Coronavirus Update in Nigeria: 'Ewu ń bẹ pẹ̀lú bí àwọn ọmọ iléèwé ṣe wọlé padà lásìkò àrùn Coronavirus'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita Onimọ nipa eto ilẹra lorilẹede Niajiria ti ni ewu nla ni yoo jẹ fun eto ilẹra ni Naijiria ti ijọba apapọ ba paṣẹ ofin konile-o-gbele ọlọjọ gbọọrọ mii, ti arun Coronavirus ba peleke si ni Naijiria.
Alaga ẹka to n risi ajakalẹ arun ni ileewosan ẹkọṣẹ ti ileewe giga fasiti eto ilera ni Naijiria, UNIMED ni ipinlẹ Ondo, Dokita Ayodeji Akinbodewa lọ sọ bẹẹ fun BBC.
Dokita Akinbodewa n sọrọ lori bi awọn eniyan ṣe kọ lati ma ṣe yoju si ileewosan fun ayẹwo nipa arun Coronavirus.
- Akomolede àti Aṣa: Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yán ni Bunmi Femi Amao ń kọ́ wa lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà
- Ọ̀gá iléeṣẹ́ gbé £10 mílíọ̀nù ẹ̀bùn owó fún òṣìṣẹ́, èyí lohun tó pawọ́n pọ̀
- Orílẹ̀èdè Amẹrika ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wo wọlé-wọ̀de Atiku, àwọn ìyàwo rẹ̀ lórí owó tí wọ́n kó lọ sí òkèèrè
- Hisbah mú ọkùnrin mẹ́ta tó pín fídíò ìfipábánilòpọ̀ ọmọdébìnrin 16 tó fẹ́ ṣèyàwó lórí ayélujára
Dokita Akinbodewa ni ibanujẹ ọkan ni yoo jẹ fun awọn dokita ni ileewosan kaakiri orilẹede Niajiria nitori iṣẹ yoo wọ wọn lọrun.
O ni kii ṣe arun Coronavirus nikan ni Naijiria n koju lọwọlọwọ, awọn aisan bii Lassa Fever, ikọ fere ati arun ti ko gboogun, HIV naa ṣi n ba awọn ọmọ Naijiria finra ju arun Coronavirus lọ.
''Nitori naa ni ijọba, awọn oloṣelu ati awọn adari ijọ gbọdọ fi ọwọ sowọpọ lati rii wi pe awọn eniyan tẹle ofin to rọmọ didẹkun itankalẹ arun Coronavirus ni Naijiria''
''Ti a ba wo awọn orilẹede miiran lagbaye, ohun ti a ri ni pe ti ijọba ba ti dẹ ofin konile o gbele, ti awọn eniyan si pada si igbeaye wọn tẹlẹ, arun naa ni peleke sii ni, ti o si n mu ọpọlọpọ ẹmi lọ.''
''Amọ, yatọ si orilẹede South-Afrika ni ilẹ Afrika, arun yii ko ni ipa lara wa bi akọsilẹ ṣe kọkọ sọ wi pe yoo ri.''
''Bakan naa ni ida aadọrin awọn eniyan to ni arun Coronavirus ni Naijiria ni ko fi ami han lara wọn, ti ko si ṣe wọn ni ijamba.''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nitori naa, alaga ẹka to n risi ajakalẹ arun ni ileewosan ẹkọṣẹ ti ileewe giga fasiti eto ilera ni Naijiria, UNIMED, Dokita Ayodeji Akinbodewa naa ni oun ni igbagbọ wi pe bi awọn akẹkọọ ṣe pada si ileewe yii, ko le e ni ipa buburu lori awọn eniyan.

Oríṣun àwòrán, @Osrt school Instagram
Ẹwu nla n bẹ pẹlu bii awọn akẹkọọ ṣe pada si ileewe lasiko arun Coronavirus yii- Bisi Iyaniwura
Onimọ nipa eto ọrọ aje ni Niajiria, Bisi Iyaniwura ti ni inu oun bajẹ pẹlu bii ijọba ṣe fun awọn ọmọ ileewe alakọbẹrẹ laaye lati pada si ileewe lasiko arun Coronavirus yii.
Iyaniwura ni o lewu nitori wi pe ijọba ko fi ohun gbogbo ti awọn ọmọ naa nilo lati pada si ileewe sibẹ, ki ijọba to paṣẹ ki awọn ọmọ kekeke pada si ileewe.
O ni awọn ọmọ ileewe ti oun ri ni agbegbe kan n di mọ ara wọn lai tẹlẹ ofin ijinasiraẹni nitori wi pe o ti pẹ ti wọn ti ri ara wọn gbẹyin.

Oríṣun àwòrán, osun state government/ twitter
''O ṣi dara ti awọn ọmọ girama ati fasiti ba pada si ileewe, amọ o buru jai fun awọn ọmọ ileewe alakọbẹrẹ nitori wọn ko le e tọju ara wọn.''
Nitori naa, o rọ ijọba lati fun awọn ọmọ naa laaye lati jọkọ sile fun oṣu kan si meji lati woye bi arun naa yoo ṣe lọlẹ si, ki wọn to pada si ileewe.
Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba to fi owo kun owo epo ati owo ina lasiko arun Coronavirus ti awọn orilẹede miran n ṣe iranwọ fun awọn araalu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O rọ ijọba lati mu gbogbo nkan rọrun fun awọn ọmọ Naijiria lasiko yii, ki wọn ba le tọju ara wọn ati ẹbi wọn.
Awọn ileewe wọle pada fun saa igbẹkọ tuntun lẹyin igbele isede ajakalẹ aarun coronavirus.
Bakan naa lawọn ile ẹkọ giga nipinlẹ Eko wọle pada.
Oṣu mẹfa gbako ni ijọba fi gbe awọn ileewe tipa lẹyin ti ajakalẹ aarun covid-19 bẹ silẹ lorilẹede Naijiria.
- Orílẹ̀èdè Amẹrika ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wo wọlé-wọ̀de Atiku, àwọn ìyàwo rẹ̀ lórí owó tí wọ́n kó lọ sí òkèèrè
- Lawuyi Ogunniran, àgbà ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé Eégún Aláré dágbére fáyé!
- Bah N'Daw àti Assimi Goita di adarí tuntun láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè Mali ní ọdún kan àti aàbọ̀
- Wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká tó ṣe ìgbéyàwó ní ọdún 2020 yìí
- Ọ̀rọ̀ Soyinka àti Obasanjo papọ̀ lórí pé Buhari n ṣe ìpínyà Nàìjíríà
Awọn akẹkọọ to wọle lọjọ Aje lawọn ileewe alakọbẹrẹ ati girama kan niluu Eko ko pọ rara.
Ṣugbọn lawọn ileewe kan, niṣe lawọn akẹkọọ tu yahaya tu yahaya wọle pada sile iwe.
Ohun to jẹ iyalẹnu ni pe awọn ogo-wẹẹrẹ ti a mọ si ''Nursery pupils'' ti ijọba paṣẹ pe ki wọn maa tii wọle rara naa wọle pẹlu awọn akẹkọọ ileewe alakọbẹrẹ lawọn ileewe kan niluu Eko.
Ohun ti a gbọ ni pe ileewe alakọbẹrẹ ẹgbẹrun le ni mẹtadinlogun(1017) to jẹ ti ijọba ipinlẹ Eko ko tii wọle.
Ọpọ ileewe alakọbẹrẹ to jẹ ti aladini naa ko wọle kaakiri ilu Eko.
Ilé ìjọsìn lè bẹ̀rẹ̀ ìsìn àárín ọ̀sẹ̀ padà, Mọ́sáláṣí àti Ṣọ́ọ̀ṣì lé gba iye èèyàn tó wù wọ́n ṣùgbọ́n...
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe ki awọn ile ijọsin bẹrẹ isin aarin ọsẹ pada ni ipinlẹ naa.
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti fun awọn Musulumi laaye lati bẹrẹ adura ojoojumọ pada ki iye awọn to fẹ kirun si pọ bi o ba ṣe wu wọn.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Sanwo-Olu
Sanwo-Olu sọ ọrọ yii lasiko to n kede awọn igbesẹ tuntun ti wọn gbe lati de awọn ofin to de arun Coronavirus ni ipinlẹ Eko.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Amọ, gomina Sanwo-Olu rọ awọn eniyan lati tẹle ofin ijinasiraẹni ati fifọ ọwọ loore koore, lọna ati dẹkun itankalẹ arun Coronavirus.
Oṣu mẹfa sẹyin ni ijọba ti awọn ileewe, ile ijọsin ati awọn ojuko iṣere to fi mọ sinima lọna ati dẹkun arun Coronavirus.
Bakan naa ni gomina Sanwo-Olu kede awọn ilana tuntun fun awọn akẹkọọ ti o fẹ wọle pada ni Ọjọ Ajẹ, Ọjọ Kọkanlelogun, Oṣu Kẹsan, ọdun 2020.
Iye awọn eniyan to ti lugbadi arun Coronavirus ni Naijiria bayii ti le ni ẹgbẹrun lọna mẹtadinlọgọta.
Nigba ti , iye eniyan to ti ni arun Coronavirus ni ipinlẹ Eko kaakiri ti le ni ẹgbẹrun mejidinlogun.
- Wọ́n ti dáwọ́ ìdánwò àbẹ́rẹ̀ àjẹsára Oxford dúró lẹ́yìn ti olùkopa kan ṣàìsàn
- Coronavirus bí èso rere nílẹ̀ Adúláwọ̀, wo díẹ̀ lára èso náà...
- Coronavirus cases in Africa- Ó tí lé ni mílíọ̀nù kan ènìyàn to ti lùgbàdì ààrùn Covid-19
- Ẹ̀rọ CCTV tú àsírí ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún tó fi ipá bá ọmọ ọdún mọ́kànlá lòpọ̀
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn ọmọ ilé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde ọjọ́ ìwọ́lé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún àwọn ìpele ẹ̀kọ́ ni ìpíńlẹ̀ yìí.
Gómínà ìpínlẹ̀ Eko Babajide Sanwo-Olu kéde ọ̀rọ̀ yìí lọ́sàn ọjọ Abamẹta, nílé ìjọba tó wà ni Marina.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ni àlàálẹ̀ oríṣiríṣi ló ti wà fún àwọn ìpele ẹ̀kọ́ ní ìpińlẹ̀ Eko pàápàá jùlọ èyí to níṣe pẹ́lú sí pípéjú ọgbà ilé iwé.

