ti wọn ba kojọ nipa ilana ti Amọtẹkun yoo maa tẹle.
''Ohun ta fẹ ni pe ki a gbe ikọ alaabo eleyi ti yoo ba ofin mu kalẹ, ki awọn eeyan agbegbe ta ti ṣe agbekalẹ rẹ baa le ni igbabọ ninu rẹ. Afojusun wa ni ki a ni ofin ti yoo daabo bo ẹmi awọn ara ilu''
Fapohunda tẹsiwaju pe, abadofin tawọn n ṣeto rẹ ni yoo ṣe agbekalẹ aṣẹ ti awọn yoo gbe le ikọ Amọtẹkun lọwọ.
''Kii ṣe nkan tuntun ni ki awọn ikọ alaabo ni agbara lati mu awọn ọdaran. Gbogbo awọn ikọ alaabo igbalode wa lo ni agbara lati mu ọdaran. Ohun pataki ni pe ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin ti wọn ba mu awọn ọdaran naa tan?''
Bi Amọtẹkun yoo ti ṣe ṣiṣẹ ni pe bi wọn ba ri ọdaran to n tasẹ agẹrẹ sofin, wọn yoo fi to awọn agbofinro leti. Bi eleyi ko ba ṣeeṣe, wọn yoo mu ẹni naa ti wọn yoo si fa le awọn agbofinro lọwọ''
O pari ọrọ rẹ pe, awọn ṣi n ṣiṣẹ pẹlu awọn ọọfisi agbẹjọro agba lawọn ipinlẹ Iwọ oorun to ku, lati ri pe awọn ofin wọnyi ko yatọ sira wọn.

Bi a ko ba gbagbe, laipẹ yi ni awọn Gomina ipinlẹ Iwọ oorun ati ijọba apapọ fẹnuko lori idasilẹ ikọ alaabo Amọtẹkun.
Ninu ipade naa, ti igbakeji aarẹYemi Osinbajo dari rẹ, wọn panupọ pe ki awọn ijọba ipinlẹ pada lọ ile lati fi ofin to yẹ gbe idasilẹ Amọtẹkun lẹyin.













