Neighbours clash: Ọkùnrin kan kú nítorí pé o fi ẹ̀sùn kan alájọgbélé rẹ̀ pé o n yan ìyàwó ẹnìkan lálè

Oríṣun àwòrán, others
Ibẹrẹ ọrọ yii ni wọn sọ pe Stanley fi ẹsun kan Adekunle ti wọn jọ n gbele papọ pe, o n yan iyawo ayalegbe miran, Arinze Onuoha, ni ale.
Arinze to jẹ ọkọ iyawo, koju Adekunle, ni ọrọ naa si di ariwo nla ni adugbo ti gbogbo wọn jọ n gbe.
Stanley to rojọ fun ọkọ iyawo gan-an ko si nile lasiko ti ede aiyede naa waye.
Ẹnikan to n gbe ni adugbo kan naa pẹlu wọn, Ibidunni Adegoke, sọ fun iwe iroyin abẹle pe Adekunle koju Stanley, nigba ti wọn ri ara wọn ni alẹ.
Ọrọ di ija, debi pe lasiko ija naa ni Adekunle fi ọ̀bẹ gun Stanley, ni eyi to si ja si iku fun un.
- Ààrẹ Buhari buwọ́lu gbígbé ìṣàkoso nọ́mbà ìdánimọ̀ (NIMC) lọ sí ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí ìbáraẹnisọ̀rọ̀
- Wọ́n ti sún ìdájọ́ àwọn sójà tó pa ìyá àti ọmọ ní ọdun 2018 sí oṣù tó m bọ̀
- Ìjà d'ópin, fún ìgbà àkọ́kọ́, bàálù gbéra láti Israel lọ sí UAE
- Iléẹjọ gíga jùlọ da ẹjọ́ SDP àti PDP nù, wọ́n ní Yahaya Bello ló wọlé ìbò gómìnà Kogi
- Yàtọ̀ sí Eko, wo ohun t'áwọn ìpínlẹ̀ meje míràn ń sọ nípa ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́
Onitọhun sọ pe "Stanley (ti wọn pa) lọ ọ fi ẹjọ sun iya Arinze pe Adekunle n yan iyawo ọmọ rẹ, Chisom, ni ale."
Iroyin sọ pe inu ile kan naa ni gbogbo wọn n gbe, to si jẹ pe Adekunle lo maa n fun iyawo Arinze ni owo lati fi fun idile rẹ ni oúnjẹ, ti ọkọ rẹ ko ba ti ṣe ojuṣe.
"Nitori naa lo ṣe ro pe awọn mejeeji n fẹ ara wọn. Eyi to mu ko lọ ọ sọ fun iya Arinze.
"Adekunle koju Stanley, nigba ti awọn mejeeji de lati ibi isẹ wọn. Lasiko ti ọrọ naa di ija ni Stanley fi èdè Igbo sọ fun iyawo rẹ pe ko mu ọ̀bẹ wa fun oun, nigba to ri pe Adekunle ti n bori.
" Ọ̀bẹ naa lo fi kọkọ gun Adekunle ni ẹsẹ̀. Sugbọn, Adekunle pada ja ọ̀bẹ gba mọ ọ lọwọ, o fi gun Stanley ni aya, o si tẹ ẹ mọ́lẹ̀ titi to fi ku."
A gbọ pe ni nkan bi aago meji òru ni ija naa waye.
Ara adugbo míì, Omotola Aderibigbe, sọ pe ni kia ti Adekunle ri i pe Stanley kú, lo sa kuro ni yara Stanley ti ija ti waye, to si salọ.
"O halẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ sun mọ òun.
Lẹyin naa lo sọ fun iyawo rẹ pe, ko ba oun mu nkan ninu yaara ti wọn, o si salọ kuro nile."
- Wo ojú Akeem t'Ọlọ́pàá mú pé ó fipá bá ọ̀dọ́mọbìnrin kan sùn létí odò l'Oṣun
- Ìdí tí mo fi ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí 35 lọ́dọọdún rèé- Allwell Ademola
- Ìjọba Ghana ṣí iléeṣẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà padà. ó fún Nàìjíríà l'èsì àwọn ẹ̀sùn tó fi kàn-án
- Ọ̀fẹ́ ni China yóò kọ́ fásítì $50M ètò ìrìnnà sí Daura ìlú Ààrẹ Buhari- Amaechi
"Wọn gbe Stanley lọ sile iwosan General Hospital to wa ni Ikorodu, sugbọn ẹpa ko boro mọ.
Awọn ara adugbo lọ ọ fi ọrọ to ileesẹ ọlọpaa l'eti, ti wọn si ti gbe iyawo Adekunle lọ si agọ wọn láti ran wọn lọwọ ninu iṣẹ iwadii.
Gbogbo awọn ayalegbe to kù naa ti salọ, nitori ibẹru pe ki ọlọpaa o ma mu wọn.
Bakan naa ni wọn ti gbe oku Stanley lọ si mọsuari.
Ileesẹ ọlọpaa sọ pe iwadii ti n waye lori iṣẹlẹ naa, ti wọn si tun ti n wa Adekunle.
- Wo àwọn ìbejì tó mú ẹ̀dọ̀ àti egungun àyà kan ṣoṣo wá látọ̀run
- Ṣé Nàìjíríà lẹ́mìí nkan tí Ghana ń ṣe fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ "Secondary" tí yóò wọlé ní October yìí?
- Ààrẹ Buhari buwọ́lu gbígbé ìṣàkoso nọ́mbà ìdánimọ̀ (NIMC) lọ sí ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí ìbáraẹnisọ̀rọ̀
- Wọ́n ti sún ìdájọ́ àwọn sójà tó pa ìyá àti ọmọ ní ọdun 2018 sí oṣù tó m bọ̀

