Oríṣun àwòrán, Sanwol-olu/instagram
- Lẹ́yìn olóògbé Barrister àti Kollington, èmi làgbà kàn nínú iṣẹ́ orin Fuji- Obesere yarí
- Building Collapse: Iléèwé míràn tún dàwó ní ìpínlẹ̀ Eko
- Yatọ̀ sí pé ó ṣe sọ́jà, tó tún jẹ́ ọkọ Oriṣabunmi, wo àwọn nkan tí o kò mọ̀ nípa Jimoh Aliu
- Facebook mú àyípadà bá àtẹ̀jíṣẹ́ síra ẹni lórí òpó Instagram, wo àwọn ǹkan tó kàn ọ níbẹ̀
Ó ní àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ tó wà ni ipele, kẹta àti ìkaarún ní ilé ìwé girama nìkan ni ààyè wà fún láti padà sí ilé ẹ̀kọ́ ni ọjọ́ ajé, ọjọ́ kọkàlélógún, oṣù yìí.
Gónìmà ni èyí rí bẹ́ẹ̀ láti lè jẹ́ ki wọ́n gbáradì fún ìdánwò tó ń bọ̀ lọ́nà àti kí àwọn onípele kààrún nílé ẹ̀kọ́ girama ba à lè múrasílẹ̀ fún ipele kẹfa.
Sùgbọ́n fún gbogbo àwọn ipele ẹ̀kọ́ tó kù láti ilé iwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ titi de àwọn onipele kẹrin nílé iwé girama, ìjọba ni òun yóò kéde lẹ́yìn ti arídáju bá ti wa pé gbogbo ìlàna tó yẹ ló ti wà nílẹ̀.
Ẹ̀wẹ́, o ní kí olúkúlùkù pada si àwọn ìlàna orí ayelujara tabi rẹdíò ti wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ láti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni ìmọ̀ títí di ìgbà ti ìjọba yóò ṣe ikéde tuntun.
Bakan náà ni ìjọba tún kéde pé gbogbo àwọn ilé ọtí àti gbogbo ibi ìtura gbogbo tó fi mọ́ àwọn ilé ijọ àti sinimá níwọ̀n ìgbà ti wọ́n ba ti tẹ̀lé àwọn ìlànà lati dena ìtàkálẹ̀ ààrùn Covid-19.
Iye ènìyàn tọ gbọ̀dọ̀ péjú lẹ́ẹ̀kan kò gbọdọ jú ìdá ọgbọ́n lọ́, gbogbo àwọn ilé iṣẹ́ yìí si gbọ̀dọ gba iwé ẹ̀rí lọ́dọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kí wọn to bẹ̀rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde
Ìjọba Oyo kéde pé láàrín Sept. sí Dec. ni abala kínní sáà ètò ẹ̀kọ́ yóò wáyé
Ijọba ipinlẹ Oyo ti kede pe awọn ile ẹkọ rẹ yoo di ṣiṣi pada ni ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan-an taa wa yii.Atẹjade kan ti kọmisana feto ẹkọ nipinlẹ Oyo, Olasunkanmi Olaleye fi sita lo sisọ loju ọrọ yii.
Atẹjade naa ni ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan-an si ọjọ kejidinlogun oṣu kẹwaa ọdun 2020 ni abala kinni saa eto ẹkọ ọdun 2020 si 2021 yoo bẹrẹ.
Abala keji saa eto ẹkọ naa yoo bẹrẹ lọjọ kọkanla osu kinni si ọjọ kẹsan-an osu kẹrin ọdun 2021.
Abala kẹta eto ẹkọ naa yoo bẹrẹ lọjọ Kẹta osu karun, ti yoo si pari ni ọgbọnjọ osu keje ọdun 2021.Ileesẹ eto ẹkọ wa rọ awọn araalu ati awọn eeyan tọrọ naa gberu lati ṣe akiyesi bi saa eto ẹkọ naa yoo ṣe lọ.

Oríṣun àwòrán, osun state government/ twitter
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun fún àwọn ọmọ ilé ìwé ní ìgbéga sí kílààsì tó kàn láì ṣe ìdánwó nítori Covid-19
Ijọba ipinlẹ Ogun ti kede igbega si kilaasi to kan lai ṣe idannwo fun awọn ọmọ ile iwe alakọbẹrẹ ati girama ipinlẹ naa ni kete ti wọn ba pada ṣenu ẹkọ wọn.
Bakan naa lo tun kede ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2020 gẹgẹ bi ọjọ ti awọn ile iwe rẹ yoo di ṣiṣi pada.

Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR
Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ naa, Kunle Somorin lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan to fi sọwọ si awọn akọroyin.
- Ó yẹ kí Buhari dá owó epo padà sí ₦97 tàbí kó kọ̀wé fipò sílẹ̀ - Àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Wò ó bí Alaafin àti aya àkọ́fẹ́ rẹ̀, Olorì Abibat ṣe pàdé ní èwe
- Ọmọ Ààrẹ lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìgbéyàwó yálà àwọn ará ìlú fẹ́ràn ìjọba bàbá rẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Aisha Buhari
- Owó lítà epo ní Nàíjíríà ló kéré jùlọ l‘Áfíríkà - Lai Muhammed
O ni gomina Dapo Abiodun ti buwọlu ṣiṣi gbogbo ile iwe pada bẹrẹ lati ile iwe alakọbẹrẹ titi de awọn ile ẹkọ giga.
Somorin fi kun pe ijọba ti ṣetan lati ṣi awọn ile iwe naa ni ibamu pẹlu ilana to rọmọ Covid-19.
Gẹgẹ bi alakalẹ ṣiṣi ile iwe ọhun ṣe lọ, awọn ọmọ ile iwe alakọbẹrẹ lati ipele kini si ikẹta yoo lọ ile iwe lati aago mẹjọ owurọ si mọkanla, nigba ti awọn to wa ni ipele kẹrin si ikẹfa yoo lọ lati aago mejila ọsan si aago mẹta.
Awọn ti ile iwe girama lati ipele kini si ikẹta akọkọ yoo kẹkọọ lati aago mẹjọ si mọkanla owurọ, nigba ti awọn ti ipele kinni si ikẹta keji yoo lọ ile iwe lati aago mejila ọsan si mẹta.
Somorin ṣalaye pe awọn to n lọ ile iwe ẹkọṣẹ ọwọ yoo maa kẹkọọ bi wọn ṣe n ṣe tẹlẹ, lati aago mẹjọ owurọ si meji ọsan.
Nigba ti awọn akẹkọọ ile iwe giga ni anfani lati ṣi ile iwe pada ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2020, ṣugbọn igbesẹ naa wa lọwọ awọn adari ile iwe bẹẹ.
Ni ti awọn ọmọ ile iwe lati ọmọ ọdun mẹta si marun un, o ni wọn ko lanfaani lati pada sile iwe lasiko yii.
Bo tilẹ je pe awọn akẹkọọ nile iwe girama to wa ni ipele kẹta akọkọ yoo tẹsiwaju si ipele kinni ẹlẹẹkeji lai ṣe idanwo, wọn yoo ṣe idanwo BECE ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2020.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Sept. 14 ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò padà sí iléèwé ní Kogi
Ijọba ipinlẹ Kogi ti kede pe awọn akẹkọọ yoo wọle pada ni Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Kẹsan an, ọdun 2020 lai yọ ileẹkọ alakọbẹrẹ, girama ati awọn ileewe giga ipìnlẹ naa.
Kọmisọnna fun eto ẹkọ, imọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ nipinlẹ naa,Arakunrin Wemi Jones lo kede rẹ ni ilu Lokoja.
Jones ni ijọba ipinlẹ naa kede igbesẹ yii lẹyin ti wọn ṣe ifọrọwerọ pẹlu awọn eniyan ti ọrọ naa kan ni ẹka eto ẹkọ.
- Ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Adams Oshiomole kìí ṣe ojú lásan, àwọn kan ló fẹ́ pa á- APC
- Ọba Saudi Arabia yọ ọmọ rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ kúrò nípò nítorí ìwà àjẹbánu lórí owó tó yẹ fún ààbò ìlú
- Èèyàn 239 míràn ṣẹ̀ṣẹ̀ kó COVID-19 ní Nàìjíríà
- Ọkùnrin kan di èrò ọ̀run nítorí pé o fi ẹ̀sùn kan alájọgbélé rẹ̀ pé o n yan ìyàwó ẹnìkan lálè
- Victoria Rubadir ọmọ Kenya ló gba àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor BBC World News
Jones fikun un pe idi ti gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello ṣe gbe igbesẹ lati ti ileekọ ni Oṣu Kẹta, ọdun 2020 ni tori arun Coronavirus to n ja ranyinranyin kaakiri agbaye.
"Lẹyin naa ni awọn tẹlẹ aṣẹ ilẹeṣẹ ijọba to n risi ẹka eto ẹkọ ni Naijiria, wi pe ki wọn ṣi ileewe alakọbẹrẹ fun awọn to wa ni Primary 6, JSS3 ati SS3 ni Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Kẹjọ, Ọdun 2020.
"Ati wi pe lẹyin ipade pẹlu awọn ti ọrọ naa kan ni gomina naa gbe igbesẹ naa pe ki gbogbo awọn akẹkọọ pada si ileewe ni Ọjọ Kẹrinla, Osu Kẹsan an, ọdun 2020 ".
- Àwọn ará ìlú Ikarẹ Akoko ń ṣọ̀fọ̀ Ọba Adegbite, Ọwá Ale Ikarẹ tó wàjà
- Gbajúgbajà òṣèré “Blue film'' wọ gàù ẹ̀sùn fífipá bá obìrin 13 lòpọ̀
- Ẹgbẹ́ wa ò dàrú o! Kódà gbọingbọin la wà lẹ́yìn Akintoye gẹ́gẹ́ bíi adarí YWC nílé, lẹ́yìn odi
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Àṣírí tú! Wo àwọn tó ń jí owó Covid-19 tí Ìjọba ní wọ́n yóò káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́
Kọmisọnna fun eto ẹkọ naa fikun wi pe idi ti ijọba ipinlẹ Kogi ṣe ni ki awọn akẹkọọ pada si ileẹkọ ni pe awọn ko kabamọ pẹlu awọn akẹkọọ Primary 6, JSS3 ati SS3 ti wọn ti kọkọ wọle.
Bakan naa ni ijọba wa rọ awọn adari ileewe lati tẹle ofin ati ilana ti ijọba gbe kalẹ lati le bọ lọwọ arun Coronavirus nipinlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ kéde ìwọlé fásitì, ASUU àti ìjọba àpapọ̀ ní kí wọ́n ṣọ́ra!
Awọn alaṣẹ ijọba apapọ ti fi imọran sita gẹgẹ bi awọn ijọba ipinlẹ kọọkan ṣe ti kede ọjọ ti awọn ileewe yoo wọle.
Ipinlẹ Eko ati Osun ni iha Guusu-Iwọ Oorun ti ni awọn ileewe yoo di ṣiṣi lọjọ kẹrinla ati ikọkanlelogun oṣu kẹsan ọdun 2020.
Ijọba apapọ gan ti wa funpe si awọn ijọba ipinlẹ pe ki wọn ṣọra lori bi wọn ṣe fẹ ṣi awọn ileewe tori pe ewu ṣi wa loko longẹ.
Boss Mustapha to jẹ akọwe ijọba apapọ to tun jẹ alaga igbimọ amuṣẹya aarẹ lori ọrọ COVID-19 fi ikilọ yii lede lọjọ Aje ni ilu Abuja nibi ipade ikejilelọgọta igbimọ naa.

Oríṣun àwòrán, osun state government/ twitter
O ni bi orilẹede ṣe n pinu lati ṣi awọn ibi ipejọpọ itagbangba, wọn gbudọ rii pe wọn ṣi n ṣe ohun gbogbo lati bori.Minisita fun eto ilera ni agbara aisan COVID-19 ko re 'bikan o pe o lewu to si n gba ẹmi awọn eniyan.'Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn olukọni fasiti ni Naijiria, ASUU ti kilọ fun awọn ijọba ipinlẹ pe ki wọn ma ṣe ṣi awọn ile ẹkọ giga lasiko yii.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ẹgbẹ ASUU n fẹ ki ijọba mu suuru titi di igba ti wọn ba lee ri ọna gboogi lati dinwọ aranka aarun Coronavirus ku.
Ẹgbẹ naa ni bi nkan ṣe wa lasiko yii, o fẹrẹẹ ma le tii si aaye fun awọn ile iwe giga ijọba lati tẹle ofin ijinasiraẹni.
Lọwọlọwọ awọn ọmọ ileewe girama to wa ni kilaasi aṣekagba nikan lo n lọ ileewe kaakiri gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji Naijiria lati ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ọdun 2020 lati le kọ idanwo wọn bii WAEC ati NECO.Ẹwẹ, minisita abẹle fun eto ẹkọ, Họnọrebu Emeka Nwajiuba sọ pe ijọba apapọ ko tii sọ ọjọ ti awọn ileewe yoo wọle jakejado ṣugbọn ọjọ eyi tawọn ijọba ipinlẹ kede n kọ awọn obi lominu gidi gan.

Oríṣun àwòrán, Adegboyega oyetọla
Ìpínlẹ̀ Osun kéde ọjọ́ táwọn iléèwé yóò ṣí padà
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede eto iwọle tuntun fun ṣiṣi awọn ileewe ni ipinlẹ naa pẹlu mimu ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan ọdun 2020 fun ṣiṣi awọn ileewe nibẹ.
Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọnna feto iroyin ati ilanilọyẹ ni ipinlẹ naa, Arabinrin Funkẹ Ẹgbẹmọde fi sita lẹyin ipade igbimọ iṣakoso ijọba ni ipinlẹ naa, ijọba ipinlẹ Ọṣun ṣalaye pe awọn ilana a a tẹle gbogbo yoo ṣi wa nikalẹ fawọn alẹnulọrọ lẹka eto ẹkọ nibẹ ni ibamu pẹlu ilana ti ijọba apapọ ba gbe kalẹ.
Pẹlu eyi, ijọba ipinlẹ naa ti kede ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan an naa lati pari saa kẹta eto ẹkọ to n lọ lọwọ ki ajakalẹ arun COVID-19 loṣu kẹta ọdun 2020.
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ni awọn gbe igbesẹ yii lẹyin oniruuru agbeyẹwo lawọn ileewe lati mọ bi igbaradi wọn lati pada si eto ẹkọ kikọ ṣe ja fafa si.
Ni ọgbọn ọjọ, oṣu kẹwaa ni saa kẹta to ku yoo pari fun awọn akẹkọọ lati le e lọ fun isinmi ranpẹ eyi ti yoo pari ni ọjọ kẹsan an, oṣu kọkanla, ọdun 2020.
Atẹjade naa tun fi kun un pe isinmi ranpẹ miran yoo tun waye bẹrẹ lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila nitori pọpọṣinṣin ọdun ti yoo maa waye nigba naa.
Ṣugbọn awọn akẹkọọ yoo pada si ẹnu ẹkọ wọn ọjọ kẹrin oṣu kinni, ọdun 2021 lati pari saa akọkọ eto ẹkọ ọdun 2020/2021 eyi ti yoo pari ni ọjọ kejilelogun, oṣu kinni, ọdun 2021.
Ki wa ni ijọba apapọ wa sọ lori ṣiṣi ileewe pada fun ẹkọ?
Amọṣa, ijọba apapọ ti fa awọn ipinlẹ to n gbe igbesẹ lati ṣi awọn ileewe pada leti pe ẹkọ gbigbona n fẹ suuru.
Boss Mustapha to jẹ alaga ikọ amuṣẹya lori ọrọ ajakalẹ arun COVID-19 ni Naijiria ṣalaye lasiko ijiroro igbimọ naa lọjs Aje nilu Abuja pe nnkan lee da bi ẹni pe o ti n lọlẹ lẹnu lọwọlọwọ yii lori ọwọja ajakalẹ arun naa ṣugbọn O ni ẹyẹ ina gbigbona lọrọ arun naa ni Naijiria bayii, O kan fi eeru tutu boju ni.

Oríṣun àwòrán, others
Yàtọ̀ sí Eko, wo ohun t'áwọn ìpínlẹ̀ meje míràn ń sọ nípa ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́
Ni bayii ti awọn eeyan lorilẹ-ede Naijiria, paapaa julọ awọn obi, alagbatọ ati akẹkọọ n ko aya soke lori ibeere ati mọ igba wo gan an lawọn iloro ileewe yoo di ṣiṣi pada fun ẹkọ lorilẹ-ede Naijiria.
Lati oṣu kẹta ọdun 2020 ni ileewe ti wa ni titi pa lorilẹ-ede Naijiria nitori ọwọja ajakalẹ arun COVID-19 to bẹ silẹ kaakiri agbaye.
Ni ọsẹ to kọja ni ijọba ipinlẹ Eko kede ni tirẹ pe awọn akẹkọọ ileewe giga gbogbo ni ipinlẹ naa yoo wọle pada sẹnu eto ẹkọ ni ọjọ kẹrinla oṣu kẹsan an nigba ti awọn ileewe alakọbẹrẹ ati girama yoo tẹlee ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan kan naa.
Eyi tubọ mu ki ọpọ akẹkọọ lawọn iipinlẹ yokuu o maa beere pe igba wo ni yoo kan awọn naa pẹlu.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu iwe iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria, ipinlẹ Ogun ati Ekiti ti ni awọn ko kanju lati da akẹkọọ pada si ileewe bayii.
- Ìdí tí mo fi ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí 35 lọ́dọọdún rèé- Allwell Ademola
- Wo ojú Akeem t'Ọlọ́pàá mú pé ó fipá bá ọ̀dọ́mọbìnrin kan sùn létí odò l'Oṣun
- Ìjà d'ópin, fún ìgbà àkọ́kọ́, bàálù gbéra láti Israel lọ sí UAE
- Wọ́n ti sún ìdájọ́ àwọn sójà tó pa ìyá àti ọmọ ní ọdun 2018 sí oṣù tó m bọ̀
- Ààrẹ Buhari buwọ́lu gbígbé ìṣàkoso nọ́mbà ìdánimọ̀ (NIMC) lọ sí ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí ìbáraẹnisọ̀rọ̀
Ninu ọrọ ti Remmy Hazzan, olubadamọran fun gomina ipinlẹ Ogun lori ọrọ ibanisọrọ ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin naa, pe wọn ko tii le wọle.
Remmy Hazzan ni aṣẹ ijọba apapọ lawọn tẹle ni ipinlẹ Ogun.
Eyi to wa lati ti awọn ileewe pa, o si di igba ti ijọba apapọ ba tun gbe aṣẹ miran jade to tako eyi ki awọn to lee ṣi ileewe pada.
Bakan naa ni ẹni to n dari igbimọ amuṣẹya lori ọrọ coronavirus ni ipinlẹ Ekiti Ọjọgbọn Bọlaji Aluko pẹlu sọ pe awọn ko ṣetan lati wo aago alaago sare.
O ni awọn yoo kọkọ wo bi nnkan yoo ṣe lọ si lẹyin eto idanwo aṣekagba girama WASSCE ati JSSCE to n lọ lọwọ ba ṣe waye.
Ipinlẹ Ogun ati Ekiti nikan kọ lo ni ero yii lori wiwọle pada awọn akẹkọọ.
Ipinlẹ Enugu, Katsina, Bauchi, Gombe pẹlu ni awọn ko tii lee ṣe ohun to js bẹẹ lọwọ yii.
Wọn ni o di igba ti ọkan ba balẹ lori abo ati alaafia awọn akẹkọọ ki awọn to gbe igbesẹ ati ṣi ileewe pada.

Oríṣun àwòrán, @Sanwoolu
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde ọjọ́ tí àwọn iléèwé gígá yóò wọlé
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti kede pe ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹsan an, ọdun 2020 ni gbogbo ileewe giga to wa ni ipinlẹ naa yoo bẹrẹ pada.
Gomina Sanwo-Olu sọ eyi di mimọ lasiko to n ba araalu sọrọ lori ibi ti nkan de duro lori aarun coronavirus nipinlẹ naa.
Bakan naa ni gomina sọ pe ijọba ti n ṣiṣẹ lori ki awọn ileewe girama, ati alakọbẹrẹ naa le wọle pada, to ba ṣe e ṣe lati ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ni ijọba Naijiria ti gbe gbogbo ileewe ti pa, nitori itankalẹ aarun coronavirus.
Ṣugbọn ṣa, gomina kilọ fun awọn obi, ati alakoso ileewe pe "igba kuugba ni wọn le ṣe atunṣe tabi agbeyẹwo si igbesẹ naa.
Bakan naa lo sọ pe awọn ile ti, ile faaji, ati ile ijo yoo ṣi wa ni titi pa.
Ṣaaju ni Minista ileeṣẹ ijọba apapọ to n risi eto ẹkọ ni Naijiria ti fi ilana aatẹle sita ṣaaju ki awọn ile ẹkọ to wọle pada.
O ni awọn ilana yii di dandan ki ile iwe to ku le di ṣiṣi fun awọn akẹkọọ to ku lati bẹrẹ kilaasi wọn pada.
Sugbọn wọn ko tii sọ ọjọ gangan ni pato ti awọn akẹkọọ maa wọle pada sile iwe wọn.
Ṣaaju ni ijọba Naijiria ti ṣi awọn ile ijọsin, eto irinna ọkọ ofurufu nile tai nilẹ okeere ati awọn igbesẹ miran.
Lẹyin ti ajakalẹ arun to n ba gbogbo agbaye finra yii ti di ohun ti ajọ WHO ni ao kọ lati maa baa gbe titi abẹrẹ ajẹsara yoo fi jade ti yoo si gbọ wiwo ni.
Ijọba Naijiria ti fi awọn ilana to le jé ki ajajakalẹ arun Covid 19 naa dinku ni titankalẹ ti awọn akẹkọọ ba pada sile iwe bayii:
1) Ile iwe kọọkan gbọdọ kọ Olukọ nipa eto aabo funra wọn ati akẹkọọ ati awọn oṣiṣẹ nile iwe kọọkan.
2) Wọn gbọdọ ṣe agbekalẹ ilana Covid 19 lati tete de ile iwosan tabi ipese ayẹwo ni kia ti ifura ba wa.
3) Ile iwe kọọkan gbọdọ ṣeto ọkọ to n gbe alaisan nipa iṣẹlẹ apajawiri ki wọn si ni oore ọfẹ lati tete ṣe ayéwo lasiko pẹlu itọju pẹlu ajọ NCDC to n risi itankalẹ ajakalẹ arun ni NAijiria.
4) Wọn gbọdọ ni omi to mọ, ọṣẹ ifọwọ sanitaisa, imọtoto nigba gbogbo fun akẹkọọ ati awọn Olukọ.
5) Ki ile iwe din iye akẹkọọ to n wa ni kilaasi kọọkan ku ati ni ile igbe awọn akẹkọọ ati awọn ibudo ijọsin.
6) Ki wọn maa lo gbagede fun awọn eto kọọkan dipo inu iyara ikawe tabi kilaasi.
Ki wọn ṣe agbekalẹ igbimọ kan ti yoo maa mojuto ilana aatẹlẹ wọnyii fun ile iwe wọn.
Awọn ile iwe gbọdọ ṣeto iwe kika lọna to rọrun fun awọn akẹkọọ ti wọn ko si ni korajọ pọ soju kan.
Ki wọn rii pe awọn akékọọ ati Olukọ ati awọn osiṣẹ to ku n tẹlẹ awọn ilana ti ijọba ti la kalẹ naa.
Imọtoto fun gbogbo ẹni to ba n wọle to si n jade ninu ile iwe kọọkan.

Oríṣun àwòrán, julischools.com.ng
Awọn ile iwe ti ko ba ni agbra lati pese awọn ilana aatẹle yii ni oore ọfẹ lati ṣi fi awọn akẹkọọ wọn sile nile obi ati alagbatọ wọn.
Ki wọn si maa kọ wọn ni ẹkọ lati ori ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Emmanuel oloye
Ki lo ti kọ́kọ́ sẹlẹ̀?
Láì san owó oṣù tẹ jẹ wá, kò sọ́rọ̀ kankan - ASUU sọ fún ìjọba
ASUU Strike: Àwọn olùkọ́ fásitì ní àmúṣẹ àdéhùn ọdún 2019 làwọn dúró lé lórí
Adari ẹgbẹ awọn olukọ nile ẹkọ fasiti nilẹ wa (ASUU), Ọjọgbọn Biodun Ogunyemi ti sọ fun ijọba apapọ ati ti ipinlẹ pe ki wọn san owo oṣu oṣiṣẹ ti wọn gbe ẹsẹ le fun awọn ọmọ ẹgbẹ naa.
ASUU ni bi eyi ba waye, yoo fun awọn ni anfaani lati lee joko sọrọ lori awọn nkan to so pọ mọ iyanṣẹlodi to ti bẹrẹ lati ọjọ kẹtalelogun, Oṣu Kẹta, Ọdun yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Torí ₦300, awakọ̀ ojú omi ṣokùnfà ikú èèyàn méjìlá l‘Eko - Ọlọ́pàá
- Ìjọ́ mí ní Italy ni mo fi ń ṣèrànwọ́ fáwọn aṣẹ́wó ọmọ Nàíjíríà tó há - Taribo West
- Ààrẹ orílẹ̀èdè Mali, Boubacar Keita kọ̀wé fipò sílẹ̀
- Inú mí dùn láti kọrin pẹlú Beyonce nílẹ̀ Amerika- Ìyá àgbà láti Nàíjíríà
- Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá kọjú ìjà síra wọn lórí ìdárò akẹẹgbẹ́ wọn tó kú
- Ìpàkọ́ kò gbọ́ sùtì ní ọ̀rọ̀ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń bú mi- Oyedepo
- Mo kọ̀ láti pín ọkọ mi pẹ̀lú ẹnikẹ́ni, nítorí náà ẹ tú wa ká- Abílékọ Idowu faraya ní kóòtù kọkọ-kọkọ
Ogunyemi ni owo oṣu marun ni awọn olukọ fasiti ko tii ri gba ati pe, awọn ko ni ṣẹwele iyanṣẹlodi naa ti ijọba apapọ ba kọ lati se amuṣẹ adehun to ṣe pẹlu ASUU ni ọdun 2019.
Bakan naa ni ẹgbẹ salaye lọjọ isẹgun pe, ilana sisan owo oṣu awọn oṣiṣẹ fasiti (UTAS) ti wa nilẹ bayii, lati tan imọlẹ si owo oṣu oṣiṣẹ sisan ti ijọba apapọ beere fun.
ASUU lo se agbekalẹ UTAS lati duro gẹgẹ bii IPPIS tiẹ, eyi to da gbọmisi-omi-oto silẹ laarin ASUU ati ijọba apapọ.
Ogunyemi kede pe UTAS ti wa nilẹ lasiko apero kan to waye nilu Abuja, bakan naa lo pe aarẹ Muhammadu Buhari lati da si rogbodiyan to n lọ ni fasiti Eko (UNILAG), ko si se agbekalẹ igbimọ olubẹwo si ile iwe naa.
O ni ASUU ko ni sinmi iyanṣẹlodi ti ijọba ko ba ṣe amuṣẹ adehun rẹ ọdun 2019 pẹlu ASUU.
O ni owo oṣu marun gbako ni ijọba gbẹsẹ le laisan fawọn oṣiṣẹ fasiti ni Maiduguri, nigba ti Akowe owo Fasiti Michael Opara, si n di owo awọn olukọ ibẹ, nitori wọn kọ lati fi orukọ silẹ fun IPPIS.
O wa kilọ pe ASUU ko ni ri aaye fun ẹjọ kankan mọ lori wiwọgile iyanṣẹlodi, ti ijọba ba kọ lati san awọn owo ti wọn jẹ.
Tí ìjọbá bá kọ̀ láti san owó oṣù wa, a o da iṣẹ́ sílẹ̀ - ASUU
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, ASUU ti paṣẹ fun awọn olukọ fasiti lati da iṣẹ silẹ ni igbakugba ti ijọba ba ti kọ, lati san owo oṣu wọn.
Alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni ile ẹkọ fasiti Abeokuta, Adebayo oti sọ fun ile iṣẹ iroyin Punch pe awọn ti fi aṣẹ naa ranṣẹ si awọn ọmọ ẹgbẹ naa.
Adebayo ni abajade ipade ẹgbẹ ni wi pe ti ijọba ba kọ lati san owo oṣu awọn kan, gbogbo awọn ni awọn yoo da iṣẹ silẹ.
- Imoyosola Adetoro: Àwọn èèyàn sọ fún ìyàwó mi pé mo ti jẹ́ẹ̀jẹ́ nínú awo pé ń kò ní bímọ
- A ti gbé ìlẹ̀kùn ìjọba ìbílẹ̀ tìpa láti dẹ́kun wàhálà l‘Ọyọ - Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀
- Ọ̀daràn tó bá ta féle-fèle yóò bọ́ sọ́wọ́ Amọtẹkun - Ìjọ́ba Ekiti
- Agbábọ́ọ́lù alápẹ̀rẹ̀, Kobe Bryant àti ọmọ rẹ̀ dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú
Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan awọn oṣiṣẹ ijọba pe wọn lọ gba ẹyin ba ẹbọ jẹ lori eto isanwo oṣiṣẹ eto IPPIS.
Eto IPPIS ni ijọba pese lati ma a san owo oṣu oṣiṣẹ lati inu apo isuna kan naa fun owo gbogbo oṣu oṣiṣẹ ijọba, eleyii ti Asuu ni eto isanwo yii yoo gba aṣẹ to gbe awọn duro lati le daduro lai si afikun ijọba lori eto isuna awọn.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Amọ ijọba ni idi ti awọn fi gbe e kalẹ ni lati gbe ogun ti iwa ibajẹ ati jẹgudujẹra to wa ni ẹka oṣiṣẹ ijọba lorilẹede Naijiria.
Lẹyin ọpọlọpọ ipade ati akitiyan lati ọdọ ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU, wọn gba pe ki wọn gbe ajọ UTAS silẹ ti yoo gbogun ti iwa ibajẹ ni eto isuna ile ẹkọ giga, ẹleyii ti ko nilo eto IPPIS.
Amọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU fi ẹsun kan ijọba pe wọn ko duro lori ọrọ wi pe ki wọn gbe ajọ UTAS yẹmọ, amọ ti ijọba paṣẹ pe oṣiṣẹ ti ko ba si lori eto isuna IPPIS ko ni gba owo Oṣu Kini, ti ọdun 2020 ti o n pari ni ọṣẹ yii.

Oríṣun àwòrán, other
Laipẹ yii ni Aarẹ Buhari paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ lasiko ti oun ṣe ipade pẹlu wọn lati ri pe wọn yanju ọrọ naa pẹlu minisita fun eto ẹkọ lorilẹede Naijiria, Adamu Adamu.

























